NPF RESCUE ME APP: Wo bí o ṣe lè sáré fi "App" yìí kàn sí Ọlọ́pàá bóo bá wà nínú ewu

Oríṣun àwòrán, adejobi.olumuyiwa
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti rọ araalu lati ṣamulo aapu tuntun kan ti wọn sọ pe yoo fun wọn lanfaani lati kan si wọn lasiko pajawiri.
Adele ọga patapata ileeṣẹ ọlọpaa Olukayode Egbetokun lo fidi ọrọ yi mulẹ to si ni kawọn ọmọ Naijiria ṣamulo aapu yi torukọ rẹ n jẹ “NPF Rescue Me App”.
Alukoro ọlọpaa Muyiwa Adejobi ninu atẹjade to fi sita ṣalaye pe agbekalẹ aapu yi wa lara awọn igbesẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa n gbe lati rii pe wọn tati were si ọrọ to ba kan araalu.
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye wọn le ri aapu yi loju opo Play Store yala fun android tabi ẹrọ ibanisọrọ to n lo iOs.
Bakan naa ni Olumuyiwa sọ pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ti paṣẹ fawọn ẹka iwadii lati tara ṣaṣa ṣe agbende awọn irinṣẹ ẹrọ tẹkinọlọji ti wọn yoo lo lati fi le ṣakojọ iroyin awọn afurasi.
O ni yoo jẹ ki iwadii gunrege isi ju ti tẹlẹ lọ ti gbogbo oṣiṣẹ ọlọpaa yoo si lanfaani lati lo awọn iroyin yii.
Kini ero araalu lori igbesẹ yii?
Atẹjade ti Muyiwa Adejobi fi sita ko sọ pato ọna ti aapu yi yoo ṣe maa gba ṣiṣẹ amọ awọn araalu kọọkan ti n sọ ero wọn lori rẹ.
Bawọn kan ṣe n gboṣuba kare fun igbesẹ yi lawọn ẹlomiran n beere pe ṣe kii ṣe ọna ti ọlọpaa yoo ma fi tọ pinpin awọn araalu ni aapu yi jẹ.
Bakan naa lawọn miran n sọ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa wa ọna ti wọn yoo fi pese kamẹra alasomọra fawọn oṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi ọna lati mu idagbasoke ba iṣẹ agbofinro ni Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2

End of X post, 3
Ibaṣepọ laarin ọlọpaa ati awọn araalu ni Naijiria jẹ eleyi ti araalu ko fi taratara ni igbagbọ ninu awọn agbofinro.
Ileẹṣẹ ọlọpaa a maa sọ pe ọrẹ araalu ni ọlọpaa jẹ ṣugbọn awọn kọlọrọsi kan lara oṣiṣẹ wọn a maa tẹ ẹtọ araalu mọlẹ nipa ṣiṣe iṣẹ wọn.
Bi a ko ba gbagbe ariwo lori idẹyẹsi ati idunkoko ọlọpaa si araalu lo mu ki wọn tu ikọ SARS ọlọpaa ka ti eleyi ko si tori rẹ ni ki araalu fi ọkan tan ọlọpaa.
Aarẹ tuntun Bola Ahmed Tinubu ṣẹṣẹ kede adele ipo ọga ọlọpaa tuntun iyẹn Kayode Egbetokun ti ireti si wa pe iṣakoso rẹ yoo mu iyipada ba iṣẹ ọlọpaa ni Naijiria ni kopẹ kopẹ.