Èèyàn 42, dúkìá tówó rẹ̀ tó N14.62b ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì lọ lóṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ 2023 l'Eko

Aworan ile kan to dawoni ilu Eko

Ileeṣẹ panapana nipinlẹ Eko ni eeyan mejilelogoji lo ku ninu ijamba ina, ibugbamu ati ile wiwo ni ipinlẹ naa laarin oṣu kini si ikẹfa ọdun 2023.

Laarin asiko yii kan naa, iṣelẹ ijamba ina ẹẹdẹgbẹrun ati mẹrinlelogun (924) lo waye ni ipinlẹ Eko lapapọ.

Ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko sọ eyi ninu abajade iṣẹ iriju rẹ fun ilaji akọkọ ọdun 2023.

Adari ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko, Adeseye Margaret Abimbola ni ọkan lara opo ijọba Babajide Sanwoolu ni ki isẹlẹ ijamba dinku nipinlẹ ọhun.

O ni dukia ti owo rẹ to biliọnu mẹrinla ati miliọnu mejilelọgọta naira (N14.62b) lo ṣegbe sinu awọn iṣẹlẹ ajalu to waye laarin saa naa.

Atupalẹ iṣẹlẹ pajawiri laarin oṣu kini si ikẹfa ni ipinlẹ Eko

Aworan

Oríṣun àwòrán, Ileesẹ Panapana

  • Iṣẹlẹ pajawiri ẹgbẹrun kan ati ojilelẹẹgbẹta o le meji (1642) lo waye.
  • Eeyan mejilelogoji (42) lo ku.
  • Eeyan mẹtadinlọgọsan (177) ni wọn doola ẹmi wọn.
  • Iṣelẹ ijamba ina ẹẹdẹgbẹrun ati mẹrinlelogun (924) lo waye
  • Iṣẹlẹ ibugbamu mẹta (3)
  • Ijamba ile wiwo meji (2)
  • Iye dukia to ṣegbe ninu awọn ijamba naa jẹ biliọnu mẹrinla ati miliọnu mejilelọgọta naira (N14.62b)
  • Iye dukia ti awọn oṣiṣẹ panapana doola jẹ biliọnu mẹtadinlaadọrun ati ẹẹdẹgbẹrun o le meji miliọnu naira. (N87.72billion)

Ọga agba ileeṣẹ panapana nipinlẹ Eko ni isẹlẹ ijamba wọpọ lọdun yi ju ọdun to kọja lọ.

"Iwadii fihan pe ailakasi awọn eeyan wa lo sokunfa bi ijamba ṣe n wọpọ sii ati pe bi awọn eeyan se n pe ipe pajawiri lori irọ jẹ ohun kan to ku diẹ kaa to.

Ọga agba wa rọ awọn olugbe ipinlẹ Eko lati yago fun iwa to le sokunfa ijamba ina , to si fi da wọn loju pe Ileeṣẹ panapana wa fun wọn ni igba gbogbo.