Makinde ṣe ìlérí láti parí aáwọ̀ láàrin Fasoranti àti Adebanjo

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ti ṣe ileri lati yanju aawọ to wa laarin Pa Reuben Fasoranti ati Baba Ayo Adebanjo tí ẹgbẹ Afenifere.

Makinde sọ eleyi niluu Ibadan lẹyin to ṣe ipade pọ pẹlu awọn adarí ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Afenifere lori yiyanju aawọ to wa laarin awọn agba ẹgbẹ mejeeji.

O tẹsiwaju pe eto idibo ti kuro bayi, ti asiko si ti to lati mu isọkan wa ni ilẹ Yoruba, ti oun ati awọn adarí kan ninu ẹgbẹ Afenifere sì ti mu ni isẹ lati yanju aawọ naa.

"A mọ nnkan to n lọ laarin olori Afenifere mejeeji. Lasiko yii ti eto idibo ti lọ, a ni lati jẹ alaafin ati isọkan wa nilẹ Yoruba

"A mọ pe ti awọn Baba mejeeji yii ba ti pada, isọkan ti a fẹ lorilẹede Naijiria yoo wa si imusẹ.

"Tí a ba wo, ti ile Yoruba ba ti wa ni isọkan, orilẹede Naijiria naa ti wa ni isọkan tí ija ba si bẹẹ silẹ ni ilẹ Yoruba, gbogbo Naijiria ni nnkan ṣe

"Mo n fi da yín loju pe a ti bẹrẹ isẹ lori igbesẹ yii ati pe dundun ni ọsan yoo so fun wa."

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni Kola Omololu, Jare Ajayi, Oloye Eric Oluwole, Dare Babarinsa, Oloye Korede Duyile, Oloye Leke Mabinuori Hon Bakkita Olufowobi Bello ati Oloye Diran Adesua.

Awọn yooku nias Dokita Gbola Adetunji, Dokita. Akin Onigbinde (SAN) Oloye Babatunde Tijani ati Chief Mrs. Bola Doherty, ati awọn miiran.