Wo ipenija pàtàkì mẹ́ta tí Tinubu yóò kojú gẹ́gẹ́ bí Alága ECOWAS

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat
Ni kete ti olori tabi alaṣẹ ba gba iburawọle sipo tan , lọpọ igba wọn a maa sọ erongba wọn ati ohun ti wọn gbeero lati koju lori ipo naa.
Bẹẹ lọrọ ri nigba ti aarẹ Naijiria Bola Ahmed Tinubu gba ipo Alaga ajọ ECOWAS laipẹ yi.
Ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ aarẹ Tinubu, Abdul'aziz Abdul'aziz,ṣe ẹkunrẹrẹ alaye fun BBC lori ọrọ ti Aarẹ sọ niwaju awọn akẹgbẹ rẹ lẹyin ti wọn dibo yan sipo.
O ni Tinubu sọ pe ''Niṣe ni apọnle n deba Naijiria si loju awọn orileede agbaye eyi lo si mu ki wọn gbe ipo alaga ajọ Ecowas fun aarẹ Naijiria tuntun yi.''
O ni ''ṣe ẹ mọ pe ni nkan bi oṣumeji sẹyin ni wọn dibo yan Tinubu si ipo aarẹ Naijiria amọ ipo Naijiria ti ijẹ eeyan alapọnle rẹ lo mu ki wọn gbe ipo alaga yi fun.
Lẹyin alaye yi o wa ṣatipalẹ awọn koko pataki mẹta ti Tinubu yoo doju kọ gẹgẹ bi alaga ajọ Ecowas.

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat
Aabo ati Alaafia
Ko jẹ tuntun taa ba sọ pe agbegbe iwọ oorun Africa ti ọpọ awọn ọmọ ajọ Ecowas ti wa n koju ipenija aabo/
Eyi jẹ ọkan pato ninu ohun ti aarẹ Tinubu sọ pe oun yoo koju. to si ni o to asiko lati mu opin ba ipenija yi.
''Ni ti aabo to peye ati alaafia,ipenija yi ti wa doju rẹ debi pe o di dandan lati wa wọrọkọ fi ṣada lori ọrọ ọhun.''
Ọrọ ree lẹnu aarẹ Naijiria to tun jẹ alaga ajọ Ecowas tuntun.
O tẹsiwaju pe ''Ko si iye meji pe aisi alaafia ati aabo yoo tubọ maa jẹ ifasẹyin fun idagbagsoke agbegbe wa''
O ni ''bayi, o di dandan lati maa fi tọkantọkan yanju awọn eto ati ilana taa la kalẹ lati le fi mu opin ba awọn ipenija aabo taa n koju.''
Tinubu mẹnu ba bi ipenija aabo lọwọ awọn agbesunmọmi bi Boko Haram ati ISWAP ṣe n mu ifasẹyin ba agbegbe naa.
O ni ipenija yi ti n tan kaakiri de awọn ibomiran ti ko de tẹlẹ.
Fifi ẹsẹ ijọba awarawa rinlẹ
Ọrọ jẹyọ lori koko pataki yi nibi ipade ikẹtalelọgọta ajọ Ecowas to n lọ lọwọ ni Guinea Bissau.
Ko si sẹyin bi awọn orileede kan ninu ajọ yi ti ṣẹ n yẹ kuro loju ọna ijọba awarawa nitori ifipagbajọba awọn ọmọ ogun.
Mali, Burkina Faso and Guinea, to jẹ ọmọ ẹgbẹ yi wa labẹ ijọba ologun lọwọlọwọ bayii.
Aarẹ Tinubu loun yoo lo anfaani ipo alaga ajọ yi lati ri wi pe wọn da awọn orileede yi pada si oju ọna ijọba awarawa.
O lawọn yoo ṣe eleyi nipa ṣiṣe eto idibo to yanranti ti araalu yoo si yan awọn olori lati ọwọ ara wọn.
Abdul'aziz fi kun pe ''Aarẹ fẹ ri daju pe ko si ijọba ologun ati pe ijọba awarawa ni yoo fẹsẹ rinlẹ lati le fun awọn eeyan orileede yi lanfaani yiyan ẹni to ba wu wọn sipo.''

