Ọmọ Amẹrika ni mí ṣùgbọ́n nítorí olólùfẹ́ mi Aanuoluwapo ni mo ṣe lọ kọ́ èdè Yoruba - Pablo

Àkọlé fídíò, Familia Pablanu
Ọmọ Amẹrika ni mí ṣùgbọ́n nítorí olólùfẹ́ mi Aanuoluwapo ni mo ṣe lọ kọ́ èdè Yoruba - Pablo

Ọmọ orilẹede Amẹrika kan, Pablo ti lọ kọ ede Yoruba nitori ololufẹ rẹ kan to jẹ ọmọ Yoruba lati ipinlẹ Ondo.

Ilẹ Amẹrika ni awọn mejeji ti pade ara wọn ki wọn to ṣe igbeyawo ni ọpọ ọdun sẹyin.

Pablo Olusegun, bo tilẹ jẹ pe ọmọ ilẹ okeere ni, o gbọ ede Yoruba to bẹẹ to fi le fi ami sori ọrọ Yoruba.

Bi ere ifẹ wọn ṣe bẹrẹ

Tọkọtaya naa ti ọpọ mọ si Famili Pablanu ni wọn pade ara wọn nilẹ Amẹrika lasiko ti iyawo to jẹ ọmọ Naijiria, iyẹn Aanuoluwapo lọ silẹ Amẹrika lati kawe gboye MSc.

Aanuoluwapo sọ pe "Ọrọ ifẹ wa bẹrẹ nilẹ Amẹrika. Ilẹ Amẹrika ni a ti pade.

"Mo pari ile iwe giga niluu Indiana nibi ti mo ti kẹkọ gboye 'master.s'

"A ṣaa pade nibi ayẹyẹ kan ṣa, bi a ṣe ri ara wa niyẹn.

Tọkọtaya naa ti wọn wọ aṣọ Yoruba

"Nitori titemi ni wọn ṣe lọ sile iwe lati kọ ede Yoruba.

Pablo ni "Ọmọ ilu Amẹrika ni mi, ṣugbọn mo gbọ oriṣiriṣi ede.... Mi o mọ idi rẹ, ṣugbọn mo kan fẹran obinrin yii pupọ ni."

Ọkunrin naa to jẹ olukọ nipa oniruru ede sọ pe oun kọ ede Yoruba, oun si mọ ede naa to bẹẹ ti oun le fi ami sori ede Yoruba.

Tọkọtaya naa ti wọn wọ aṣọ Yoruba

"Ohun to gbe wa kuro nilẹ Amẹrika"

Lẹyin ọdun mẹjọ ti wọn ti gbe ara wọn niyawo ti wọn si ti bi awọn ọmọ, awọn mejeji pinnu lati kuro l'Amẹrika lati maa gbe ni Naijiria.

Aanuoluwapo sọ pe lasiko ti wọn wa nilẹ Amẹrika, niṣe lo ba bii pe wọn ko ni akojọ kankan latari bi wọn ṣe n fi pupọ ninu owo ti wọn n pa wọle gbọ bukata.

O ni "A wa wo o pe a ko le ni ikojọ nibi yii, bi a ṣe n ri owo naa ni o n lọ... a wa ba ẹsẹ wa sọrọ.

"A ja pada ni, awọn kan n japa, awa ja pada ni."

Tọkọtaya naa ti wọn wọ aṣọ Yoruba

"Ede Yoruba la n sọ si awọn ọmọ wa nile"

Nigba ti BBC kan sile tọkọtaya naa, a ṣakiyesi pe orukọ Yoruba ni wọn sọ awọn ọmọ wọn, gbogbo wọn si gbọ ede Yoruba.

Gẹgẹ bi ẹni to fẹran ede, Pablo ni oun ti pinnu lati ilẹ lati kọ awọn ọmọ oun ni ede Italy ki iya wọn si kọ wọn ni ede Yoruba.

Awọn mejeji ni eyii ko ṣẹyin eredi ti wọn ṣe fun awọn ọmọ naa ni orukọ Yoruba ti wọn si n sọ ede Yoruba si wọn ninu ile.

Wo fidio oke yi fun ẹkunrẹrẹ ohun ti tọkọtaya yii ba BBC Yoruba sọ.