Kókó ohun mẹ́jọ tí yóò ṣẹlẹ̀ lásìkò yìí pẹ̀lú ìkéde pàjáwìrì lẹ́kà ààbò tí Tinubu ṣe àti bó ṣe kàn ọ́

Awọn ọlọpaa ilu Eko lasiko iwọde kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ana Ọjọru ni Aarẹ Bola Tinubu kede ofin pajawiri ni ẹka eto abo Naijiria, paapaa lawọn ilu ti iṣẹlẹ ijinigbe ti di tọrọkọbọ lẹnu ọjọ mẹta yii.

Aarẹ tun paṣẹ ki wọn gba nnkan bii ẹgbẹrun lọna aadọta eeyan siṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ ologun lati le koju eto abo to mẹhe.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ gba oṣiṣẹ bii ẹgbẹrun lọna aadọta lati kun awọn ọlọpaa 370,000 to wa nilẹ lọwọ.

Koko ohun mẹjọ ti yoo sẹlẹ bi aarẹ Tinubu se kede ofin pajawiri lẹka eto abo Naijiria

Onimọ nipa eto aabo naa, Akin Adeyi wa salaye koko ohun to maa sẹlẹ lasiko yii ti ijọba apapọ kede igbesẹ pajawiri lẹka eso aabo.

O ni ijọba ni ojuṣe lati ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ fun araalu ki araalu naa si fọwọsowọpọ pẹlu ijọba.

Awọn koko to mẹnuba pe yoo sẹlẹ ree:

  • Naijiria yoo gbe gbogbo ofin to rọ mọ eto abo ti ṣẹgbẹ kan, ki awọn agbofinro le ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ lai si idiwọ kankan fun wọn.
  • Ofin pajawiri ni wọn yoo maa lo lakoko yii lawọn agbegbe ti ọrọ kan.
  • Awọn agbofinro le gbe irufẹ igbesẹ bẹẹ lai kọkọ duro de aṣẹ lakoko naa. Boya tẹlẹtẹlẹ, o yẹ ka duro de aṣẹ kan lati ibi kan ki a to le gbe igbese lati pinwọ iwa ibi kan, ko ni si bẹẹ mọ,
  • Ẹni to ba wa lagbegbe kan lasiko iṣẹlẹ ibi ba n waye le gbe igbesẹ lati yanju ọrọ naa lai kii ṣe pe o kọkọ beere lọwọ ẹnikẹni, ti ẹnikẹni ko si ni beere lọwọ rẹ pe 'kilode ti o fi ṣe bẹẹ.' Kii ṣe pe ki ọgagun kan ṣẹṣẹ maa duro de aṣẹ lati oke... tabi ko maa sọ pe wọn ti ni ki a ma yinbọn si wọn mọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
  • Awọn irin gberegbere kan ko ni si mọ.
  • Ko ni nilo ki wọn ṣẹṣẹ kede konileogbe mọ, agbofinro kan le da eeyan duro ko si sọ pe 'oya, maa lọ inu ile rẹ' lai ṣe pe niṣe lo tẹ ẹtọ araalu naa mọlẹ lati rin lasiko to ba wu u."
  • Ikede Aarẹ naa ti gbe ẹtọ araalu nipa ọrọ abo si ẹgbẹ kan ati pe gbogbo ẹka ileeṣẹ agbofinro ni Naijiria lo le ṣiṣẹ ara wọn lai si idiwọ kankan.
  • Ọlọpaa le ṣiṣẹ ṣọja, ti ṣọja yoo le ṣiṣẹ ọlọpaa; bẹẹ ni DSS le ṣiṣẹ NSCDC, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣe Naijiria nilo afikun si awọn ọlọpaa to wa nilẹ?

Nigba to n sọrọ lori igbesẹ Aarẹ lati gba nnkan bii ẹgbẹrun lọna aadọta eeyan si ileeṣẹ ọlọpaa, Adeyi ni imọ ẹrọ ni a nilo, kii afikun ọlọpaa.

O ni "Ko ni nnkankan lati ṣe pẹlu didaabo bo araalu bi ko ṣe ọrọ oṣelu pe 'ti a ba fun awọn ọmọ wọn nisẹ diẹ boya wọn maa tun dakẹ.'

"Ọrọ ọlọpaa ati eto abo laye ode oni kii ṣe nipa ki ọlọpaa pọ lapọju, bikoṣe nipa lilo imọ ẹrọ.

