Mmesoma Ejikeme: Ọdún mẹ́ta ni JAMB sọ pé Mmesoma ko ni fi kàwé nílé ẹ̀kọ́ gíga kankan ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ajọ JAMB ti fofin de akẹkọọ ipinlẹ Anambra ti wọn fẹsun kan pe o ṣe magomago esi idanwo JAMB re.
Wọn sọ pe ile ẹkọ giga kankan ni Naijiria ko gbọdọ gba Mmesoma Ejikeme wọle gẹgẹ bii akẹkọọ rara fun odindin ọdun mẹta ni Naijiria.
Won ni pe eyi ni ijiya fun akiẹkọọ naa nitori pe o parọ pe oun gba odinwon maaki to sọ pe oun gba.
Akẹ́kọ̀ọ́ tí Jamb fẹsùn kan sọ̀rọ̀ síta, Ìjọba Ìpínlẹ̀ Anambra fèsì
Ejikeme Joy Mmesoma, Akẹkọọ tí Ajọ eleto idanwo Jamb fẹsun kan pe o se mọndaru esi idanwo rẹ tí ni irọ nla ni ẹsun naa.
Ninu fọnran kan to gba sorí ayelujara safihan bí akẹkọọ ọhun ṣe salaye bí irin ajo ṣe waye.
Akẹkọọ ọhun ni oun ko ni imọ lati yi esi idanwo oun pada ati pe ẹsun tí wọn fí kan oun ti fa arẹ si oun lara.
Fọnran ọhun safihan bi akẹkọọ ṣe mu esi idanwo rẹ dani.
"Emi ni mo ní esi idanwo yii. Orí opo ayelujara Jamb ni mo ti rí esi idanwo mi."
"362 ni mo gba, bi wọn ṣe ma wo esi idanwo ni mo ṣe wo lori ayelujara.
"Ohun tí Jamb n sọ pe mo yí esi idanwo mi jẹ nnkan ti n ko mọ nípa rara. Nigba ti wọn ni mo yí esi idanwo, wọn ṣe ayẹwo o gbe orúkọ ẹlomiiran jade, ti eeyan naa si gba 138 sugbọn nigba ti o ya, wọn yí pada si 318 to fihan pe isoro wa nibi kan."
Iwadii DSS ati awon nnkan mìíran tí Akẹkọọ naa sọ
Akẹkọọ ọhun salaye siwaju pe oun ati ọga agba ile ẹkọ rẹ mu esi idanwo ati atẹjisẹ tí Jamb fi ransẹ lọ fihan Kọmisọna fun eto ẹkọ nipinlẹ Anambra.
Kọmisọna ṣe ayẹwo, o si fi sọwọ pada si ajọ Jamb.
Ṣugbọn Ajọ Jamb fesi pada pe ayederu ni esi idanwo naa ati pe awọn ti ransẹ si ajọ DSS lati wa gbe awọn lọdọ Kọmisọna
"Àjọ DSS gbe wa lọ sí ọfisi wọn, a kọ ọrọ ẹnu wa silẹ tí wọn dẹ ni awọn yoo se iwadi lori esi idanwo naa sugbọn kaka kí ajọ duro de esi iwadi, wọn gbe jade pe mo ṣe mọndaru esi idanwo mi."
Ìjọba ìpinlẹ Anambra tí gbe ìgbìmọ kalẹ lati tan imọlę si ọrọ naa
Igbesẹ yii ni ijọba gbe lẹyin awuyewuye bẹrẹ lori tani o gba maaki ju lọ nínu idanwo Jamb.
Ọjọgbọn Ngozi Chuma-Udeh, Kọmisọna fun eto ẹkọ nipinlẹ Anambra ni iṣẹlẹ naa jẹ ohun to ti ni loju pupọ
O ni bi iṣẹlẹ ṣe waye lasiko ti Gomina Charles Soludo n se isẹ nla lati ri gbé eto ẹkọ larugẹ nipinlẹ naa
Ọjọgbọn ni awọn ọtẹlẹmuyẹ tí bẹrẹ iwadi lori ẹsun ti Jamb fi kan akẹkọọ naa
Ìjọba ìpinlẹ naa ni wọn ti kọkọ ṣe ayẹyẹ fun akẹkọọ Anglican Girls School Uruagu pe oun lo ni maaki to pọju ninu idanwo Jamb.
