Kí ló fà á táwọn agbébọn ṣe rọgba yí ìpínlẹ̀ Kwara ká àti ipa tó ní lórí aráàlú?

Àkọlé fídíò, Kí ló fà á táwọn agbébọn ṣe rọgba yí ìpínlẹ̀ Kwara ká?
Kí ló fà á táwọn agbébọn ṣe rọgba yí ìpínlẹ̀ Kwara ká àti ipa tó ní lórí aráàlú?
    • Author, Faoziyah Saanu-Olomoda
    • Role, Journalist
    • Reporting from, Kwara

Ni bii ọdun mẹwaa sẹyin, ọkan lara awọn ipinlẹ ti eto aabo rẹ duro ire ni ipinlẹ Kwara jẹ ṣugbọn eyi ti yipada lati bii ọdun diẹ bayii

Awọn olugbe Kwara paapaa lawọn agbegbe kan ni ijọba ibilẹ Lafiagi, Patigi, Edu àti Baruten ni ẹkun ariwa ati ifelodun, Irepodun, Isin ati ijọba ibilẹ Ekiti ko le sun asunpiye mọ bayii

Eyi ko ṣẹyin bi ijinigbe ati ipaniyan ṣe n gbilẹ lojoojumọ lawọn agbegbe yii.

Ni ọsẹ to kọja lawọn agbebọn yawọ ile ijọsin CAC ni ilu Eruku, ṣekupa eeyan mẹta, ji eeyan mejidinlọgbọn gbe lọ ki wọn to gba itusilẹ ni ahamọ awọn ajinigbe naa lẹyn ọjọ marun-un

Awọn eeyan pupọ gbe akọle oniruuru lọwọ lati se iwọde tako iklu awọn agbebọn ati ijinigbe to n waye ni ipinlẹ Kwara.

Oríṣun àwòrán, Truth Nigeria

"Agbebọn ya wọ ibudokọ kan ni Ilesha Baruba, wọn si ṣina ibọn bolẹ nibi ti eeyan mẹjọ ti padanu ẹmi wọn"

Ṣaaju asiko yii ni awọn eeyan ilu Oke Ode ni ijọba ibilẹ Ifelodun sa fi ile wọn silẹ lẹyin ikọlu awọn agbebọn to ṣekupa eeyan mọkanla.

Inu oṣu Kẹjọ ni ilu Babanla atawọn ilu to wa ni agbegbe rẹ di ahoro latari ikọlu awọn agbebọn

Ni ẹkun ariwa, ninu oṣu kẹrin ọdun yii ni awọn agbebọn yawọ ibudokọ kan ni Ilesha Baruba, ijọba ibilẹ Baruten ti wọn si ṣina ibọn bolẹ nibi ti eeyan mẹjọ ti padanu ẹmi wọn

Ni ilu Karunji ati Kermanji, bakan naa ni ọmọ ṣe ṣori

Ọpọ awọn olugbe ilu Lafiaji, ijọba ibilẹ Edu nibi ti iwa ijinigbe ti di tọrọ fọkanle, lo ti n fi ilu silẹ lati wa aabo lọ sawọn ibomiran

Ibeere to gbẹnu ọpọ eeyan ni pe ki ni o ṣokunfa ijinigbe ati ipenija eto aabo to n sọ awọn olugbe ipinlẹ Kwara sinu inu fu aya fu yii?

Araalu kan ni Kwara to ba BBC News Yoruba sọrọ

"Lati bii ọdun 2016 si 2017 ni awọn agbebọn ti n fi awọn inu igbo to wa ni ipinlẹ Kwara ṣe ibugbe, tawọn eeyan si gbiyanju ta awọn ilu lolobo"

Nigba to n ba BBC News Yoruba, ọkan lara awọn eekan ilu ni ijọba ibilẹ ti ko fẹ darukọ oun woye pe lati bii ọdun 2016 si 2017 ni awọn agbebọn yii ti n fi awọn inu igbo to wa ni ipinlẹ Kwara ṣe ibugbe tawọn eeyan si gbiyanju ta awọn ijọba lolobo.

"Lati igba tawọn agbebọn yii ti wa ninu igbo lati bii ọdun 2016 si 2017, wọn ko maa ṣe ikọlu rara titi di nnkan bii oṣu mẹrin si marun-un sẹyin lọ.

Ero rẹ yii yatọ diẹ si ti Ọjọgbọn Abdulganiy Jawondo, onimọ nipa itan ni ile ẹkọ giga fasiti, University of Ilorin to gbagbọ pe awọn agbebọn yii ko fi ipinlẹ Kwara ṣe ibujokoo.

Jawondo, to tun figba kan ri jẹ adari ẹka imọ nipa ipẹtusaawọ, Centre for Peace and Strategic Studies ní University of Ilorin sọ pe afẹfẹ awọn ohun to n ṣẹlẹ ni awọn ipinlẹ to paala pẹlu Kwara lasan ni a n ri bayii.

Ilu kan ni ipinlẹ Kwara to da paroparo, koda, ọja wa nibẹ ti wọn ti pa

'Awọn ohun alumọni ilẹ tawọn kan fẹ maa wa lọna aitọ wa lara ohun to n fa ipenija eto aabo Kwara'

Amọ awọn mejeeji lo gba pe ohun alumọni inu ilẹ wa lara ohun to bi ikọlu awọn agbebọn paapaa ni ẹkun ariwa Kwara.

"O ṣeeṣe ko jẹ pe awọn ohun alomọni inu ilẹ lo ṣokunfa ikọlu awọn agbebọn yii nitori bi awọn to n wakusa ṣe n wọ ọpọ awọn ilu ti ohun alumọni wa lati gba aṣẹ fun iwakusa n pọ si.

"Láti bíi ọdún meji sẹyin bayii ni awọn awakusa labẹle atawọn ti ilẹ okeere n pọ si ni Kwara lati maa wa kusa."

Wọn rọ ijọba Kwara lati ri pe wọn mojuto eto iwakusa lojuna ati dena awọn to n lo awọn agbebọn lati maa fi da aabo iṣẹ ibi ti wọn n ṣe.

Ohun mii ti wọn ni o ṣokunfa bi awọn ajinigbe ṣe pọ lawọn ijọba ibilẹ yii ni pe o kun fun igbo eyi tawọn agbebọn le ha si fun igba pipẹ lai ni fu eeyan lara.

Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Kwara, Rafiu Ajakaye nigba to n ba BBC sọrọ, o wọ asọ alawọ omi aro, o si de fila si pẹlu. O ka ọwọ sori tabili ninu ọọfisi rẹ, awọn ẹrọ ti wọn fi n se ẹda iwe wa lẹgbẹ alaafia rẹ.

Ki ni ijọba ipinlẹ Kwara sọ?

Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Kwara, Rafiu Ajakaye nigba to n ba BBC sọrọ ṣalaye pe ọpọ awuyewuye lo ti n waye lori eto aabo to mẹhẹ ni Kwara.

O ni gbogbo igbesẹ to yẹ lati da aabo bo awọn eeyan ni ijọba n gbe ati gbogbo awọn ọlọpaa àtawọn ọmọ ogun ni wọn ti da sinu igbo lati ri pe aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia awọn eeyan.