Ìdí rèé tí Trump ṣe dáwọ́ fífún àwọn ọmọ orílẹ̀èdè 19, tí kò rọ́wọ́ họrí, ní físà dúró

Oríṣun àwòrán, Facebook/Donald J. Trump
Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ti kede pe oun yoo da fifun awọn awọn orilẹede ti ko rọwọ họri ni fisa fun akoko diẹ.
Amọ ko mẹnuba atupalẹ bi igbesẹ naa yoo ṣe jẹ ati awọn orilẹede ti ọrọ naa kan ni pato.
Aarẹ ọhun fẹsun kan awọn eeyan ilẹ okere pe awọn lo n da omi alaafia orilẹede Amẹrika ru, o si ṣeleri pe oun yoo le ẹnikẹni to ba n ṣakoba fun eto abo orilẹede naa kuro nibẹ.
Ọrọ yii lo n jẹyọ lẹyin ti wọn fẹsun kan ọmọ orilẹede Afganistan kan pe oun lo ṣekupa ọmọ ogun National Guard kan niluu Washington DC lana ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025.
Trump sọ pe ikọlu naa ṣafihan ewu eto abo to n koju ilẹ Amẹrika, oun yoo si le gbogbo awọn to dunkoko mọ eto abo orilẹede naa kuro nibẹ.
Lọjọru ni ijọba Amẹrika bẹgidina gbogbo awọn to n gbiyanju lati gba fisa wọ Amẹrika latari pe ijọba ilẹ naa n ṣe awọn iwadii eto abo awọn eeyan ọhun.
Ninu atẹjade to fi lede loju opo X rẹ, Trump ni oun yoo da gbogbo awọn anfani ijọba ti awọn atọhunrinwa n jẹ nilẹ naa duro.
Nigba ti BBC bere lọwọ ijọba Amẹrika nipa awọn orilẹede ti ọrọ naa kan, niṣe lo tọka si atẹjade kan to fi lede ninu oṣu Kẹfa ọdun yii nibi to ti mẹnuba orilẹede bii Afghanistan, Cuba, Haiti, Iran, Somalia ati Venezuela.
Awọn orilẹede mii ti ijọba Amẹrika yoo ṣayẹwo awọn to ti gba kaadi alawọ ewe rẹ ni Burma, Chad, Republic of Congo ati Libya.
Awọn orilẹede wo ni ko rọwọ họri ti Trump n fi ọrọ ranṣẹ si?
Trump funra rẹ tabi awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ ko darukọ tabi ṣalaye kikun nipa awọn orilẹede ti ọrọ yii yoo kan.
Amọ Joseph Edlow to jẹ ọga agba ajọ to n ri si wọlewọde ilẹ Amẹrika, United States Citizenship and Immigration Services ni Trump ti paṣẹ ki awọn ṣe ọfintoto gbogbo ọmọ orilẹede ti wọn n pe ni "country of concern" ti wọn ti gba kaadi alawọ ewe lati maa gbe l'Amẹrika finifini.
Fun idi eyii, awọn orilẹede wo gan ni wọn ka si orilẹede 'Countries of Concern?'
Ninu oṣu kẹfa ọdun yii, Trump fofin de awọn ọmọ orilẹede mejila kan pe wọn ko gbọdọ wọ Amẹrika mọ, bẹẹ lo tun fofin de awọn orilẹede meje mii fun igba diẹ lori pe wọn jẹ orilẹede 'Countries of Concern.'
Awọn orilẹede naa ni:
- Afghanistan – Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika
- Burma - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika
- Chad - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika
- Republic of DR Congo - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika
- Equatorial Guinea - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika
- Eritrea - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika
- Haiti - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika
- Iran - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika
- Libya - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika
- Somalia - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika
- Sudan - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika
- Yemen - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika
- Burundi - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika fun igba diẹ
- Cuba - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika fun igba diẹ
- Laos - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika fun igba diẹ
- Sierra Leone - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika fun igba diẹ
- Togo - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika fun igba diẹ
- Turkmenistan - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika fun igba diẹ
- Venezuela - Ko si aaye fun wọn lati wọ Amẹrika fun igba diẹ
Awọn orilẹede wo ni ko rọwọ họri ti wọ n pe ni "'Third World Countries?'
Orilẹede mẹrinlogoji ni ajọ UN ka sabẹ awọn ti ko rọwọ họri tabi ti oṣi n ta, iyẹn "'Third World Countries?' ti mẹtalelọgbọn wọn si wa nilẹ Afrika.
Awọn orilẹede naa ni Afrika ree:
- Angola
- Benin
- Burkina Faso
- Burundi
- Central African Republic
- Chad
- Comoros
- Democratic Republic of Congo
- Djibouti
- Eritrea
- Ethiopia
- Gambia
- Guinea
- Guinea Bissau
- Lesotho
- Liberia
- Madagascar
- Malawi
- Mali
- Mauritania
- Mozambique
- Niger
- Rwanda
- Senegal
- Sierra Leone
- Somalia
- South Sudan
- Sudan
- Togo
- Uganda
- Tanzania
- Zambia
Awọn ti ko rọwọ họri tabi ti oṣi n ta ni Asia:
- Afghanistan
- Bangladesh
- Cambodia
- Lao People's Democratic Republic
- Myanmar
- Nepal
- Timor-Leste
- Yemen
Awọn ti ko rọwọ họri tabi ti oṣi n ta ni Caribbean:
- Haiti
Awọn ti ko rọwọ họri tabi ti oṣi n ta ni Pacific:
- Kiribati
- Solomon Islands
- Tuvalu