"Asiko ti awọn orilẹede ti wọn mọ nnkan ti wọn n ṣe n sọ pe kii ṣe nipa ọpọ ero nileeṣẹ eto abo lawa ṣẹṣẹ n sọ pe a gbọdọ gba ọpọ ero siṣẹ ọlọpaa.

"Eeyan meji pere ninu yara kan le ṣe iṣẹ ẹgbẹgbẹrun eeyan pẹlu ẹrọ 'drone' to n fo loju ofurufu."

O ni kii ṣe nipa gbigba ọpọ ero siṣẹ ọlọpaa ni eto abo yoo fi dara amọ nipa lilo imọ ẹrọ igbalode fun eto abo.

Ki ni ojuṣe araalu?

Onimọ eto abo naa sọ pe araalu gbọdọ maa sin ijọba atawọn agbofinro ni gbẹrẹ ipakọ paapaa lasiko ti ọdun n sunmọle yii.

Adeyi ni wọn gbọdọ maa bun ọlọpaa gbọ ni gbogbo igba ti wọn ba kofiri nnkan tabi eeyan ti ko yẹ layika wọn.

Lẹyin naa lo mẹnuba ọrọ awọn ọlọkada to n lo iboju lasiko yii.

O ni ko tọ fun ọlọkada lati maa lo iboju lati ṣiṣẹ nitori iru wọn le gbe eeyan lọ ti ẹnikẹni ko si ni mọ irufẹ ẹni to wa labẹ iboju ọhun.

O pari ọrọ rẹ pe oju ni alakan fi n ṣọri pe gbogbo araalu gbọdọ maa funra ki wọn si ṣọra fun ibi ti ọpọ ero ba pọju si lasiko pọpọṣinṣin ọdun nitori asiko yii gan ni awọn kọlọrọsi ẹda maa n ṣọṣẹ.

Kí ni ìtúmọ̀ ìgbésẹ̀ pàjáwìrì lórí ètò ààbò tí ààrẹ Tinubu kéde àti kókó ìgbésẹ̀ méjìlá tó mẹ́nubà láti kojú ààbò tó mẹ́hẹ

Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu wọ agbádá olómi aro

Oríṣun àwòrán, Presidency

Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu ti kéde ìgbésẹ̀ pàjáwìrì lórí ètò ààbò orílẹ̀ èdè yìí látàrí àwọn ìkọlù lemọ́lemọ́ tó wáyé láwọn apá ibìkan láti bíi ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn.

Nígbà tó ń ṣe ìkéde náà ni ààrẹ tún darí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àti ológun láti túnbọ̀ gbà àwọn òṣìṣẹ́ síi.

Àtẹ̀jáde tí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìròyìn ní Nàìjíríà fi léde lọ́jọ́rú sọ pé ìgbésẹ̀ náà yóò ṣe ìrànwọ́ fún gbígba àwọn ọlọ́pàá 20,000 sẹ́nu iṣẹ́.

Ó ní èyí yóò jẹ́ àlékún sí àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n kó kúrò lẹ́yìn àwọn èèkàn ìlú, tí wọ́n sì máa ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún wọn kí wọ́n le kájú òṣùwọ̀n nídìí dídá ààbò bo àwọn aráàlú.

Bákan náà ni ààrẹ tún pàṣẹ fáwọn òṣìṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, Department of State Services, DSS láti gba àwọn aṣọ́gbó tí yóò máa ṣọ́ igbó ọbá.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Iléeṣẹ́ DSS ní àṣẹ mi láti da àwọn aṣọ́gbó tí wọ́n ti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún sínú igbó ọba láti kojú àwọn agbéṣùmọ̀mí àtàwọn agbébọn dànù kúrò nínú igbó tí wọ́n ń fara pamọ́ sí.

"Wọ́n ní àṣẹ láti ọ̀dọ̀ mi láti túnbọ̀ gba àwọn òṣìṣẹ́ si kí wọ́n lọ máa ṣọ́ àwọn igbó ọba."

Ìgbésẹ̀ ààrẹ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan táwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ilé ìjọsìn CAC ní Eruku ìpínlẹ̀ Kwara, ilé ẹ̀kọ́ GGCSS ní Maga, ìpínlẹ̀ Kebbi àti ilé ẹ̀kọ́ St Mary's Catholic, Papiri ìpínlẹ̀ Niger.

Ìjọba kéde gbígba ìtúsílẹ̀ àwọn olùjọsìn táwọn agbébọn náà jí gbé ní Kwara àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kebbi ṣùgbọ́n àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ilé ẹ̀kọ́ St mary's ṣì wà ní àhámọ́ àwọn ajínigbé náà títí di àsìkò yìí.

