Owó ilé ẹ̀kọ́ ga ju ara lọ lásìkò yìí, orí ń ta àwa Òbí

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Bii awọn ile ẹkọ ṣe n pada si ẹnu isẹ lẹyin isimi tamu lọjọ Aje, ọpọ awọn obi lo ti mu igbe hanu lori ọwọn gogo owo ile ẹkọ ni ile ẹkọ aladani.

Ọpọ awọn obi lo ti bu ẹnu atẹlu bii awọn ile ẹkọ ko ṣe ro bii ọrọ Aje orilẹede Naijiria ṣe dojubolẹ, ti wọn si ti fi owokun owo ile ẹkọ.

Iya ọlọmọ mẹta kan, Iyafin Olawumi Johnson ni ori irọnu ni ọkọ oun wa lẹyin to gbọ eye owo ti awọn ọmọ maa san fun ọwọ ile ẹkọ.

“Fifi owo kun owo ile ẹkọ ni ko bojumu rara pẹlu bii nkan ṣe n lọ lọrilẹede lonii.

Arabinrin Deborah Adefusi ni pẹlu bii owo ti wọn fi kun owo ile ẹkọ awọn ọmọ ko to ẹgbẹrun mẹwaa, bii nnkan ṣe ri lasiko yii, ni ko ki n ṣe igbesẹ to dara rara.

“A nilo eto ọrọ Aje wa ko maa gboro ki igbe aye wa le rọnu fun wa lati wa.”

Bakan naa, Arakunrin Sanmi Olatunde ni awọn ile ẹkọ ko ro nnkan ti awọn obi n lakọja ki wọn to fi owo le owo ilẹ ẹkọ awọn akẹẹkọ.

“Awọn ile ẹkọ ni lati ṣe suuru pẹlu awa obi, wọn si gbọdọ ri pe awọn owo ile ẹkọ wọn jẹ ohun ti a ni agbara, pẹlu bii nnkan ṣe wa lasiko yii lorilẹede yii.

“Gbogbo wa ni a n la nnkan kọja lọwọlọwọ, fun idi eyi, ile ẹkọ ni lati tun erongba wan wo ti wọn ko ba fẹ ki awọn obi maa jẹ wọn ni igbese.”

Ki ni ẹgbẹ awọn oludasilẹ ile ẹkọ sọ?

Nigba ti Olori awọn ilẹ ẹkọ aladani nipinlẹ Oyo n sọrọ lori bii awọn obi ṣe n pariwo si sita lori ọwọn gogo owo ile ẹkọ. Dokita Mary Odedare ni ẹgbẹ awọn oludasilẹ ile ẹkọ aladani ko ni agbara lori bii awọn ile ẹkọ ṣe n fi owo kun owo ile ẹkọ wọn.

“Ti wa naa bami ki a ro pẹlu gbogbo nnkan to n ṣelẹ lọwọ bayii, asiko yii kọ lo yẹ ki wọn fi owo kun owo ilẹ ẹkọ awọn ọmọ.

“Gbogbo wa lamọ bii eto ọrọ Aje ṣe ri lorilẹede Naijiria ati ni gbogbo agbaye ni apapọ.”