Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 24 tí wọ́n jí gbé ní Kebbi gba ìtúsílẹ̀

Aworan ibusun ile ẹkọ naa ti ko si awọn akẹkọọ nibẹ

Oríṣun àwòrán, Mustapha Ibrahim Maga/BBC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Lẹyin ọjọ mẹsan-an ni ahamọ awọn ajinigbe, awọn akẹkọọbinrin ti wọn ji gbe nile ẹkọ girama Government Girls Comprehensive Senior Secondary School (GGCSS) Maga, ipinlẹ Kebbi, ti gba itusilẹ.

Bayo Onanuga, Oludamọran pataki fun Aarẹ Tinubu lori ikede, lo fi eyi sita lonii ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu Kọkanla ọdun 2025, loju opo X rẹ.

Atẹjade naa sọ pe Aarẹ Tinubu ti ki awọn ọmọbinrin mẹrinlelogun naa kaabọ, bẹẹ lo gboriyin fun awọn ẹṣọ to jẹ ki itusilẹ naa ṣee ṣe.

" Ọkan mi fuyẹ bayii ti awọn ọmọbinrin mẹrinlelogun yii ti pé, a gbọdọ tete tun jara mọṣẹ lati dena ijinigbe ni awọn agbegbe miran ti wọn tun wa ninu ewu ijinigbe.

"Ijọba mi yoo pese gbogbo iranwọ lati mu eyi ṣẹ."

Bẹẹ ni atẹjade naa wi.

Aarẹ Tinubu rọ awọn agbofinro lati ma ṣe dẹkun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe lori aabo.

Bawo ni awọn ọmọ naa ṣe gba itusilẹ?

Gẹgẹ bi awọn ẹka iroyin ṣe ro o, ilana ibaraẹnisọrọ lai lo ipa ni ijọba lo lati gba awọn akekọọ naa kalẹ.

Wọn fi kun un pe ifọwọsowọpọ awọn ẹka DSS ati ONSA lo tun mu itusilẹ naa waye.

Ninu fidio kan to ṣafihan awọn ọmọdebinrin naa ninu ọkọ to gbe wọn de, wọn n darukọ ara wọn ati kilaasi ti wọn wa ki awọn ajinigbe too gbe wọn lọ.

Wọn ka ara wọn nikọọkan, ejeeji, wọn si jẹ mẹrinlelogun.

Bakan naa ni awọn fọto ati fidio wọn nigba ti wọn de ti balẹ si oju opo ayelujara kiri.

Ẹ o ranti pe ọjọ Aje to kọja ni awọn ajinigbe ya bo ile ẹkọ (GGCSS), ti wọn ko akẹkọọbinrin mẹẹẹdọgbọn lọ.

Iṣẹlẹ naa lo mu Aarẹ Tinubu, paṣẹ fun Minisita eto aabo, Mohammed Bello Matawalle, lati ko lọ si Kebbi, ko si maa mojuto igbesẹ ijoba lati ri awọn akekọọ naa gba pada.

Ọjọru ni awọn ọmọ naa yoo pada sọdọ awọn obi wọn-Gomina Kebbi

Ninu ọrọ tirẹ, Gomina ipinlẹ Kebbi, Nasir Idris, fidi ẹ mulẹ pe awọn akẹkọọ naa ti gba ominira.

Nibi ipade awọn akoroyin to ṣe lọjọ Iṣẹgun lo ti ni awọn akekọọ naa ti n pada bọ ni Kebbi lasiko ti ipade ọhun n lọ lọwọ.

O ni Ọjọru, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kọkanla ni awọn yoo fa wọn le awọn obi wọn lọwọ.

Gomina Idris sọ pe alaafia ni awọn ọmọdebinrin naa wa .

O dupẹ lọwọ Aarẹ Tinubu, awọn agbofinro ati awọn ojiṣẹ Ọlọrun to ni wọn ko sinmi adua lọsan-an loru latigba ti awọn akẹkọọ naa ti lọ.

Wo àwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n gbé ìlẹ̀kùn ilé ẹ̀kọ́ tì pa ní Naijiria torí ààbò tó mẹ́hẹ

Aworan yara ikawe ti ko si akẹkọọ nibẹ, afi awọn aga to ṣófo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin awọn iṣẹlẹ ijinigbe to waye leralera lọsẹ to kọja yii ni awọn ile ẹkọ girama meji lorilẹede yii, awọn ile ẹkọ kan ti beere fun pe ki ijọba jẹ kawọn ti ilẹkun ibẹ pa na.

Pupọ awọn ile ẹkọ naa lo jẹ eyi ti awọn akẹkọọ n gbe nibẹ, ṣugbọn ti kaluku ti pada sile awon obi rẹ bayii.

Awọn ibudo ikẹkọ naa yoo wa titi pa titi ti nnkan yoo fi fararọ pada, gẹgẹ bi awọn alaṣẹ wọn ṣe kede. Bo tilẹ jẹ pe awọn akẹkọọ kan ti jajabọ lọwọ ajinigbe ninu awọn ti ipinle Niger, bi ajọ CAN ṣe kede, ti awọn kan ṣi wa nigbekun naa.