Lára àwọn ohun tí ààrẹ ní ó máa ṣe ìrànwọ́ láti kojú ìpèníjà ààbò ni kí àwọn aṣòfin tètè buwọ́lu ìdásílẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀.

Ó ní káwọn aṣòfin ṣe kíákíá láti ṣe àgbéyẹ̀wò òfin tó máa jẹ́ káwọn ìpínlẹ̀ tó bá fẹ́ dá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ sílẹ̀ láti tètè ṣe bẹ́ẹ̀ lásìkò.

Lórí ìkọlù tó máa ń wáyé láàárín àwọn àgbẹ̀ àti darandaran, Tinubu ní òun ti darí iléeṣẹ́ tó ń rí sí nǹkan ọ̀sìn láti tètè wá ojútùú sí ìṣòro náà.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Kí ni pàjáwìrì ètò ààbò tí ààrẹ kéde?

Ìpè pàjáwìrì lórí ètò ààbò túmọ̀ sí pé ṣíṣe ìkọlù sí gbogbo àwọn ọ̀daràn tó ń mú ìpèníjà bá ètò ààbò bá Nàìjíríà, onímọ̀ nípa ètò ààbò kan sọ fún BBC News Yorùbá.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé látàrí bí ètò ààbò tó lágbára tó nílò àtúnṣe ní kíákíá.

Ó ní yóò jẹ́ ìgbésẹ̀ láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn aráàlú pẹ̀lú àtìlẹyìn ìjọba.

Okasanmi fi kun pé ìgbésẹ̀ ètò ààbò tó nílò àtìlẹyìn ìjọba tó fi mọ́ ohun ìjà ogun àti ohun tí wọ́n fi máa ṣe ìrìnnà.

Àkóónú ìpèníjà ètò ààbò pàjáwìrì

Ààrẹ Tinubu kéde pé ìnílò wà fún ètò pàjáwìrì lẹ́ka ètò ààbò àti ohun tó túmọ̀ sí gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ààrẹ ṣe sọ.

  • Gbígba àwọn òṣìṣẹ́ ààbò si, tí wọ́n sì máa kó wọn lọ sí àwọn agbègbè tí ìpèníjà ààbò ti lágbára.
  • Àwọn iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àti iléeṣẹ́ ológun ní àṣẹ láti gba àwọn òṣìṣẹ́ kúnra si.
  • Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá máa gba òṣìṣẹ́ 20,000 kún 30,000 tí ààrẹ ní kí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá gbà kúnra.
  • Àwọn ọlọ́pàá le máa lo àwọn ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn àgùnbánirọ̀ láti máa ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún ìgbà kan ná.
  • Àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n kó kúrò lẹ́yìn àwọn èèkàn ìlú nílò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n tó kó wọn padà sáwọn agbègbè tí ìpèníjà ètò ààbò wà.
  • DSS gba àṣẹ láti da àwọn aṣọ́gbó sí igbó ọba láti lọ kojú àwọn agbébọn àtàwọn agbéṣùmọ̀mí tí wọ́n ń fi igbó ọba ṣe ibùgbé.
  • DSS ní àṣẹ láti gba àwọn aṣọ́gbó síi.
  • Tinubu rọ àwọn aṣòfin láti ṣe àgbéyẹ̀wò ìdásílẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀, kí wọ́n sì fún àwọn ìpínlẹ̀ tó bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ láṣẹ láti tẹ̀síwájú.
  • Ààrẹ rọ àwọn ẹgbẹ́ darandaran láti lo àǹfàní iléeṣẹ́ nǹkan ọ̀sìn tí wọ́n dá sílẹ̀ láti máa wá oúnjẹ fáwọn ẹran wọn. kí wọ́n fòpin sí dída ẹran jẹ oko ní gbangba.
  • Bákan náà ni wọ́n ní kí wọ́n dènà lílo àwọn ohun ìjà olóró lásìkò tí wọ́n ń daranjẹ̀.
  • Ààrẹ ní kí àwọn tó ń dá ilé ẹ̀kọ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń gbé máa ri dájú pé wọ́n ń pèsè ààbò tó yẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì yàgò fún gbígbé ilé ẹ̀kọ́ sáwọn ibi tó jìnà sínú ìlú.
  • Kí àwọn ilé ìjọsìn máa gba àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò lásìkò tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ètò àdúrà tàbí ìpéjọpọ̀ ọlọ́pọ̀ èrò.