Alásè míì bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti se oúnjẹ fún wákàtí 150 nípìnlẹ̀ Ondo

Chef Deola

Oríṣun àwòrán, ChefDeo/Twitter

Obinrin alásè mii tun ti bẹrẹ igbesẹ lati se oúnjẹ fun ọpọlọpọ wakati to tii pọ julọ fun ẹnikan ṣoṣo.

Adeyeye Adeola bẹrẹ oúnjẹ sise naa ni ọjọ Ẹti, ọgbọnjọ oṣu Kẹfà, o si ni oun yoo se oúnjẹ fun aadọjọ wakati, lati le fi ìtàn míì lélẹ̀ ninu iwe Guiness World Record.

Ilu Ile-Oluji, ni ìjọba ibilẹ Okeigbo nipinlẹ Ondo lo ti n se oúnjẹ. Ọjọ́bọ, ọjọ kẹfaa, oṣù Keje ni ireti wa pe yoo parí.

Igbesẹ Arabinrin Adeola n waye lẹyin ti ọmọbinrin kan lati ipinlẹ Ekiti, Adeparusi Damilola, ní oun se oúnjẹ fun ọgọ́fà wakati lai dawọ duro, niluu Oye-Ekiti, ipinlẹ Ekiti.

Botilẹ jẹ pe o pada sọ pe oun ko ṣe e lati gba ami ẹyẹ Guiness.

Lọwọlọwọ, ọmọ orile-ede Naijiria, Hilda Baci, lo ni ami ẹyẹ Guiness World Record, fun ẹni to se oúnjẹ fun ọpọlọpọ wakati lai dawọ duro.

Wakati mẹtalelaadọrun ati isẹju meji lo fi se oúnjẹ tọsan-toru.

Baci ṣe oúnjẹ laarin ọjọ kọkanla, oṣu Karùn-ún si ọjọ kẹẹdogun oṣù Karun-un, ọdun 2023 niluu Eko.

Iroyin igbesẹ rẹ tàn kaakiri agbaye, paapaa lori ayelujara, ti ogunlọgọ àwọn ọmọ Naijiria si lọ sibi to ti se oúnjẹ naa lati ṣe iwuri fun.

O le ni ọgọ́rùn-ún ìkòkò oúnjẹ ti Baci se.

Chef Deola

Oríṣun àwòrán, Chef Deo/Twitter

Ti Adeola Adeyeye ba fi ṣe àṣeyọrí, ti àjọ Guiness World Record si fi ontẹ lu igbesẹ rẹ, o ṣeéṣe ko jẹ oun ni yoo gba ami ẹyẹ ẹni to ṣe ounje fun ọpọlọpọ wakati julọ l'agbaye.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post