Olúgbohùn ni wọ́n fi bá ìyàwó mi sọ̀rọ̀, wọ́n ti ra á níyè kó tó tẹ̀lé wọn, kìí ṣe ojú lásán - Ọkọ òṣìsẹ́ FRSC tí wọn pa òun àti ọmọ rẹ̀ ṣàlàyé

Oluwamayokun Lasisi ninu aṣọ iṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo pẹlu ọmọbinrin rẹ Sewa

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 14

Ọgbẹni Jimoh Lasisi, to jẹ ọkọ Oluwamayokun, oṣiṣẹ FRSC ti wọn pa nipinlẹ Osun ti bá BBC News Yorùbá sọrọ nípa ikú aya rẹ náà.

Ọkunrin naa sọ pe iyawo oun kii ṣe ẹni ti wọn le tan lọ sibikibi, ṣugbọn ó ní olugbohun ni wọn fi gbe Oluwamayokun ati ọmọ oun kuro nile lọjọ ti wọn dele gbẹyin.

''Iroyin ibanujẹ lo jẹ fun mi wi pe ọmọ ọdun mẹwaa ti ko tii mọ ohunkohun ni wọn tun pa danu.

O dun mi gidi. Ologbohun ni wọn fi pe iyawo mi kuro nile lọjọ to kuro nile.

Gbogbo nnkan to n ṣe latigba ti wọn ti fi ologbohun naa pe e jade ni ko mọ.

Aṣọ kan ṣoṣo to wọ jade lọjọ naa lo wa lọrun rẹ, ko to di pe wọn pa a.

''O fọ aṣọ ile-ẹkọ Adeṣẹwa tan ni, o si tun n lọ aṣọ naa lọwọ ni, ko to di pe wọn fi olugbohun pe e kuro nile.

A ko tii fẹ sọ gbogbo ohun to ṣẹlẹ sita bayii, nitori pe iwadii ko tii pari.

Wọn ti ra iye iyawo mi pẹlu oogun abẹnugọngọ ti wọn fi pe e.

''Gbogbo ohun ti wọn n ṣe pẹlu ẹ lẹyin naa ni ko ye e si.

Gbogbo ibi ti wọn n lọ, lo n tẹle wọn lọ.

Mọto ni Victor wa fi gbe wọn nile, to si gbe wọn lọ si Ikoyi-Ile.

Igba ti wọn de Ikoyi-Ile, lo gbe mọto naa silẹ lẹgbẹ titi, to si fi kọkọrọ sẹnu ẹ nibẹ, lati le jẹ ki awọn eeyan ro pe niṣe ni wọn ji wọn gbe."

Lasisi tẹsiwaju pe ''Mọto miran ni Victor fi gbe wọn lati Ikoyi-Ile lọ si Iwoye Ijesa, nibi ti wọn ti lọ pa a.

Ibi ti wọn fi mọto naa silẹ si, ni wọn ti pa foonu iyawo mi, nitori to ti mọ pe a maa wa.

Babalawo naa jẹwọ gbogbo ohun to ṣelẹ fun wa. ''

"Victor kii ṣe ololufẹ ikọkọ iyawo mi, ó kere pupọ si aya mi lọjọ orí"

Nigba to n sọrọ lori iroyin to sọ pe ọrẹ ikọkọ ni Victor ati Oluwamayokun jọ n ṣe, ki ọrọ to yiwọ, Jimoh sọ pe ko si nnkan to jọ bẹẹ rara.

O ni Victor ati iyawo rẹ, ni wọn jọ mọ iyawo oun lọjọ kan naa, ati pe ọmọkunrin naa kere si iyawo oun lọjọ ori pupọ, ti iru nnkan bẹẹ ko si le ṣẹlẹ laaarin wọn.

''Ọjọ kan naa ni Iyawo Victor ati Victor jọ mọ iyawo mi, ṣugbọn Victor lo wa n sunmọ iyawo mi ju, wọn si ti wa jọ dabi ọrẹ-mọlẹbi.

