Omiyalé gbé èèyàn 159 lọ ní Sri Lanka, 20,000 di àwátì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan, eeyan 159 ni agbara omi ti gbe lọ lorilẹede Sri Lanka ni bayii ti orilẹede naa n koju ọkan lara iṣẹlẹ omiyale to buru julọ ninu itan rẹ.
Yatọ si awọn to ku, eeyan to le igba ni wọn ṣi n wa.
Iroyin ni ileegbe to le ni ẹgbẹrun lọna ogun lo ti ba omi lọ eyii to sọ 108,000 eeyan di alairilegbe.
Ajọ Disaster Management Centre sọ pe ida kan ninu mẹta orileede naa ni ko ni ina ijọba lọwọ yii latari iṣẹlẹ naa.
Agbegbe ti awọn eeyan ti padanu ẹmi wọn julọ ni Kandy ati Badulla ti awọn adoola ẹmi ko tete de.
Saman Kumara to jẹ olugbe abule Badulla lagbegbe Maspanna sọ pe "eeyan meji ni a padanu ni abule wa… A ko le fi abule naa silẹ bẹẹ lawọn mii ko le wọle nitori ilẹ to ya di oju ọna."
O sọ fun ileeṣẹ iroyin News Center lori ẹrọ ilewọ pe "Ko si ounjẹ fun wa, bẹẹ ni ko si omi to mọ geere."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọlọpaa ni ara awọn to ku ni eeyan mọkanla ni abule naa nibi ti wọn ti n tọju awọn arugbo lẹyin ti omi gbe ibi ti wọn n gbe lọ.
Ni Anuradhapura, wọn doola eeyan 69 ti wọn ha sinu bọọsi ti omi gbe lọ.
Ọkan lara ero inu bọọsi naa sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe awọn ologun lo ran awọn lọwọ lati gun ori igi ki wọn to moribọ.
Ijọba orilẹede naa ti rawọ ẹbẹ sawọn ijọba ilẹ mii fun iranlọwọ, bẹẹ ni wọn tun rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ orilẹede naa to wa nilẹ okeere lati fi owo ranṣẹ fun iranlọwọ awọn ti ọrọ naa kan.
Iji lile Cyclone Ditwah to kọlu Sri Lanka lọjọ Ẹti lo ṣokunfa iṣẹlẹ naa amọ a gbọ pe iji lile naa ti kuro nilẹ naa ti alagbalugbu om iyi ka.
Lootọ ni Sri Lanka maa n koju iji nla amọ orilẹede naa ko tii ri irufẹ iji bayii ri.
Iṣẹlẹ omiyale to buru julọ nilẹ naa waye ninu oṣu Kẹfa ọdun 2003 to si mu ẹmi eeyan 254 lọ ti ẹgbẹgbẹrun tun di alainilelori.















