Afurasí olóògùn olóró lóbìnrin, tí NDLEA ń dọdẹ fọ́jọ́ pípẹ́, wọ gbaga pẹlú òògùn olóró ₦5bn

Aworan afurasi oloogun oloro naa pẹlu awon egboogi naa

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ìwọ̀n oogun oloro (Cocaine) to to 23.50kg, ti owo ti wọn le ta a si to biliọnu marun-un naira (₦5bn) ni ajọ to n gbogun ti gbigbe oogun oloro lorilẹede yii, NDLEA, kede pe awọn ba ni yara awọn ọmọ afurasi kan, Shodunke Simbiat Yetunde, nipinlẹ Eko.

Ana ọjọ Aiku ni ajọ NDLEA kede bẹẹ ninu atẹjade ti agbẹnusọ wọn, Femi Babafemi, fi sita.

NDLEA ni o ti pe ogun oṣu tawọn ti n dọdẹ Simbiat to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ tọkọtaya oniṣowo oogun oloro kan, Bolanle Lookman Dauda ati Olayinka Toheebat Dauda.

NDLEA ní ipinlẹ Eko ati Ogun ni ọwọ ti ba tọkọtaya to ń saaju ikọ̀ ooogun oloro tí Simbi wa

Ajọ naa sọ pe ipinlẹ Eko ati Ogun ni ọwọ ti ba tọkọtaya naa pẹlu oogun oloro onibiliọnu naira rẹpẹtẹ ti wọn fẹ gbe kọja lọ si orilẹede Ghana.

Ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Karun-un ọdun 2024 ni NDLEA mu wọn bi wọn ṣe sọ.

Ṣugbọn bi wọn ṣe mu wọn, ko di Simbi lọwọ lati maa tẹsiwaju ni tiẹ.

NDLEA sọ pe niṣe lo kan farapamọ lati oṣu Karun-un ọdun 2024, ṣugbọn o n ba iṣẹ lọ labẹnu.

Bawo ni ọwọ ṣe ba Simbi l'Eko?

Atẹjade ajọ NDLEA ṣalaye pe lẹyin ti ọwọ ti ba tọkọtaya to n lewaju ikọ oloogun oloro naa, afojusun awọn ni lati mu gbogbo ọmọ ẹgbẹ wọn pata.

Eyi ni wọn lo fa a ti wọn fi n dọdẹ Simbi, bo tilẹ jẹ pe o pẹ kọwọ ofin too ba a.

"Nigba ti a ti pinnu lati gbọn gbogbo ikọ ologun oloro naa yẹbẹyẹbẹ, awọn oṣiṣẹ NDLEA tẹsiwaju ninu iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ wọn lori awọn to n gbe oogun naa lati ẹnu ibode ilu kan si ikeji.

"Eyi ni wọn ṣe titi ti ọwọ fi ba Shodunke Yetunde Simbiat, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (39). Olobo lo ta wa pe ọkan gboogi lara awọn ikọ naa ni.

"A dọdẹ rẹ de ile rẹ to wa lojule kọkanlelọgbọn, opopona Onasanya, Surulere, niluu Eko, iyẹn lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹsan-an oṣu Kejila ọdun 2025.

Agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi lo ṣalaye bẹẹ.

Simbi di oògùn olóró kalẹ sinu apamọwọ aláwọ̀ dudu sinu yara ti awọn ọmọ rẹ n sun

NDLEA ni nigba ti awọn tu ile Simbiat yẹbẹyẹbẹ ni awọn ri oogun oloro (cocaine) to di kalẹ sinu apamọwọ alawo dudu, to si gbe e sinu yara ti awọn ọmọ rẹ n sun.

"O jẹwọ fun wa pe oun loun ni oogun oloro naa, eyi ti iye rẹ ju biliọnu marun-un naira lọ bi wọn ba ta a.

Afurasi naa ati ẹru ofin to n ta si ti wa ni ahamọ bi NDLEA ṣe fidi ẹ mulẹ.