'Kasnaty Sugar' tí sọ́ bí òun ṣe bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ''Conductor'' kí òun tó da ìlúmọ̀ọ́ká lórí rédíò
'Kasnaty Sugar' tí sọ́ bí òun ṣe bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ''Conductor'' kí òun tó da ìlúmọ̀ọ́ká lórí rédíò
Gbajugbaja sọrọsọrọ ti orukọ rẹ n jẹ Kolawole Atanda Adejojo amọ ti ọpọ mọ si 'Kasnaty Sugar' lori redio sọ iriri rẹ ati bi o ṣe di ilumọọka nidi iṣẹ to yan laayo.
Kasnaty Sugar ni oun bẹrẹ lati ẹrọfọ ki oun to di ẹni ti aye mọ ni oni ni idi iṣẹ igbohunsafẹfẹ paapaa lori eto rẹ ti o ti ma n ṣaanu fun awọn arugbo ati awọn to nilo iranwọ.
O ni awọn araalu to ni inu irẹ lo n ṣiṣẹ pẹlu oun lati saanu fun awọn eniyan to si ti mu ki aye rọrun fun awọn arugbo ti wọn ba kan si oun.
Bakan naa lo ni asiko ajakalẹ arun Covid-19 ni ọdun 2020 ni oun bẹrẹ eto naa, to si ti burẹkẹ bayii.
Lasiko to n fi ọrọ jomitoro-ọrọ pẹlu BBC Yoruba lo tun salaye lori iku iyawo rẹ ati awọn ọrọ ahesọ to tẹle.
Ẹ wo fidio naa fun ẹkunrẹrẹ...






