Èdè Yorùbá ni Àbọrú Àbọyè, kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú Ifá, Òrìṣà - Tope Alabi fọhùn lórí àwọn tó ń ta kò ó

Tope Alabi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gbajugbaja olorin ẹmi, Tope Alabi ti fesi si fọnran kan to da arinyanjiyan silẹ lori ayelujara nibi to ti lo ede Yoruba kan, iyiun "Aboru Aboye" ninu orin rẹ.

Ọrọ yii jẹ eyi ti awọn eeyan gbagbọ pe ohun ikini lo jẹ fun awọn alawo nilẹ Yoruba ti wọn si bẹrẹ si ni tutọ soke foju gba a pe kilode ti Tope Alabi lo o fi kọrin yin Ọlọrun ni ilana Kristẹni.

Ninu Fọnran ọhun, Alabi sapejuwe ara rẹ gẹgẹ ohun ẹbọ.

O ni; "Abiye ni mi, Orukọ mi niyẹn. Mo dẹ bọ, mo ru, mo ye ..."

Awọn ọrọ wọnyii lo da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ laarin awọn ololufẹ rẹ ati awọn olori ẹsin ibilẹ lori ọrọ ti o lo naa.

Ki ni Tope Alabi sọ gan?

Tope Alabi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ninu fọnran miiran to jade lori ayelujara, a ri olorin ẹmi naa to n fesi si ọrọ yii ni ede Yoruba pọnbele ninu ile ijọsin kan ti wọn ti pe e ko wa kọrin.

Tope Alabi ni ede Yoruba pọnbele ni Aboru Aboye jẹ, ti ko si ni nkankan se pẹlu alawo.

"O ni: "Dafidi si ru ẹbọ ododo si Ọlọrun", o wa beere ibeere pe "kilode ti wọn o ṣe sọ ọ sinu bibeli Yoruba pe ko ki nse bẹẹ lo yẹ ko ri?"

"Ko si ede kan fun ede awo, gbogbo wa ni a n sọ Yoruba.

"Ti awọn kan ba ni irufẹ asa ti wọn ni yẹn, ko si nnkan to buru nibẹ, awa naa dẹ maa mu u nitori pe a fẹ ẹ".

"O wa ninu Bibeli, a ru ẹbọ, ti ẹbọ si ru, o gba

"Ti Isaac si ye.

"Abi ko ye?"

Tope Alabi wa rọ awọn olujọsin lati fi ara fun Ọlọrun gẹgẹ bi ẹbọ aaye.

"Ti ẹbọ ba ru ni pe o jẹ itẹwọgba".