Àrùn Diphtheria pa ọmọ ọdún mẹ́fà nípìnlẹ̀ Osun

Gómìnà Adeleke

Oríṣun àwòrán, Mallam Olawale

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ti pàṣẹ pe ki awon ibudo itọju pajawiri bẹ̀rẹ̀ ni kiakia, lati le koju àrùn Diphtheria nipinlẹ naa.

Olawale Rasheed, to jẹ akọ̀wé ikede fun gomina, lo fi ikede naa sita ninu atẹjade kan lọjọ Aje, gẹ́gẹ́ bi Iwe iroyin Cable ati awọn ileeṣẹ iroyin mii ṣe sọ.

Igbesẹ naa waye lẹyin ti ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Osun kede pe àrùn naa ti wa nípìnlẹ̀ ọ̀hún. Ọgbẹni Rasheed sọ pe awọn alaṣẹ eto ilera ní àrùn naa ti pa ọmọ ọdun mẹfa kan.

O ni "ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹfà, ni ọmọdebinrin naa bẹ̀rẹ̀ si ni fi àwọn àmì àrùn naa han, kó tó di pe o kú ni ọjọ keje, oṣu Keje.

O fikùn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pe ẹlòmíì ti wọn fura si pe o ni àrùn naa, ti n ṣe àyẹ̀wò bayii, ti gomina si tun pàṣẹ pe ki wọn tete wa awọn to ti ni ìbá pàdé pẹ̀lú wọn fun ayẹwo.

Àjọ NCDC sọ pe eeyan bii 789 ni àrùn naa ti ràn, ọgọrin si ti ku.

Ipinlẹ Kano, Lagos, Yobe, Katsina, Cross River, Kaduna, Osun ati ilu Abuja ni àrùn naa ti wà bayii.

A ṣi n ṣe àkójọpọ̀ iroyin yii lọwọ

Kini awọn ami ti yoo farahan ti eniyan ba lugbadi aarun Diphteria

  • Aran gbigbona
  • Iba
  • Aile jẹun daradara
  • Ẹnu wiwu
  • Aile mi daradara
  • Catarrh ati ikọ wiwu
  • Ara riro ati ara rirẹ

Kini ọna lati dena arun Diphteria?

Awọn dokita ni ọna kan gboogi lati dena itankalẹ aarun naa laarin agba ati ọmọde ni lati gba abẹrẹ ajẹsara naa. Wọn ni abẹrẹ yii yoo ba aarun naa ninu ara. Bakan naa lo pọn dandan ki awọn eniyan ni imọ nipa abẹrẹ ajẹsara fuin awọn ọmọde nitori igbagbọ wa pe eyi yoo koju ikọ wiwu, ẹyin to jẹra ati igbona.