Báyìí ni ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ níwájú ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ lónìí

Atiku, Obi àti Tinubu

Oríṣun àwòrán, COLLAGE

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó àwọn ẹ̀rí rẹ̀ kalẹ̀ láti wẹ ara rẹ̀ mọ́ níwájú ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ntó fi ìlú Abuja ṣe ibùjókòó.

Tinubu àti àjọ elétò ìbò Nàìjíríà, INEC ni Peter Obi, olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party àti Atiku Abubakar, olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ń pè lẹ́jọ́ lórí ètò ìdìbò Ààrẹ ọdún 2023.

INEC ti kó àwọn ẹ̀rí wọn síwájú ilé ẹjọ́ láti tako ẹjọ́ tí PDP àti Labour Party pè pé àwọn ni àwọn borí ìbò náà.

Ẹlẹ́rìí kan ni INEC gbé síwájú ilé ẹjọ́ tí wọ́n sì kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé kalẹ̀ láti fi ìdí ọ̀rọ̀ wọn múlẹ̀ tí ilé ẹjọ́ náà sì gbà wọ́n wọlé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tó yanrantí.

Ní ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹfà ọdún 2023 ni ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò náà wọlé ìjókòó padà lẹ́yìn tí wọ́n lọ fún ìsinmi nígbà tí Atiku àti Obi ti fi ẹ̀rí wọn múlẹ̀ tán.

Dókítà Lawrence Bayode, tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ INEC ni ẹlẹ́rìí tí INEC gbé wá sílé ẹjọ́, tọ sì gbé àwọn ẹ̀rí rẹ̀ síwájú ilé láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Bola Tinubu ló jáwé olùbóri ìbò náà.

Ẹ̀wẹ̀, Agbẹjọ́rò Atiku Abubakar, Chris Uche ní kí ilé ẹjọ́ má gba àwọn ẹ̀rí náà wọlé, tó sì ṣe àgbékalẹ̀ ìjábọ̀ àjọ EU lórí ètò ìdìbò náà.

Uche bèèrè lọ́wọ́ Bayode bóyá ó ti rí ìjábọ̀ náà, ó ní òun ti ri àmọ́ òun kò ì tíì kà á.

Ọ̀la ni ìgbẹ́jọ́ yóò tún tẹ̀síwájú.

Kíni ká máa retí ní ìgbẹ́jọ́ ètò ìdìbò ààrẹ tó tẹ̀síwájú lónìí

Aworan

Igbẹjọ esi idibo sipo aarẹ ti ọ̀un 2023 n tẹsiwaju ni ileẹjọ kotẹmilọrun ni Ọjọ Aje, Osu Keje, ọdun 2023.

Saaju ni wọn ti dawọ duro lati Ọgbọnjọ, Osu Kẹfa, ọdun 2023 lẹyin ti awọn olupẹjọ lati ẹgbẹ oselu Labour Party ati PDP pari fifi ẹri wọn han.

Awọn ẹgbẹ oselu mejeeji naa ni wọn tabuku esi idibo to gbe Bola Ahmed Tinubu wọle gẹgẹ bi aarẹ lorilẹede Naijiria.

Wọn ni ajọ eleto idibo INEC se magomago pẹlu esi idibo naa.

Awọn adajọ marun un ti wọn gbo ẹjọ naa gba awọn ẹri awọn olupẹjọ naa wọle lẹyin ti igbẹjọ bẹrẹ lati bi ọsẹ mẹta sẹyin.

Aworan

Kini yoo waye loni?

Aworan

Awọn adajọ naa yoo bẹrẹ si ni gbọ awuyewuye ati awọn ẹri ti ẹgbẹ oselu APC ni lati tako ẹri ẹgbẹ oselu PDP ati Labour party.

Awọn ti yoo mu ẹri wa naa ni ẹgbẹ oselu APC ti aarẹ Bola Tinubu ati igbakeji rẹ, Shettima to fi mọ Ajọ eleto idibo, INEC.

Saaju ni Ajọ eleto idibo INEC ti ni awọn nilo ọjọ mẹta lati mu awọn ẹlẹri ti wọn wa, ti yoo fidirẹ mulẹ pe ko si magomago ninu eto idibo to gbe aarẹ Tinubu wọle.

Ati wi pe awọn tẹle ofin lati kede aarẹ Bola Ahmed Tinubu gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo sipo aarẹ naa.