Ruga Settlement: Osinbajo ta kété sí ọ̀rọ̀ Gàá Fúlàní

ỌJỌGBỌN YEMI OSINBAJO

Oríṣun àwòrán, PROF YEMI OSINBAJO/TWITTER

Àkọlé àwòrán, ỌJỌGBỌN YEMI OSINBAJO

Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn yemi Osinbajo ni oun kọ loun wa nidi amojuto akanṣe eto Ruga Settlement bi awọn kan ṣe n gbe iroyin rẹ ka.

Ninu atẹjade kan to fi sita, osinbajo ni ọtọ lohun ti wọn fi oun ṣe olori fun iyẹn Eto ayipada fun sinsin maalu ti awn gomina ipinlẹ fọwọ si labẹ akoso igbimọ eto ọrọ aje Naijiria.

Àkọlé fídíò, Kayefi BBC Yorùba: Bàbá ọmọ, Mọ́ṣúárì, Ọlọ́pàá kẹ́jọ́ rò nípa òkú ọmọ tó pòórá

Igbakeji aarẹ ni ọtọ ni Eto kikọ Gaa Fulani (Ruga Settlement) ọtọ ni Eto ayipada fun sinsin maalu (National Livestock Transformation Plan).

Awọn ile iṣẹ iroyin si royin pe akọwe agba ẹgbẹ ọlọsin maalu ni Naijiria, Miyetti Allah Cattle Breeders Association of Nigeria iyẹn Baba Uthman Ngelzarma lo sọ pe igbakeji aarẹ Osinbajo lo n ba awọn Fulani daran daran da Ruga Settlement silẹ kaakiri orilẹede naijiria.

Igbakeji aarẹ ni "ninu gbogbo eyi, ijọba apapọ ko ni mu ipinlẹ kankan ni dandan lati pese ilẹ fun eyi"