Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn UCH gùnlé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ Márùn-ún, dá aláìsàn padà

Aworan

Oríṣun àwòrán, UCH

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

‎Ńṣe ni ile iwosan UCH niluu Ibadan daa paroparo pẹlu bii agbarijọpọ awọn oṣisẹ ile-iwosan ẹkọṣẹ fasiti Ibadan, University College Hospital, UCH ti gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ marun-un lati fẹhonu han lori awọn isoro ti ile-iwosan naa n koju.

‎Awọn oṣiṣẹ yii ti wọn jẹ ẹgbẹ awọn dọkita, awọn nọọsi, awọn olukọ nipa eto ilera, ẹgbẹ awọn agba oṣiṣẹ, awọn oniṣẹ iwadii, ati bẹẹbẹẹ lọ labẹ aburada agbarijọpọ awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ ni UCH, (CUUL) ni wọn gunle iyansẹlodi ọhun ni ana ọjọ ajẹ, ọjọ kẹji, ninu oṣu kẹta.

‎Akoroyin BBC yoruba fidi rẹ mulẹ wi pe nṣe ni ọpọ awọn oṣiṣẹ ile iwosan naa ‎n woṣẹ niran ti awọn miran ko tilẹ wa sibi isẹ rara.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita ti Alaga Comr. Oladayo Olabampe, ati Igbakeji, Dọkita Uthman Adedeji si bu ọwọ lu, agbarijọpọ awọn oṣiṣẹ yii salaye awọn kudiẹkudiẹ to n ba ile - iwosan Ijọba apapọ naa finra.

‎Atẹjade yii to tẹ ileeṣẹ iroyin BBC News Yoruba lọwọ, salaye wi pe fun odindi ọjọ mejilelọgọrun, ile iwosan naa ko ni ina mọnamọna nitori ede aiyede pẹlu ajọ to n ri si ọra ina nilu Ibadan, IBEDC.

‎Wọn ṣe afikun pe bo tile jẹ pe wọn ti da ina ọhun pada, awọn ẹka kan to ṣe pataki ko ni anfaani si ina mọnamọna ti eyi si n ṣe akoba fun ẹka eto ilera, paapaa julọ awọn to n gba itọju, awọn irinṣẹ, awọn eroja itoju, iṣẹ abẹ sise, esi ayewo, ati awọn iṣẹ pataki miran ni ile iwosan naa.

‎Wọn tun ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ n koju orisirisi ipenija ni ẹnu iṣẹ wọn, latari bi wọn ṣe n ṣisẹ ni ọna to buru jai, ti o si tako ilana eto ilera, eyi to fa ki ile-iwosan ijọba naa o maa padanu ẹgbẹlẹgbẹ milionu lojoojumọ.

‎Wọn salaye pe awọn oṣiṣẹ to n gbe ninu ile-iwosan n san owo ina mọnamọna to to ẹgbẹrun mẹwaa si mẹẹdọgbọn losoosu amọ ina ti wọn n lo ki saaba ju wakati kan lọ lojoojumọ. Wọn se afikun wipe ọpọ igba ni awọn oṣiṣẹ ati awọn to n gba itoju maa n ni lati lọ wa omi lọ, latari ọwọn gogo omi to n ba ile iwosan naa finra.

‎Awọn oṣiṣẹ yii wa rọ awọn adari ile iwosan naa lati gbe igbesẹ lori bi ina mọmọ to muna doko yoo ṣe wa ni gbogbo ẹka ati ibugbe awọn oṣiṣẹ. Wọn tun beere fun atunṣe awọn ẹrọ mita to ti bajẹ, ati mimu adinku ba owo ile awọn osiṣẹ ni ilana bi ijọba apapọ ṣe laa kalẹ.

‎Wọn tun rọ awọn ile iṣẹ ijọba apapọ to n ri si ọrọ eto ilera, igbaye-gbadun ara ilu, ọrọ ina mọnamọna ati gbogbo ara ilu lati se iranwọ fun ile iwosan naa.

‎Akoroyin BBC yoruba gbiyanju lati baa awọn to wa fun itọju ara wọn sọrọ sugbọn nise ni wọn ko jalẹ lati sọrọ.