Ǹjẹ́ ó ṣeéṣé kí iná mọnamọna wà lára igi? - Ọ̀jọ̀gbọ́n ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awọn fọnran kan lo ti gba ori ayelujara, to si ṣafihan bi giloobu ṣe mu ina jade lẹyin ti wọn fi idi rẹ kan ara igi.
Ọrọ ọhun lo fa ọpọlọpọ awuyewuye ni ilu kan lorilẹede Kenya lẹyin ti wọn kede pe ara igi ni wọn ti n mu ina jade fun lilo agbegbe naa.
Ninu fọnran kan lori Youtube lo ti jade.
"Ẹ ha igi, wọn ko ri ina. Ti wọn ba fi ha igi mẹwaa, ti ina ko jade, wọn yoo dawọ isẹ duro."
Eyi ni ọrọ ti Ọjọgbọn Idowu Farai, onimọ nipa imọ ẹkọ Physics ti fasiti Ibadan sọ fun BBC.
Oriṣi ọna ti awọn fi n mu ina wa

Oríṣun àwòrán, YOUTUBE
Oriṣiriṣi ọna ni awọn eeyan ti gbe jade ti wọn ni awọn fi n tan ina latigba ti ọwọngogo ọpọlọpọ nnkan ti bẹ silẹ lorilẹede Naijiria.
A ti fi ọrọ wa ọdọkunrin kan lẹnu wo to ni onu lee mu ina jade latara okuta.
Bakan naa, awọn eeyan ti ti fi fidio sita ti wọn n lo afẹfẹ gaasi lati mu ina jade latara ẹrọ amunawa.
Koda a ri fọnran kan ti ẹnikan ti fi giloobu kan nnkan ọmọkunrin rẹ, ti ina si jade.
Lara eyi ti a fi ṣewadii lẹnu ọjọgbọn ti BBC ba sọrọ naa ni ti arakunrin kan ni ipinlẹ Ekiti, orilẹede Naijiria ti fidio rẹ gba ori ayelujara nibi to ti n fi giloobu kan ara igi ti wọn bo epo ara rẹ ti ina si n ta.
Eyi jẹ iyalẹnu fun awọn eeyan ti awọn mii si n sọ pe irọ gbaa ni.
Bi ina mọnamọna ṣe jade ninu fọnran ti a ri
Ọjọgbọn Farai ṣalaye pe, "bi awọn eeyan se n bere nipa ọrọ ina ni gbogbo igba n mu ka fi apọnle fun nnkan ti ko yẹ ka fun ni apọnle.
Nipa bi ina ṣe wa lara igi ninu fọnran to wa lori ayelujara, Ọjọgbọn Farai ni o jẹ nnkan ti ko ṣeeṣe ki ina wa lara igi.
Ọpọlọpọ fọnran miiran lo ti jade lori boya ṣe lootọ ni ina mọnamọna wa lara igi sugbọn pabo ni igbinyanju wọn jasi.
Onimọ miiran, Simeon Anieloka naa sọrọ lori ọrọ yii, o ni: "Ajọsepọ wa laara igi ati giloobu ati pe ina ara igi to kere, nitori rẹ ni wọn ni lati ha igi naa, ki wọn to gbe giloobu sii ati pe ina wa lara giloobu naa tẹlẹ!"
"Igi gan an ni ẹmi fun ara rẹ, fun idi eyi, ti ina ba maa wọ ara igi, igi naa maa ku nitori bii pe ara san pa igi naa ni. Ohun to wa sẹlẹ si awọn eeyan naa ni yẹn.
Onimọẹrọ Anieloka tẹsiwaju, "Ti ẹ ba ge igi, o ti ṣe afihan inu igi naa sita, fun idi eyi, ti ẹ ba fi giloobu sii, igi yoo sisẹ gẹgẹ alajọsepọ, eyi lo fa a ti ina fi jade.
"Ti ẹ ba fi giloobu naa kan ara eeyan, ina yoo jade nibẹ".