Àtọwọ́dá máàkì 362 ni akẹ́kọ̀ọ́ tó gba ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lò- JAMB

Oríṣun àwòrán, Jamb website
Àjọ to n ṣe eto idanwo aṣewọle si ile ẹ̀kọ́ gíga, (Jamb) sọ pe inu oun ko dùn rara si diẹ lara awọn akekọọ to ṣe idanwo naa lọdun 2023.
Àṣírí tu si Jamb lọwọ pe awọn akekọọ kan lo ọgbọn jibiti lati fi pàárọ̀ èsì idanwo wọn.
Àjọ naa sọ pe awọn akekọọ naa yí maaki ti wọn gbà ninu idanwo wọn pada.
Jamb sọ ninu àtẹ̀jáde kan to fi sita lọjọ Aiku pe eyi to buru ju ninu rẹ ni ti ọmọbìnrin kan, Ejikeme Joy Mmesoma, to kede pe oun gba 362 ninu idanwo UTME ti ọdun 2023.
Wọ́n ni Mmesoma lo maaki to fi kún naa gba ẹbun ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lọwọ ọkùnrin oníṣòwò kan, eyi ti owo rẹ to miliọnu mẹta Naira.
Fabian Benjamin, agbẹnusọ àjọ naa sọ pe awọn yoo gbe igbesẹ to l'agbara lodi si awọn akekọọ naa.
Bawo ni awọn akekọọ naa ṣe ri maaki wọn yi pada?

Oríṣun àwòrán, Others
Ọjọ Aiku ni àjọ Jamb kede pe 249 ni Mmesoma gbà, sugbọn "o fi ọwọ́ ara rẹ yí padà si 362".
Àjọ naa sọ pe imọ ẹrọ kan 'software' lati fi yí maaki wọn pada.
Wọ́n ni awọn akekọọ naa tun lo maaki atọwọda naa lati fi ní okiki lori ayelujara, eyi to mu ki àwọn eeyan kan fun wọn ni ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́.
"Pupọ ninu awọn akekọọ to n gbe ayederu esi idanwo kiri, ni ojulowo maaki ti wọn gbà kere pupọ si iye ti wọn n kede."
Bawo ni àṣírí wọn ṣe tú?
Gbajumọ oníṣòwò, Oloye Innocent Chukwuma, to ni ileeṣẹ to n ṣe ọkọ̀ Innoson Motors, lo fun Mmesoma ni ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ miliọnu mẹta Naira.
Àjọ Jamb sọ pe àṣírí nnkan ti ọmọbìnrin naa ṣe tú, nigba ti awọn aṣojú ijọba ipinlẹ Anambra pé Jamb lati mọ̀ boya lootọ ni o gba maaki to ni oun gbà. Ijọba ipinlẹ Anambra naa n gbèrò lati da a lọla.
"Asiko naa ni àjọ naa tu àṣírí pe 249 gan-an ni ojulowo maaki ti Ejikeme Joy Mmesoma gbà dipo 362 to sọ pe oun gba."
Jamb sọ pe àṣírí rẹ to tú, "lo mu ki àṣírí akẹkọọ miran to ni oun gba maaki 380 ninu idanwo to kọja, tú".
"Akẹkọọ kan ni Kaduna, Atung Gerald, sọ pe oun gba 380.
" Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ilu rẹ ti ẹ ti n pé wa pe ka fun ni àmì ẹ̀yẹ, ko to di pe àṣírí tu si wa lọwọ pe Atung ko ti ẹ ra fọọmu idanwo Jamb rara, debi ti yoo ti ẹ ṣe idanwo".