Wọn ti jọ wa wọnu ara wọn, wọn si maa n mu iyawo mi lọ sori oke lati gbadura.

O maa n tẹle wọn lọ si Oṣogbo lati lọ gbadura, o si ti wa fọkan tan wọn gidi." Jimoh fidi rẹ mulẹ.

''A ṣi n gbadura pe ka ri iṣẹ naa ṣe daadaa.

Ni kete ti awọn ọlọpaa ba ti pari iṣẹ wọn, a maa fun un yin ni iroyin ayọ, nitori pe mo fẹ ki wọn gbe wọn lọ sile-ẹjọ loju ẹsẹ ni."

''Emi ni mo fun awọn ọlọpaa nibi ti Victor n gbe niluu Ileṣa ati Osogbo, mo si ni gbogbo iroyin naa lọwọ"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lasisi ni ibanujẹ nla lo jẹ fún òun wi pe awọn amookunṣeka ṣeku pa iyawo oun, ati ọmọ obinrin kan ṣoṣo tI òun bi nigbesi aye oun.

Lasisi ni bo tilẹ jẹ pe ko tii to akoko lati sọrọ, sibẹ, oun ko nii ṣai sọ diẹ lati le jẹ ki awọn eeyan mọ okodoro ọrọ èyí to yatọ si ohun ti awọn eeyan n gbe kaakiri ori ayelujara.

''Mi o tii ro pe asiko ree fun mi lati sọrọ, nitori pe iwadii ṣi n lọwọ.

Ẹnu mi nikan naa lẹ ti le gbọ okodoro, ṣugbọn lọwọlọwọ bayii, mo ni lati mọ riri gbogbo ẹyin akọroyin patapata ati awọn to n ba mi kẹdun,''

Ọgbẹni Jimoh sọ bẹẹ fun akọroyin.

Baale ile naa sọ pe nigba to to asiko lati ba iyawo ati ọmọ oun sọrọ, ṣugbọn toun ko gburo wọn, lo jẹ ki ara fu oun, toun si ranṣẹ sawọn eeyan lati ṣewadi ibi ti wọn wa.

''Emi ni mo fun awọn ọlọpaa nibi ti Victor n gbe niluu Ileṣa ati Osogbo, mo si ni gbogbo iroyin naa lọwọ.

A ti ri oku Sewa, niṣe lo pa oun naa.

Awa araalu nilo ọpọ nnkan lati ṣe, lati maa fi daabo bo ara wa.

Ọmọbinrin kan ṣoṣo ti mo ni niyẹn.''

''Ko sẹni to le sọ pe oun loun ran mi lọwọ lati ṣe ohunkohun lori nnkan to ṣẹlẹ yii"

Lasisi Jimoh tí fi ye wa saaju pe ipari ọdun 2019 loun kuro ni Naijiria lati wa atijẹ lọ silẹ Amẹrika, toun si n ṣe ẹtọ lori iyawo ati ọmọ oun latigba naa.

''Ọkọ daradara ni mo jẹ, ti mo si n gbaruku ti iyawo ati ọmọ mi.

N ko gbadura pe iru nnkan bayii le ṣẹlẹ si mi lasiko ipenija ti mo wa yii.

Mo ṣẹṣẹ lo ọdun marun-un nilẹ Amẹrika ni, ipari ọdun 2019 ni mo lọ silẹ Amẹrika.

''Ko sẹni to le sọ pe oun loun ran mi lọwọ lati ṣe ohunkohun lori nnkan to ṣẹlẹ yii.

''Alakoso eto igbaniwọle nile ẹkọ ọmọ mi, Alaba Lawson, ni mo kọkọ pe lati beere boya wọn ri ọmọ mi nile-ẹkọ.

Lójú ẹsẹ lo si ti pe mi wi pe wọn ko rii ni kilaasi JSS 1.

Mo ni lati pe ọrẹ mi kan naa lati sọ fun un pe ko lọ ba mi wo ọmọ ni nile-ẹkọ.

