Ẹ̀yin ológun, ẹ gbákoso, rọ̀gbà yí àwọn igbó ọba tó wà ní Kwara, Niger àti Kebbi ká, ẹ gba àwọn tó wà ní ìgbèkùn ajínigbé kalẹ̀ - Tinubu

Oríṣun àwòrán, @SundayDareSD
Bi awọn ajinigbe ṣe fi kun ikọlu wọn lati ọsẹ to kọja titi wọ ọsẹ yii, Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ pe ki awọn ọmọ ogun ta okun aabo yi awọn igbo ka lawọn ipinlẹ kan ni Naijiria.
O ni ki wọn rọgba yi awọn igbo naa ka, lati tun so okun aabo le si i.
Awọn ipinlẹ mẹta ti Aarẹ paṣẹ igbesẹ yii fun bayii ni Kwara, Niger ati Kebbi .
"Gbogbo agbegbe pata ni iṣẹ aabo yii kan, awọn ẹṣọ alaabo yoo ṣiṣẹ pọ lati ri awọn ti wọn ji gbe gba pada"
Oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin ati ibaralusọrọ Sunday Dare, lo kede eyi loju opo X rẹ lọjọ Iṣẹgun.
Bakan naa ni Aarẹ paṣẹ pe kawọn ẹṣọ oju ofurufu fi kun iṣẹ wọn, nipa bi wọn yoo ṣe maa wọde awọn apa ibi to wọnu ninu igbo ipinlẹ Kwara.
Awọn agbegbe naa ni igbagbọ wa pe awọn agbesunmọmi n fi ara pamọ si bo ṣe sọ.
O fi kun pe bi wọn yoo ṣe maa dọdẹ awọn ajinigbe naa fun wakati mẹrinlelogun, yoo kun iṣẹ awọn ọmọ ogun ori ilẹ to wa ni ipagọ lọwọ.
Aarẹ tẹsiwaju pe gbogbo agbegbe pata ni iṣẹ aabo yii kan, nibi ti awọn ẹṣọ alaabo yoo ti maa ṣiṣẹ pọ lati ri awọn ti wọn ji gbe gba pada.
Bakan naa ni wọn rọ awọn eeyan ilu ti iṣoro aabo yii kan, lati tete maa fi to awọn alaṣẹ leti bi wọn ba kẹẹfin irin afurasi kan.
Eyi yoo ran awọn ẹṣọ alaabo naa lọwọ lati mu aabo pada.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















