Aṣọ ń pe aṣọ ránṣẹ́ báwọn ọmọ bíbí Ogbomoso nile àti lókè òkun ṣe péjú fún àjọ̀dún àṣà ìlú wọn

Àwọn èèyàn lọkunrin àti lobinrin tó péjú síbi àjọ̀dún àṣà nilu Ogbomoso wọ onírúurú aṣọ oke toke tilẹ̀ pẹlu ìlẹ̀kẹ̀ lọrun àti ní ọwọ́ wọn.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

‎Tilu tifọn ati inú dídùn ni ayẹyẹ ajọdun àwọn ọmọ bíbí ilu Ogbomoso, ti wọn sọri rẹ ní Ogbomoso Cradles Carnival fi wa sopin.

Pápá ìṣeré Soun Ajagungbade to wa nilu Ogbomoso ni ayẹyẹ naa ti wáyé.

‎Eto naa lo ti bẹẹrẹ lati Ọjọbọ ọjọ kejidinlogun osu Kejila ọdun yii, pẹlu sise afihan awọn ounjẹ ibilẹ ilu Ogbomoso, Egungun, Asa, ipate ọja ati iṣeṣe ilu Ogbomoso.‎

Soun tilẹ̀ Ogbomoso, ọba Ghandi Afolabi Laoye joko sori aga ọlọ́lá, ó wọ aṣọ oke agbada àti Sokoto aláwọ̀ Goolu pẹlu fìlà rẹ, o wa ìlẹ̀kẹ̀ sọrun, ó sì dé adé sórí.

Ẹ fi ọwọ́ so ọwọ́ pọ pẹ̀lú mi, kí idagbasoke le ba ìlú Ogbomoso - Soun

‎Ninu ọrọ ikinni kaabo rẹ, Soun ti ilẹ Ogbomoso Ọba Ghandi Afolabi Laoye, Orumogege kẹta ṣalaye wi pe eto naa jẹ bi ìbẹ̀rẹ̀ idagbasoke eto ọrọ aje fun ilu Ogbomoso.

‎Soun ti ilẹ Ogbomoso gbosuba fun gbogbo awọn ọmọ Ogbomoso to kopa ninu eto naa.

Pápá julọ awọn to wa lati ilẹ okere bii ilu Ọba, Orile-ede Togo, Benin Republic, Ghana ati awọn orileede miran.

‎Kabiyesi rọ awọn ọmọ ilu Ogbomoso lati fi ọwọ sọwọpọ pẹlu oun, ki idagbasoke le ba ilu Ogbomoso.

Soun wa kede ifilọlẹ ẹgbẹ miran ti yoo so gbogbo ẹgbẹ ilu Ogbomoso papọ .‎

Àwọn ẹgbẹ́ kan wọ aṣọ oke aláwọ̀ búlúù

Ayẹyẹ àṣà yìí yóò mú ìṣọ̀kan to pọ àti idagbasoke ba ìlú Ogbomoso - Segun Odebunmi

‎Bákan náà, Oloye Olusegun Odebunmi ẹni tí o jẹ alaga fun eto naa sapejuwe ayẹyẹ àṣà náà gẹgẹ bii eyiti yoo mu awọn ọmọbibi ilu Ogbomoso wa sile.

‎O ni eto ọhun yoo mu isọkan to loorin wa silu Ogbomoso, ti yoo si mu ki ọrọ aje ilu naa burẹkẹ sì.

‎O tẹsiwaju wi pe ayẹyẹ àṣà tí ọdun yìí jẹ ìkejì irú rẹ tí yoo waye, ó wá ṣèlérí lati sọ ayẹyẹ Ogbomoso Cradles Carnival di eyi ti gbogbo orílẹ̀èdè Naijiria yoo gbaruku tii.

Àwọn èèyàn tó jókòó wọ onírúurú aṣọ oke

Ìjọba Oyo, ẹ nawo si igbelaruge aṣa ati ise jakejado Ipinlẹ yìí - Sola Adepoju

Asiwaju ilu Ogbomoso, ọmọwe Sola Adepoju ni "ẹ wo ẹnu ilẹ̀, ki ẹ wo ẹnu ọkọ, ayẹyẹ àṣà naa ti di eyi ti gbogbo ilu Ogbomoso ti tẹ́wọ́ gba."

‎Adepoju ni pẹlu bii gbogbo papa ìṣere naa ko ṣe le gba ero, fihan wipe lọ́dún toun bọ, ayẹyẹ naa yoo túbọ̀ larinrin síi.

‎Olufemi Ajayi Oguntoyinbo ni, ẹtọ Ogbomoso Cradles Carnival yoo si Ipinlẹ Oyo loju ki idagbasoke to loorin le wa ni tibutoro Ipinlẹ Oyo.‎

‎O wa fi idunnu rẹ han si bii ọpọ eeyan ṣe wọ ìlẹ̀kẹ̀ ati orisirisi aṣọ ibilẹ bii ofi, Sanyan, Ankara ati awọn aṣọ alaranbara miran.

‎O tún rọ ijọba lati nawo si igbelaruge aṣa ati ise jakejado Ipinlẹ Oyo.