'Ganduje lẹ́jọ́ láti jẹ́ lórí fídíò gbígba dọ́là'

Abdullahi Ganduje

Oríṣun àwòrán, SALIHU TANKO

Àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu ní ìpínlẹ̀ Kano ní àwọn ti kọ̀ọ̀wé ránṣẹ́ sí gómìnà àná ní ìpinlẹ̀ náà Abdullahi Ganduje láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí fídíò kan tó gba ìgbòro lọ́dún 2017, nígbà tó ṣì wà nípò.

Àtẹ̀jáde kan tí àjọ náà fi léde ní àwọn ránṣẹ́ pé Ganduje láti wá wẹ ara rẹ̀ mọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn náà pé ó ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kọńgílá èyí tí ìwádìí rẹ̀ ṣì ń lọ lọ́wọ́.

Ní ọdún 2017 ni iléeṣẹ́ ìròyìn kan, The Daily Nigerian gbé fídíò kan jáde tó ṣàfihàn bí ọkùnrin ṣe ń gba owó dọ́là lọ́wọ́ agbaṣẹ́ṣe kan tó sì ń kó àwọn owó náà sínú àpò agbádá tó wọ̀.

Wọ́n fẹ̀sùn kan pé Ganduje ló wà nínú fídíò náà tó ń gba owó lọ́wọ́ agbaṣẹ́ṣe kan tí ìjọba gbé iṣẹ́ fún.

Fídíò náà fa onírúurú awuyewuye ní Nàìjíríà nígbà náà pàápàá lórí ayélujára ní èyí tó ṣokùnfà tí ilé aṣòfin Kana lásìkò náà fi gbé ìgbìmọ̀ kan díde láti ṣèwádìí ẹ̀sùn ọ̀hún.

Adarí àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu ní Kano, Muhyi Magaji Rimi Gado ní òun ti buwọ́lu ìwé láti fi ránṣẹ́ pe Ganduje láti wá wí tẹnu rẹ̀ fún àjọ náà ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀.

Rinmi Gado ní nǹkan tí òfin sọ ni àwọn ń tẹ̀lé tí àwọn sì ti fun Ganduje láàyè láti wá wẹ ara rẹ̀ mọ́ lórí ẹ̀sùn náà.

Wọ́n ní láti ìgbà tí fídíò ọ̀hún ti gba orí ayélujára ni àwọn ti fẹ́ ṣe ìwádìí Ganduje àmọ́ òfin atóbi má ṣè é báwí ìyẹn “immunity” tó ní gẹ́gẹ́ bí gómìnà ni wọn kò fi rí ìwádìí náà ṣe nígbà náà.

Ẹ̀wẹ̀, Kọmíṣọ́nà fétò ìròyìn tẹ́lẹ̀ ní Kano, tó tún jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Ganduje, Mallam Muhammad Garba ní àwọn kò ì tíì rí ìwé ìpè kankan tí àjọ náà ni àwọn ti fi ránṣẹ́ sí Ganduje.

Lórí ẹ̀sùn tí Ganduje ń kojú, Garba ní òun kò ní sọ ohunkóhun nípa rẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà ti wà ní ilé ẹjọ́.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ganduje náà ti jiyàn wí pé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun kìí ṣe òótọ́, pé àwọn alátakò ni wọ́n gbèrò ọ̀tẹ̀ náà láti lè dí òun lọ́wọ́ láti má le kópa nínú ìbò ọdún 2019.

Nínú oṣù Keje ọdún 2021 ni Ganduje yọ Muhyi Rimin Gado nípò olórí àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu lẹ́yìn tí ìjọba fẹ̀sùn kàn-án pé ó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ ètò ìsúná kan.

Lẹ́yìn-ò-rẹyìn ni ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n dá Muhyi padà sípò rẹ̀ àmọ́ ìjọba tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wà nípò ló pé Rimin Gado padà ṣẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ báyìí.

Rimin Gado nínú àtẹ̀jáde náà fi kun pé tí àwọn bákọ̀ láti ṣe ìwádìí Ganduje lórí ẹ̀sùn náà yóò tàbùkù ìpínlẹ̀ Kano ní Nàìjíríà àti lókè òkun.

Àwọn alátakò ló fẹ́ fi fídíò náà rẹ́yìn Ganduje

Mallam Muhammad Garba ní òṣèlú lásán ni àjọ tó ránṣẹ́ pe Ganduje fẹ́ fi ìwádìí wọn ṣe, wí pé wọ́n kàn fẹ́ tàbùkù Ganduje ni.

Ó ní wọn ò fẹ́ kí ìjọba àpapọ̀ fún Ganduje ní ipò mínísítà ni wọ́n fi hú ẹ̀sùn náà síta láti ṣe ìwádìí rẹ̀ báyìí.

Garba ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu pé irú nǹkan báyìí tún ń dìde àti pé kò yẹ kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba máa gbà láti jẹ́ kí wọ́n lo àwọn fọ́rọ̀ òṣèlú.

APC ti sọ fún Ganduje láti má yọjú níwájú àjọ náà

Kọmíṣọ́nà tẹ́lẹ̀ rí náà ṣàlàyé pé òun mọ́ wí pé ẹgbọ́ òṣèlú APC tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Kano ti sọ fún Abdullahi Ganduje láti má yọjú síwájú ìgbìmọ̀ tó ránṣẹ́ pè é.

Ó ní àmọ́ pẹ̀lú ìkìlọ̀ ẹgbẹ́ yìí Ganduje ṣì máa kàn sí àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ láti mọ ìgbésẹ̀ tó yẹ kó gbé nítorí ẹjọ́ fídíò náà wà nílé ẹjọ́ gíga Abuja.

“Mo rò wí pé pẹ̀lú pé ẹjọ́ náà ti wà nílé ẹjọ́, kò yẹ kí àjọ kankan tún máa ránṣẹ́ pe Ganduje mọ́.”

“Tí àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ bá ní kó lọ yọjú sí àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu náà, kò sí ohun tó máa dá dúró láti yọjú sí wọn.”

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ alága tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Kano, bdullahi Abbas àti akọ̀wé ẹgbẹ́, Zakari Sarina ní ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ti ṣo ọ̀rọ̀ fídíò náà di ọ̀rọ̀ òṣèlú.”

Àtẹ̀jáde náà ni ọ̀rọ̀ tó ti wà níwájú ilé ẹjọ́ ni wọ́n tún lọ ń hú jáde láti fi tàbùkù gómìnà àná náà.

Ó ní wọ́n gbé irú ìgbésẹ̀ náà ní ọdún 2019 kí Ganduje má ba à fi rí sáà kejì àmọ́ ó bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.

‘Ìwádìí sáyẹ́ǹsì fìdí fídíò náà múlẹ̀’

Ní ọjọ́rú ni àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu Kano ní ìwádìí àwọn pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ sáyẹ́ǹsì ti fi hàn lóòótọ́ ni fídíò ọ̀rọ̀ owó dọ́là náà.

Rimin Gado fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nígbà tó ń bá àwọn iléeṣẹ́ aládàni kan sọ̀rọ̀ tó sì tún ṣe àfihàn fídíò náà.

Ó ní ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé láti fìdí òótọ́ àwọn fídíò tó bá ṣókùnkùn sí ni [[ni àwọn lò láti fi ṣe ìwádìí fídíò náà.

Àmọ́ àjọ náà kò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn nípa àwọn nǹkan tí àwọn oníwàdìí náà lò láti fi òótọ́ múlẹ̀ lórí fídíò náà.