Wọnyi ni awọn ipinlẹ ti wọn ti ti ile ẹkọ pa bayii pẹlu aṣẹ ijọba

Ìpinlẹ Kebbi:

Ijọba ipinlẹ Kebbi ti paṣẹ titipa awọn ile ẹkọ ijọba ati ti adani nibẹ, titi kan awọn ile ẹkọ giga to wa niluu naa, afi ile ẹkọṣẹ imọ nipa iṣẹ nọọsi to wa ni Birnin Kebbi nikan ni wọn fi silẹ.

Kọmiṣanna eto ẹkọ giga ni Kebbi, Issa Abubakar-Tunga ati Kọmiṣanaa fun ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ati girama, Halima Bande, lo kede eyi ninu atẹjade kan.

Ẹ o ranti pe ipinlẹ Kebbi ni wọn ti ji akẹkọọ-binrin mẹẹẹdọgbọn lọ lọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025 yii.

Awọn ile ẹkọ to kan ni Kebbi ni:

*Kebbi State Polytechnic Dakingari

Abdullahi Fodio University of Science and Technology, Aliero

College of Health Sciences and Technology, Jega

Adamu Augie College of Education Argungu, ati School of Remedial Studies, Yauri.

Ipinlẹ Katsina:

Ijọba Katsina paṣẹ pe ki gbogbo ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ati girama wa ni titipa.

Kọmiṣanna fun eto ẹkọ alakọọbẹrẹ ati girama ni Katsina, Yusuf Suleman Jibia, lo kede ọrọ naa, pẹlu alaye pe o kan awọn ile ẹkọ ti awọn akẹkọọ n gbe nibẹ naa.

IpinlẹYobe:

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Yobe kede titi awọn ile ẹkọ ti awọn ọmọ n gbe nibẹ pa titi ti ẹkọ eto aabo yoo fi ṣe oju u mimu pada.

Ipinlẹ Kwara:

Ọrọ naa ko yọ ipinlẹ Kwara sile, ẹgbẹ awọn olukọ, Nigeria Union of Teachers (NUT), ẹka ti Kwara lo fi atẹjade to kede titi awọn ile ẹkọ pa naa sita.

Alaga NUT, Yusuf Agboola, sọ pe awọn ile ẹkọ to wa ni ijọba ibilẹ Isin, Irepodun, Ifelodun ati Ekiti yoo wa ni titipa.

"Irọ́ ni pé gbogbo ilé ẹ̀kọ́ Naijiria yóò wà ní títìpa"

Ẹwẹ, ijọba apapọ Naijiria ti ni irọ gbuu ni iroyin kan to ni ki gbogbo ile ẹkọ wa ni titipa ni Naijiria lati ojọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025.

Ọjọ Ẹti to kọja yii ni iroyin naa gbode, pe ijọba apapọ Naijiria ti paṣẹ pe ki wọn ti awọn ile ẹkọ girama 47 pa kaakiri Naijiria.

Iroyin naa sọ pe nitori ohun to ṣẹlẹ ni nipinlẹ Niger ati Kebbi ni ijọba ṣe gbe igbesẹ ọhun.

Nigba ti wọn n ṣalaye bi ọrọ naa ṣe jẹ, ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si eto ẹkọ, kọ ọ si oju opo X wọn pe iroyin aṣinilọna ni iroyin naa.

Wọn ni ko ti ọdọ ijọba Naijiria wa, irọ gbuu si ni.

Agbẹnusọ ileeṣẹ eto ẹkọ lorilẹede yii, Boriowo Folashade, ṣalaye ninu atẹjade to buwọ lu, pe kawọn eeyan Naijiria ma ṣe gba iroyin naa gbọ, nitori ko wa lati ọdọ ijọba apapọ.

Àwọn igba ti wọn ti ti ile ẹkọ pa ri ni Naijiria

Ọdun 2022 ni titi ile ẹkọ pa waye gbẹyin lorilẹede Naijiria, eyi waye lasiko ti awọn agbebọn n gbero ikọlu niluu Abuja.

Awọn alaṣẹ paṣẹ pe ki gbogbo ile ẹkọ wa ni titipa, wọn si le awọn akekọọ lọ sile awọn obi wọn ni Abuja ati Nasarawa.

Iroyin sọ nigba naa pe awọn agbebọn n gbero lati kọlu awọn ipinlẹ kan, titi kan olu ilu Naijiria ti i ṣe Abuja.

Ni 2021, awọn ile ẹkọ lapa Ariwa koju ikọlu pupọ, o si le ni akẹkọọ ọgọrun-un ti wọn ko lọ ni Katsina.

O le ni akẹkọọ ọkunrin ọọdunrun (300 boys) ti wọn ji gbe nile ẹkọ kan ni lagbegbe Kankara, loṣu Kejila ọdun naa, ṣugbọn wọn pada fi wọn silẹ.

Ni 2020, ọpọ ipinlẹ l'Ariwa lo paṣẹ pe kawọn akẹkọọ gba ile wọn lọ, lẹyin ijinigbe to waye ni Katsina.

Kano, Kaduna, Zamfara ati Jigawa naa ti awọn ile ẹkọ pa nigba naa lẹyin ikọlu Kastina.

Lẹyin-o-rẹyin ni ikọ alakatakiti ẹsin Islam, Boko Haram, kede pe awọn lawọn wa nidii ijinigbe naa.