Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Papiri 130 tó wà lákàtà ajínigbé gba ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Ijọba apapọ ti sọ pe awọn ti gba itusilẹ awọn akẹkọọ 130 to ṣeku si akata awọn ajinigbe lẹyin ti awọn agbesunmọmi ji wọn gbe nile ẹkọ wọn nipinlẹ Niger.
Gẹgẹ bii ohun ti ijọba apapọ sọ, itusilẹ awọn akẹkọọ ọhun jẹ aṣeyọri nla ati eyii to dun mọ awọn ninu.
Awọn ọmọde naa ti iye wọn le ni 250 ni wọn jigbe nile ẹkọ St Mary's Catholic school to wa ni Papiri, nipinlẹ Niger, lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 yii.
Nigba ti yoo di ibẹrẹ oṣu Kejila ti a wa yii, ijọba gba itusilẹ ọgọrun un ninu awọn ọmọde naa.
Lẹyin itusilẹ awọn ọmọ 130 yii ni ijọba apapọ kede pe ko si eyikeyi ninu wọn to ṣi wa lakata ajinigbe mọ.
Agbẹnusọ fun Aarẹ Bola Tinubu, Bayo Onanuga ni apapọ iye awọn ọmọ naa ti ijọba ti doola ti pe ni 230 bayii.
Lati igba ti wọn ti ji awọn ọmọ ọhun gbe lo ti ṣoro lati sọ ni pato iye awọn ti wọn ji gbe ati iye awọn to ṣi wa ni ahamọ ajinigbe.
Wayi o, titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ijoba ko ṣalaye bo ṣe ri awọn ọmọ naa gba pada, yala o san owo itusilẹ ni o tabi bẹẹ kọ.
Aarọ oni ọjọ Aje ni igbagbọ wa pe awọn ọmọ ọhun yoo balẹ siluu Minna, to jẹ olu ilu ipinlẹ Niger.
Nigba ti wọn kọkọ tu iṣi kinni awọn ọmọde naa silẹ, gomina ipinlẹ Nasarawa to fẹgbẹkẹgbẹ Niger, iyẹn Abdullahi Sule, sọ pe ijọba apapọ ko ipa ribiribi ninu itusilẹ awọn ọmọ naa amọ o ni oun ko ni mẹnuba ohun pato ti ijọba ṣe.
Ṣaaju ni ajọ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN, ti kọkọ kede pe aadọta ninu awọn ọmọde ọhun moribọ lakata awọn ajjinigbe naa ki ijọba to bẹrẹ si n gba itusilẹ awọn akẹgbẹ wọn to ku.
Iṣẹlẹ ijinigbe yii jẹ ọkan lara eyii to mi Naijiria titi lẹnu lọlọ yii ninu awọn ijinigbe to n waye sawọn ile ẹkọ ati ṣọọṣi n Naijiria.
Ti ẹ ko ba gbagbe, lọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla kan naa ni awọn agbesunmọmi ya bo ile ijọsin CAC Oke Isegun, nipinlẹ Kwara, nibi ti wọn ti gbẹmi eeyan meji ti wọn tun ji eeyan mejidinlogoji lọ.
Ọjọ meji ṣaaju iṣẹlẹ CAC Oke Isegun ni awọn mii yabo ile ẹkọ Government Girls' Secondary School nipinlẹ Kebbi, nibi ti wọn ti ji akẹkọọ marundinlọgbọn lọ.
Amọ ṣa, gbogbo awọn ti wọn ji gbe ni Kwara ati Kebbi ni wọn ti gba itusilẹ lakata ajinigbe bayii.















