Abẹ ìsẹjọba rẹ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ni ìgbésùnmọ̀mí ti bẹ̀rẹ̀- Iléeṣẹ́ Ààrẹ fèsì padà fún Obasanjo

Aworan Aarẹ orilẹede Naijiria Bola Tinubu ati aarẹ nigba kan ri, Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria ti fesi pada fun aarẹ orilẹede Naijiria nigba kan ri, Olusegun Obasanjo pe ko ni ẹtọ lati bu ẹnu atẹlu iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu lori bi eto aabo ṣe mẹhe lorilẹede Naijiria.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ kan niluu Jos, to jẹ olu ilu ipinlẹ Plateau, Obasanjo bu ẹnu atẹlu ipo ti eto aabo wa lorilẹede Naijiria.

O ni awọn ọmọ Naijiria ni ẹtọ lati kesi oke okun pe ki wọn gba wọn nitori ijọba ti ja wọn kulẹ ni gbogbo ọna.

Ẹwẹ, ileeṣẹ aarẹ ni gbogbo ohun to jọ mọ igbesunami lorilẹede Naijiria gberasọ labẹ iṣejọba Obasanjo, ti wọn si fẹsun pe oun naa dakun rogbodiyan eto aabo to wa lorilẹede Naijiria.

Bakan naa ni ileeṣẹ aarẹ tun wọgile ọrọ Obasanjo to ni pe ki Aarẹ Bola Tinubu kesi ijọba oke okun fun iranlọwọ ti ko ba le gbe ogun ti iṣoro eto aabo.

"Sisọ pe ki aarẹ bẹrẹ fun iranlọwọ lati oke okun lati koju iṣoro eto aabo ki n ṣe apẹẹrẹ adari rere to nifẹ ilu lọkan.

Awọn ọrọ yii lo jẹ yọ ninu atẹjade kan ti oludamọran pataki si aarẹ lori ọrọ iroyin, Sunday Dare gbe sori ayelujara X.

Atẹjade naa tun sọ ọrọ pe ki Obasanjo to daba pe ki Aarẹ Tinubu ju wọle fun orilẹede oke okun, o yẹ ki Obasanjo ronu bi oun fun ara rẹ se kuna lati gbe ogun ti iwa igbesunami lasiko to wa ni ijọba.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ọrọ ti aarẹ nigba kan ri sọ nipa iṣejọba aarẹ Tinubu pe ko ni agbara lati da bobo awọn ọmọ Naijiria ni ko yẹ ko tẹnu Obasanjo jade, pe awọn araalu n koju ikọlu awọn agbebọn.

"Naijiria lonii ni koju ọpọ ikọlu lati ọdọ awọn agbesunami ISIS, al-Qaeda ati awọn agbebọn ti ẹnu ibode.

"Awọn agbebọn yii ni awọn ti wọn siṣẹ fun. Wọn n pin owo, ohun ija, ati awọn mii, to si jẹ erogba wọn ni lati pin orilẹede Naijiria.

"Ẹ jẹ ka pe wọn ni orukọ wọn, Agbesunami ni wọn," ileeṣẹ aarẹ ṣalaye.

"O yẹ ka jẹ ko di mimọ pe awọn agbebọn yii gbera sọ lasiko ijọba alagbada Obasanjo. Bi wọn se n korawọnjọ, ti wọn n da ibudo silẹ, ijọba lasiko naa kọ lati gbe igbesẹ to yẹ.

"Nnkan to bẹrẹ pẹlu nnkan kekere, ni o ti di nnkan nla bayii lagbaye.

"Fun olori to jẹ pe asiko rẹ ni iwa igbesunami gberasọ, ni o ti ohun ti a n sọ kaakiri agbaye bayii.

Ileeṣẹ aarẹ tun jẹ ko di mimọ pe bi orilẹede Naijiria ṣe ṣetan lati ba orilẹede oke okun ṣiṣẹ pọ, ko ṣetan lati juwọ lẹ ominira rẹ fun orilẹede kankan.

"Naijiria yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu agbaye, bẹẹni ṣugbọn ko ni juwọlẹ fun ẹnikẹni .

