Ọ̀pọ̀ àwọn akẹgbẹ́ mi ló gbára lé babaláwo ṣùgbọ́n....- Remi Surutu

Aworan Remi Oshodi

Oríṣun àwòrán, therealremisurutu

Gbajugbaja osere tiata, Remi Oshodi, ti ọpọ mọ si Remi Surutu ni pupo awọn akẹgbẹ oun lagbo osere Yoruba lo gbara le Babalawo lati jẹ ki ogo wọn tan.

Surutu sọ eleyii nigba to n sọrọ nibi eto isinku Iya rẹ to waye nipinlẹ Eko.

O ni gẹgẹ bii iya oun ṣe kọ oun, oun gbara le Ọlọrun nikan.

“Ọlọrun nikan ni mo gbara le ti awọn akẹgbẹ mi kan si gbara le awọn Babalawo awọn kan.

“Iya mi tọ mi ni ilana Ọlọrun, ti mo si wa ni ilana naa loni.”

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

“Íya mi maa sọ fun mi pe ti n ba ti to jubọlẹ, ti mo bẹrẹ si ni gbẹ, oun ko mọ nipa rẹ rara.

“Ọpọ awọn akẹgbẹ mi ni wọn ni Babalawo ti wọn saba fun sugbọn n ko saba fun ẹnikẹni nitori mo ni Oluwa.”

Ọdun to kọja ni Remi Surutu padanu iya rẹ, lẹni ọdun mọkanlelọgọrun un.

Bakan naa ni awọn oṣere ti ransẹ ibanikẹdun si gbajumọ oṣere naa.

Ọmọ lile ni mi ṣugbọn iya mi lo mu mi wa si ile Oluwa

Remi Surutu pẹlu omije loju salaye ipa ti iya rẹ ko ni igbesi aye rẹ titi to fi di olokiki eeyan.

O ni bi oun ṣe sunmọ Ọlọrun ati ile jọsin ko sẹyin akitiyan iya naa.

Surutu ni pe: “Ọmọ lile ni mi, ti wọn ba ni ma wa si ile jọsin, ma nirọ ni sugbọn abiyamọ totọ ni iya mi.

“N ko ri ibi ti iya mi ti ja ri, ko da, iyawo mẹsan ni wọn fẹ le iya mi.

“Ti n ba ni ki maa sọrọ nipa iya mi, ilẹ maa su sugbọn iya mi jẹ ẹni to sunmọ Ọlọrun gidi gan.”