''Igba to ya, mo tun juwe ile ti iyawo ati ọmọ mi n gbe fun un, to si lọ wo wọn.

Mo tiẹ kọkọ ni ki wọn ja ferese wọle, ko ma lọ jẹ nnkan ti ṣẹlẹ si wọn ọ inu ile, ṣugbọn pabo naa lo ja si.

Loju ẹsẹ ni mo tun ti pe mama mi, ati baba iyawo mi, lati fi to wọn leti."

Lasisi tẹsiwaju pe baba iyawo oun sọ pe ọjọ́ Ẹtì lawọn ti jọ sọrọ gbẹyin.

"Lẹyin eyi ni mo ranṣẹ si ọrẹ mi kan to jẹ ọga ọlọpaa ni Eleweran lati ba mi gbe igbesẹ bi wọn yoo ṣe wa a ri.

Satide ni èmi pẹlu ẹ ti sọrọ gbẹyin. Mo fi ẹrọ ibanisọrọ iyawo mi ranṣẹ sii lati ṣiṣẹ lee lori.

''Igba to maa ba mi sọrọ gbẹyin, o ni Ikoyi-Ile nipinlẹ Osun loun tọpinpin ẹrọ ibanisọrọ naa si.

Iyawo mi ti sọ fun tẹlẹ pe oun fẹẹ wa ṣọọṣi kan lati gbadura, ibẹ ni ọkan mi kọkọ ro o lọ, wi pe boya adura lo lọ gba nibẹ,'' O ṣalaye.

"Ko tii ju wakati mejidinlaadọta ti wọn pa ọmọ ati aya mi, la ṣẹṣẹ ri oku wọn, wọn ti kun oku iyawo mi wẹlẹ̀wẹlẹ"

Nigba to n kọminu lori bi awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ko ṣe tete gbe igbesẹ lati doola ẹmi iyawo ati ọmọ oun, Jimoh sọ pe ohun to ba oun lọkan jẹ gidi ni.

O ni ka ni awọn ọlọpaa tete dide si ọrọ naa ni, ki wọn si ma ṣe fi falẹ, o ṣee ṣe ki wọn ri awọn mejeeji gba silẹ lọwọ amookunṣeka naa, ko to di pe wọn da ẹmi wọn legbodo.

''O ṣe ni laanu pe awọn ọlọpaa ko ṣiṣẹ lori iroyin ti mo fun wọn, ka ni wọ́n ṣiṣẹ wọn ní, o ṣee ṣe ki wọn ri iyawo ati ọmọ mi gba jade laaye, ko ma jẹ pe iku lo maa tọ si wọn.

Awọn ọlọpaa to n ri sọrọ ijinigbe l'Ogun ko ṣe daadaa to.

''Gbogbo igba to yẹ ki wọn wa wọn lọ, ni wọn sọ pe awọn n duro de ọga wọn to lọ gba ọmọ ilẹ China kan ti wọn jigbe niluu Ijẹbu-Igbo.

Ọjọ bii marun-un lo gba wọn, ki wọn to pari iṣẹ naa.

Niṣe ni wọn gbe ọrọ temi sẹgbẹ kan, ko si nnkan ti mo fẹẹ ṣe.

''Awọn ọlọpaa ipinlẹ Osun lo pada ṣiṣẹ yẹn, ati pe ka ni awọn ti Ogun tete bẹrẹ iṣẹ ni, a maa ri wọn gba jade.

Ko tii ju wakati mejidinlaadọta ti wọn pa wọn la ṣẹṣẹ ri oku wọn.

Ka ni wọn ti pa wọn tipẹ ni, oku wọn yoo maa jẹra, ṣugbọn niṣe lara wọn ṣi tutu.''

*Wọn pin ẹya ara iyawo mi si wẹwẹ*

''Nigba ti mo n wo oku yẹn, ọkan mi bajẹ, wọn ti pin ẹya ara iyawo mi si wẹlẹwẹlẹ, kii ṣe ohun ti mo le fi pamọ."