"Naijiria nilo iranlọwọ ati igbọraẹniye orilẹede Amẹrika, ti ajọsepọ si n lọ lọwọ," ileeṣẹ aarẹ fikun.

Ẹ yé dúnàádúrà pẹ̀lú agbésùnmọ̀mí mọ́, Obasanjo sọ ìgbésẹ̀ tó yẹ kí ìjọba gbé lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ

Oloye Olusegun Obasanjo wọ aṣọ olomi aro, o si de fila pupa

Oríṣun àwòrán, Other

Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Oloye Olusegun Obasanjo, ti kìlọ pe kí ìjọba àpapọ dẹkùn idunaadura pẹlu awọn agbésùnmọ̀mí.

Obasanjo to fidi ọrọ yii múlẹ ninu fídíò kan to ti lu ori ayelujara pa bayii, gba ìjọba Aarẹ Bola Tinubu ni imọran lati gba iranwọ awọn orilẹede ilẹ okeere lati wa ojutuu si eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.

Nigba to n sọrọ nibi isin orin Keresimesi to waye niluu Jos nipinlẹ Plateau lanaa ọjọ Ẹtì ọjọ kejidinlogun osu kẹwàá yii, Obasanjo ni ki ìjọba ye tọrọ aforijin lọwọ àwọn janduku agbésùnmọ̀mí mọ.

Aarẹ Naijiria tẹlẹ sọrọ yii lẹyìn oniruuru iṣẹlẹ ipaniyan ati ijinigbe to ti waye nipinlẹ Kwara, Kebbi ati Niger lẹnu lọọlọ yìí.

Akẹẹkọ 315 ati olukọ 13 láwọn agbésùnmọ̀mí ji gbe nile ẹkọ St Mary's Catholic school ni Papiri lọjọ kọkanlelogun oṣu Kọkànlá yii nipinlẹ Niger.

Ṣaaju ni awọn janduku agbébọn ti jí akẹ́kọ̀ọ́binrin mẹrindinlọgbọn nile ẹkọ girama to wa ni Maga, ni ìjọba ìbílẹ̀ Danko-Wasagu ni ipinlẹ Kebbi.

Ko din ni ogun eeyan tawon janduku agbébọn tún jí gbe nipinlẹ Kano ati Kwara laarin ọjọ Aje ati ọjọ Isẹgun ọsẹ yii.

Ìṣẹlẹ yìí wáyé lẹyìn t'awọn janduku ti kọkọ ji olùjọsìn mejidinlogoji ni ṣọọṣi CAC kan niluu Eruku nipinlẹ Kwara gbé nibi ti won tun ti ṣekú p'awọn eeyan kan.

O dabi ẹni pe ìjọba wa ko lagbara lati daabo bo wa mọ - Obasanjo

Obasanjo fi aidunnu rẹ lori bi eto aabo ṣe n buru sii ni Nàìjíríà, ààrẹ Naijiria tẹlẹ ni awọn ọmọ Naijiria lẹtọọ lati bèèrè iranwọ ilẹ okeere lẹyìn tí ìjọba ti kuna lati daabo bo araalu.

"Iru ẹṣin yowu ti o le maa ṣe, ibikibi to wu ki o ti wa, ọmọ Naijiria lawọn eeyan ti wọn n pa.

O si dabi ẹni pe ìjọba wa ko lagbara lati daabo bo wa mọ.

Ara awọn orilẹ-ede agbaye ni Naijiria wa, a lẹtọọ lati pe fun iranwọ ti ijọba wa ko ba le pese aabo fún wa," Obasanjo lo sọ bẹẹ.

Aarẹ ana fikun ọrọ rẹ pe awọn ohun elo ijagun Igbalode ti jẹ ko rọrùn lati ṣẹgun awọn janduku agbébọn bayii.

Obasanjo ni "ki n to kuro nijoba, ijọba lagbara lati gbe ẹnikẹni to ba huwa odaran nibi kibi.

Ipenija ti a ni lasiko naa ni pe ori ilẹ ati oju ofurufu ni a le gba mu iru ọdaràn bẹẹ.

Ṣugbọn awọn ẹṣọ eleto aabo le lo ẹrọ "drone" lati mu ọdaràn ki ọdaràn to ba sẹ sofin lọwọ yii."