Kò dára bí àwọn Ọlọ́pàá ṣé kọlu àwọn ọmọ ẹgbẹ́ níbi ìfẹ̀hònúhàn àlááfíà ni Eko- Ilana Ọmọ Odua

Oríṣun àwòrán, Twitter.com/BenHundeyin
Ẹgbẹ adijagbara to n bere fun idasilẹ Yoruba Nation, iyẹn Ilana Ọmọ Odua ti bu ẹnu atẹlu bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe kọlu awọn ọmọ ẹgbẹ wọn to n ṣe iwọde ni agbegbe Ojota nipinlẹ Eko.
Ẹgbẹ ohun ni ikọlu naa eyi ti wọn ni o gbẹmii eeyan meji ni wọn safihan pe o ti han gbangba pe ijọba orilẹede Naijiria ko bọwọ fun ofin agbaye to ni pe ẹkun orilẹede ni anfani lati ṣe iwọde.
Ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ naa, Kunle Adelakun Eruobodo fi ransẹ si awọn akọroyin, o ni iwa ẹranko ti iwa ti ileeṣẹ ọlọpaa wu, ti wọn si n kepe ajọ agbaya lati wa gba awọn si lẹ.
“Nilẹ Yoruba eeyan alaafia ni wa, ti a ko si fi a ye silẹ fun irẹjẹ rara fun awọn eeyan wa.
“Awọn toku ko ki n ṣe ọmọ ẹgbẹ wa sugbọn ọmọ Yoruba to ni igbagbọ ninu idasilẹ Yoruba Nation niwọn.
“Iwa ẹranko ni awọn ọlọpaa wu, ti a si n kesi ajọ agbaye lati gba silẹ lọwọ ijọba Naijiria.”
Eèyàn kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí àwọn olópàá àti ajìjàngbara Yorùbá Nation kọlu ara wọn ní Eko

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ọkunrin kan ti padanu ẹmi rẹ ninu rogbodiyan to waye laarọ yii laarin awọn ẹgbẹ adijagbara Yoruba Nation ati awọn ọlọpaa ni agbegbe Ọjọta nipinlẹ Eko.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fi lede, o fi idi mulẹ pe eeyan kan ti awọn ko ti mọ orukọ rẹ ba isẹlẹ naa lọ, ti awọn ẹsẹ ọba si ti wa ni agbegbe naa lati da alaafiia pada.
Hundeyin ni isẹlẹ naa bẹrẹ ni owurọ ojọ Aje nigba ti awọn awọn ọmọ ẹgbẹ adijagbara Yoruba Nation tu sita, ti wọn si n fa sun kẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ni agbegbe Ojọta.
O tẹsiewaju pe ọlọpaa meji ni ibọn ba, ti wọn si ti wa ni ile wosan bayi.
“Eeyan kan padanu ẹmi rẹ, ti awọn ọlọpaa meji si farapa lẹyin ti awọn ọmọ ẹgbẹ adijagbara yinbọn lu wọn.”
Ọwọ ti tẹ awọn afurasi mẹrin, ti alaafia si ti pada bayi
Hundeyin tẹsiwaju pe ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti awọn afurasio mẹrin loei isẹlẹ, ti iwadi si ti bẹrẹ lori isẹlẹ naa.
Bakan naa lo ni alaafia ti pada si agbegbe ọhun, ti o si rọ awọn olugbe ipinlẹ Eko lati tẹsiwaju ninu irinajo wọn.
“Ọwọ ti tẹ awọn afurasi mẹrin kan lori isẹlẹ naa, ti iwadi si ti bẹrẹ pẹlu lẹsẹkẹsẹ.
“Ileeṣẹ ọlọpaa n rọ awọn eeyan ipinlẹ Eko lati tẹsiwaju ninu irinajo wọn nitori a ti pese awọn ọlọpaa ti yoo ri pe irufẹ isẹlẹ naa ko waye rara, wọn si ti bẹrẹ lati maa fimu finlẹ lati mu ẹnikẹni to ba da alaafia ipinlẹ Eko ru lasiko yii.
” A n kede bayi pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ko ni fi aye lẹ fun ẹgbẹ tabi ẹnikẹni lati da alaafia ipinlẹ yii ru.”















