Africa in Pictures: Àwọn àwòrán tó jojú ní gbèsè láti Africa

Nibayii ti opin ọsẹ wọle de, ẹ jẹ ka pa ara wa lẹ́rin, ka si kọgbọn nipasẹ awọn ọkanojọkan aworan , eyi to wa lati ilẹ Afirika.

Awọn eeyan to n joko jẹun lori aga lori omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ibi ti aye ba ti ba ni laa tii jẹ, Awọn eeyan orilẹede Sudan kan ree ti wọn joko si eti odo ti omi funfun ati alaro odo Nile ti parapọ di ọkan
Ọkunrin kan to n jade kuro labẹ asọ to ti dibo

Oríṣun àwòrán, Sia Kambou

Àkọlé àwòrán, Ohun ti a ba fi pamọ, lo n niyi. Bi wọn se n dibo wọn ni bonkẹlẹ ree lorilẹede Mauritania lasiko idibo aarẹ to waye lọjọ Satide. ẹ ri pe asiri idibo bo pẹlu asọ
Ogunlọgọ ero to n yọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Kaabọ o, ṣe daada lo de. Awọn ololufẹ Jean-Pierre Bemba, tii se oloselu alatako ree, ti wọn lọ ki olori wọn kaabọ, nigba ti ileẹjọ to wa fẹsun ọdaran lagbaye kede pe Bemba ko lẹbi ẹsun ti wọn fi kan
Awọn ero to mu asia ilẹ Sudan lọwọ, ọkan tiẹ lẹ asia si ori

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, O ba ni, ko tii bajẹ, lawọn eeyan orilẹede Sudan n pariwo lẹyin tawọn ologun le aarẹ wọn. Awọn eeyan yii ko sọ ireti nu lori idibo, wọn si duro lati ki igbakeji olori igbimọ ologun kaabọ
Obinrin agbabọọlu meji n fori gbari lori ọdan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Haa, wahala de. obinrin agbabọọlu meji ree ti wọn lẹ ori pọ yii lọjọ Sunday. Raissa Feujio lati Cameroon ati Jill Scott lati ilẹ Gẹẹsi ni wọn lọpọ ninu ifẹsẹwọnsẹ fun ife ẹyẹ agbaye tawọn obinrin to n lọ lọwọ.
Awọn agbabọọlu Naijiria n yọ pẹlu ara wọn lori ọdan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, "Kare, ọmọ ni ẹ", eyi ni ọrọ tawọn agbabọọlu Naijiria n sọ fun Kenneth Omeruo lasiko ti wọn fa mọra, lẹyin to gba ami ayo wọle sile Guinea ninu idije AFCON 2019 to n lọ lọwọ
Awọn agbabọọlu Madagascar n jo lori ọdan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ijo ni majẹmu wa, ẹ sa jẹ ka jo. Orin yii ni awọn agbabọọlu Madagascar mu bọ ẹnu nigba ti wọn gba ami ayo wọ ile Guinea lọjọ Satide
Awọn eeyan meji to n ja niwaju ero iworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Eewọ. Ẹyin ologbo kii kanlẹ . Awọn eeyan kan to n mu ẹkẹ ree loju ija nilu Khartoum.