Ìjàm̀bá ọkọ̀ gbẹ̀mí ènìyàn ogójì, ọ̀pọ̀ míì farapa

car accident

Kò dín ní ènìyàn ogójì tí wọ́n ti pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ kan tó wáyé ní orílẹ̀ èdè Senegal.

Bákan náà ni ọ̀pọ̀ ènìyàn tún farapa tí wọ́n sì wà níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

Ìwádìí ní ọkọ̀ kan ni táyà rẹ̀ fọ́ lórí eré tó sì lọ forí sọ àwọn ọkọ̀ mìíràn tí wọ́n ń bọ̀.

Ààrẹ Senegal, Macky Sall ti wá kéde ìsinmi ọjọ́ mẹ́ta láti fi kẹ́dùn àwọn tó bá ìjàm̀bá náà lọ.

"Ènìyàn mẹtadinlaadọsan ló wà nínú àwọn ọkọ̀ tí ìjàm̀bá náà kan"

Sall tún ṣèlérí wí pé àwọn máa ri dájú pé àwọn mú àlékún bá ètò ìrìnnà ọkọ̀ kí ààbò tó péye le wà fún ará ìlú.

Ìjàm̀bá ọkọ̀ wọ́pọ̀ ní Senegal àmọ́ èyí ló fẹ́ẹ̀ burú jùlọ láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn.

Ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, Cheikh Fall sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ènìyàn 87 ló wà nínú àwọn ọkọ̀ tí ìjàm̀bá náà ṣẹlẹ̀ sí ní agbègbè Kaffrine.

Fall ní àwọn tó farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wà ní ilé ìwòsàn níbi tí wón ti ń gba ìtọ́jú.

Èèyàn mọ́kànlélógún mìí tún kú sínú ìjàm̀bá ọkọ̀ ní Kenya, mọ́kàndínláàdọ́ta sì farapa

Ààrẹ Sall tún bá àwọn ẹbí àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìjàm̀bá kẹ́dùn tó sì tún gbàdúrà àláfíà pípé fún àwọn tó farapa níbi ìjàm̀bá náà.

Ẹ̀wẹ̀, ènìyàn mọ́kànléógún mìíràn tún ti pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàm̀bá ọkọ̀ ní orílẹ̀ èdè Kenya tí àwọn mọ́kàndínláàdọ́ta sì farapa.

Nígbà tí ọkọ̀ náà ń wọ Kenya láti Uganda ni ìjàm̀bá náà wáyé.

Àwọn mẹ́jọ nínú àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn ló jẹ́ ọmọ Uganda tí àwọn yòókù sì jẹ́ ọmọ Kenya.