Wo oríṣiríṣi nǹkan tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣe tí wọ́n ló fẹ́ fa ìwé GWR ya

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Lẹyin ti Hilda Baci, olounjẹ gba ami ẹyẹ ẹni to dana fun ọpọlọpọ wakati lagbaye ni ọmọ orilẹede Naijiria ti tu sita lati ṣe ọpọlọpọ nnkan miiran lati gba ami ẹyẹ naa.

Baci lo gba ami ẹyẹ fun ẹni to se ounjẹ fun ọgọrun wakati, to si gba ipo naa lọwọ Lata Tondon, ẹni to gba ami ẹyẹ naa lọdun 2019.

Ni ibẹẹrẹ oṣe yii, Ajọ GWR kesi awọn ọmọ Naijiria pe o to gẹ!

Ki lo fa ti GWR fi gbe igbesẹ yii

Latigba ti Hilda Bacci ti gba ami ẹyẹ naa ni igboro ti daru pẹlu gbogbo awọn nnkan ẹfẹ ti awọn eeyan ni awọn fẹ ṣe lati gba ami ẹyẹ.

Koda awọn oniṣẹ ọwọ biii onidiri, olounjẹ gan atawọn adẹrinpoṣonu ti ko wọ inu fifi ami ẹyẹ GWR yii ṣe ẹfẹ.

Ileeṣẹ BBC se iwadi ati akọsilẹ awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn n gbero lati fa iwe ami ẹyẹ Guinness World Record ya to si mu ki ajọ naa kan si gbogbo awọn Naijiria.

Wo awọn ọmọ Naijria miiran ti wọn gbero lati gba ami ẹyẹ

Chef Dammy

Damilola Adeparusi lo bẹrẹ dida ina fun ọgọfa wakati lọjọ kẹsan an oṣu kẹfa ni agbegbe kan ni ijọba ibilẹ Oye, ipinlẹ ekiti.

Akẹkọọ fasiti Oye Ekiti naa ni ọpọ wa pẹlu rẹ lasiko to n dana ọhun.

Bakan naa, Dami ṣalaye idi to ṣe da ina yii ninu ifọrọwanilẹnuwo rẹ pẹlu BBC Yoruba

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Woli Arole

Adẹrinponṣonu Woli Arole naa kede pe oun fẹ darapọ mọ awọn orilẹede Naijria to n gbero lati gba ami ẹyẹ naa.

Arole ni oun fẹ ṣe agbekalẹ eto adura fun ẹgbẹrun marun un wakati, eyi ti yoo jẹ akoko to pọ ju fun adura gbigba.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Adebiyi Israel fẹ wo fiimu fun ọpọ wakati

Adebiyi Israel, ọmọ bibi ipinlẹ Ekiti pẹlu awọn to n gbero lati gbe ami ẹyẹ naa, to si fẹ gba a pẹlu wakati to pọju ti eeyan fi wo sinima.

Akẹkọọ fasiti ipinlẹ Ekiti ọhun safihan iwe ti Guiness World Record fi fesi fun un lori opo ayelujara rẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Sugartee fẹ ṣe Ekiti Kiss-a-thon - Ijọba yari

Arakunrin kan to sapejuwe ara rẹ gẹgẹ bi Sugartee lo fẹ ṣe agbekalẹ fifi ẹnu kora ẹni lẹnu fun wakati to pọju lọ lagbaye ṣugbọn ijọba ipinlẹ Ekiti ti kilọ pe irufẹ igbesẹ naa ko gbọdọ waye.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Instagram.com/iam_sugartee/

Ẹwẹ, Ijọba ipinlẹ Ekiti fesi sita pe bi ẹnikẹni ba dan iru idije ifẹnukonu yii wo ni Ekiti, yoo fi ẹwọn ọdun mẹta jura.

Ọjọ mẹta ni ẹgbẹ Sugartee gbero lati fi ṣe idije naa tẹlẹ laarin ọjọ Keje Oṣu Keje si ọjọ Kẹwa Oṣu Keje amọ ijọba ta wọn ji loju ala wọn pẹlu fifi ẹwọn kilọ fun wọn.

Oluwatobi Kufeji kọ orin iyin fun wakati 200

Oluwatobi Kufeji, ẹni ọdun mọkandinlogoji lo kọrin fun igba wakati nipinlẹ Eko.

Arakunrin yii ni tirẹ ti pari iye wakati to ni oun fẹ lo fi kọ orin yii gẹgẹ bo ṣe gbe gbogbo rẹ jade loju opo ayelujara rẹ.

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 3

Joy Chukwudi bẹrẹ si ni to ara amọ o lulẹ

Joy n to ara

Oríṣun àwòrán, Joy Chukwudi/Instagram

Arabinrin yii lo n gbinyanju lati to ara fun wakati marundinlaadọrun ṣugbọn o ṣubu, to si lulẹ.

Aadọta wakati pere lo ri yanju, to si kuna lati gba ami ẹyẹ naa.

Ki ni a n pe ni Guinness World Record?

Guinness Book of Records jẹ iwe ti wọn fi maa n ṣe akọsil̀ẹ awọn nnkan ribiribi to ba waye laarín awọn eeyan ati awọn nnkan to j́ẹ alumọnì.

Ni ọdun 1955 ni wọn ḱọkọ fi ìwe yii lede ni Ireland, lati ìgba naa lo sì ti j́ẹ ìwe ti awọn eeyan maa n ka lati fi t́ọka nnkan.

Ki orukọ enìyan to le wọ iwe yii, onitọhun gbọdọ ṣe ohun to tayọ, ti awọn to n mojuto eto yìí yoo sì ṣe ayẹwo rẹ.