Chelsea v Arsenal: Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yìí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ agbabọọlu to gba ife ẹyẹ agbaye yoo ma wakọ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu to n lewaju ni ilẹ Yuroopu lọwọ yii, iyun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ati Arsenal ni deede ago marun un abọ.

Arsenal ti bori ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ninu meje ti wọn ti gba ni ligi, ti Chelsea si ti bori marun ninu mẹfa.

Bakan naa ni awọn mejeeji fakọyọ laarin ọsẹ nigba ti won koju Bayern Munich ati Barcelona.

Ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji fidi janlẹ lọwọ Sunderland botilẹ jẹ pe Sunderland ta ọmi pẹlu Arsenal, ti wọn si bo ẹgba sidi Chelsea.

Ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Sunderland ni awọn mejeeji ti padanu ami ayo laarin ifẹsẹwọnsẹ m]ẹfa ti gba gbẹyin.

Bi tabili ligi ilẹ se ri lọwọ yii

Igba melo ni ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji ti pade ara wọn?

Chelsea ti gba ifẹsẹwọnsẹ pupọ pẹlu Arsenal (211) ju ẹgbẹ agbabọọlu miiran lọ.

Ifẹsẹwọnsẹ oni yoo jẹ igba mejidinlọgọrun ti ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji ti gba bọọlu lori paapa Stamford Bridge ni gbogbo idije.

Ọdun 2018 ni Chelsea na Arsenal gbẹyin ni Stamford Bridge lasiko isakoso Maurizio Sarri, ti wọn si bori pẹlu goolu mẹta si meji.

Arsenal ti padanu ifẹsẹwọnsẹ kan ninu mọkanla ti wọn ti koju Chelsea, (Wọn bori meje, ọmi mẹta).

Ọdun 2021 ni eyi waye paapa iṣere Emirates Stadium, pẹlu iranlọwọ goolu lati ọwọ Romelu Lukaku ati Reece James.

Aworan tabili ligi gẹẹsi laarin ifẹsẹwọnsẹ m]efa

Ori o jo ori (ninu gbogbo idije)

  • Ifẹsẹwọnsẹ ti wọn ti gba- 211
  • Eyi ti wọn bori- 66
  • Ọmi 61
  • Eyi ti wọn padanu 84

Ifẹsẹwọnsẹ marun un to waye ni Stamford Bridge gbẹyin

  • 12 May 2021 - Ni ligi Premier League, Chelsea padanu pẹlu ami ayo kan si odo , L 1-0
  • 20 April 2022 - Chelsea tun padanu pẹlu ami ayo mẹrin si meji, Premier League L 4-2
  • 6 November 2022 - Bẹẹ tun ni, Chelsea tun fidi janlẹ, L 1-0
  • 21 October 2023 - Wọn ta ọmi ninu ifẹsẹwọnsẹ ni ligi Premier League D 2-2
  • 10 November 2024 - Wọn tun ta ọmi ninu ligi Premier League D 1-1

Ifẹsẹwọnsẹ ti goolu ti pọju

  • Chelsea 6-0 Arsenal | 2013/14 | Premier League
  • Arsenal 5-0 Chelsea | 2023/24 | Premier League