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat
Eto owo nina kan naa(Single Currency)
O ti to ọjọ mẹta ti wọn ti n sọrọ nipa owo ina kan ṣoṣo lapapọ fawọn orileede ajọ Ecoiwas.
Abdul'aziz sọ pe aarẹ Tinubu mẹnu ba ọrọ yi to si ni ṣamulo rẹ yoo mu agbega ba eto ọrọ aje agbegbe naa.
Yoo si tun mu adinku ba iṣoro nina owo laarin awọn orileede ọmọ ẹgbẹ yi.
Lọdun 2020 lawọn orileede kan ninu ẹgbẹ yi gba lati bẹrẹ si ni na owo kan naa.
Ṣugbọn orileedeNaijiria ni ki wọn dawọ nina rẹ duro fun igba diẹ.
Idi si ni pe Naijiria ni pupọ awọn orileede ni ko yi ribi kaju osunwọn ti o yẹ latiu le maa ṣe ajọlo owo yi.
Ni bayii ti aarẹ ti mẹnu ba o ṣeeṣe ko ni lọkan pe asikoti to bayii lati ṣamulo nina owo kan ṣoṣo fawọn ọmọ ẹgbẹ Ecowas.
ECOWAS kéde Ààrẹ Tinubu gẹ́gẹ́ bí Alága

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Tinubu
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ni wọn kede gẹgẹ bi alaga Ajọ ECOWAS fun gbogbo orilẹede adulawọ.
Igbesẹ yii ni wọn kede nibi ipade mẹtalelọgọta ti ajọ ọhun to waye niluu Bissau, to jẹ olu ilu orilẹede Guinea-Bissau.
"A mu ijọba awarawa lọkunkundun, ijọba awarawa lo le pupọ sugbọn o le di ijọba mu." eyi ni ọrọ Aarẹ Tinubu lẹyin to tẹwọgba iwe ipo naa lọwọ alaga to kogba wọlẹ, iyin Aarẹ Guinea Bissau, Umaro Embalo.
Ipo alaga ECOWAS lo jẹ ipo kan ti awọn olori orilẹede to wa ninu ajọ ọhun ma dimu fun ọdun kan.
Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijria, Muhammadu Buhari lo di ipo naa mu ni ọdun 2018 si 2019.
Ohun to yẹ ko mọ nipa ECOWAS
Ajọ ECOWAS ni wọn da silẹ lọjọ kejidinlọgbọn ọdun 1975 nibi apero kan to waye niluu Eko lorilẹede lati ibasepọ awọn orilẹede adulawọ ni apa iwọ oorun lọ lia si wahala
Orilẹede mẹdogun ni wọn buwọlu lati darapọ ajọ naa.
Awọn ni Benin, Burkina Faso, Cabo Verde or Cape Verde, Cote D'Ivoire, The Gambia, Ghana, Guinea, Guinea Bissau, Liberia, Mali, Niger, Nigeria, Senegal, Sierra Leone ati Togo
Lati igba ti wọn ti ECOWAS silẹ, Aarẹ orilẹede Naijiria to ti jẹ alage ree
- Yakubu Gowon - 1975 - 1975
- Olusegun Obasanjo - 1977- 1979
- Muhammadu Buhari - 1985 - 1985
- Ibrahim Babangida - 1985 si 1989
- Sani Abacha - 1996 - 1998
- Abdulsalami Abubakar 1998 - 1999
- Umaru Musa Yar'Adua - 2008 - 2010
- Goodluck Jonathan - 2010 2012
- Muhammadu Buhari - 2018 - 2019