Lasi ni ko tii to asiko ti oun le sọrọ bayii, nitori pe iwadii ṣi n lọ lọwọ.

Bí ọwọ́ ọlọ́pàá ṣe tẹ afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú òṣìṣẹ́ FRSC àti ọmọ rẹ̀, ọkọ olóògbé sọ̀rọ̀ sókè nípa bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé

Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Ghana ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi apaayan kan, Victor Benjamin Fajemirokun, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, tí wọ́n fẹsun kan pé wọn lọwọ ninu iku oṣiṣẹ FRSC ti wọn ji gbe niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Ọga ọlọpaa kan nilẹ Ghana lo fi iroyin naa lede ninu fọnran kan to tẹ BBC News Yorùbá lọwọ lalẹ ọjọ Aiku to kọja.

Nínú alaye rẹ, ọ̀gá ọlọ́pàá náà ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe waye.

''Mo fẹ fi to o yin leti nipa ọmọ ilẹ Naijiria kan ti a fura si pe o pa obinrin kan ati ọmọ rẹ lorileede Naijiria, to si sa wa si Ghana lati maṣe jẹ ki ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ ni Naijiria.

''Victor Benjamin Fajemirokun, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ni ọwọ tẹ lori fọnran kan to n lọ kaakiri ori ayelujara, nibi ti wọn ti fẹsun kan an wi pe o ṣeku pa oṣiṣẹbinrin ti ajọ Road Safety, iyẹn FRSC, ati ọmọ rẹ ni Abẹokuta.

''Afurasi naa ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijijria n wa, ṣugbọn to sa wa si Ghana lati farapamọ lọdọ ọrẹ rẹ kan.

Nigba ti a gbọ ibi ti afurasi naa farapamọ si, awọn ọlọpaa sare lọ sibẹ lati mú.

O si ti wa lahamọ wa bayii, pẹlu bi igbesẹ ṣe n lọ lati fa a le ọlọpaa Naijiria lọwọ,'' iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ghana lo ṣalaye bẹẹ.

Ohun tí a mọ̀ rèé lórí ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín òṣìṣẹ́ FRSC tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ọ̀rẹ́kùnrin pa òun àtọmọ rẹ̀

Olóògbé Oluwamayokun Adegbuyi ninu aṣọ iṣẹ ẹṣọ oju popo

Oríṣun àwòrán, Others

Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe awọn apanijaye ti pa oṣiṣẹ ẹṣọ aabo ojupopo (FRSC), ẹka ti ilu Abeokuta, Arabinrin Lasisi Funmilayo Oluwamayokun, ẹni ti wọn ji oun pẹlu ọmọ rẹ gbe niluu Abeokuta, ipinlẹ Ogun, lọjọ keji, oṣu Kọkanla, ọdun 2025.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ni ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Victor Benjamin Fajẹmirokun ni wọn fura si pe o ji obinrin naa ati ọmọ rẹ, Sewa, gbe lati pa, sibẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ko ti i sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa.

Ẹnikan to sunmọ mọlẹbi oloogbe ọhun to ba BBC News Yoruba sọrọ, ṣalaye pe ọrẹ ikọkọ ni Victor ati oṣiṣẹ FRSC naa n ba ara wọn ṣe lati bi ọdun meloo sẹyin.

Ẹni naa sọ ọ di mimọ pe ipinlẹ Osun ni Victor n gbe, to si n yan obinrin naa ni ale niluu Abeokuta. O ni awọn ṣi n wa afurasi naa di bayi.

O ni bi Oloogbe Oluwamayokun ṣe n lọ ba Victor nibi to n gbe, bẹẹ naa ni ọkunrin ọhun n wa siluu Abeokuta.

O fi kun un pe ọmọ kan ṣoṣo, Sewa naa ni Oluwamayokun bi fun ọkọ rẹ, kiyẹn too rin irin ajo lọ soke okun, nibi to ba atijẹ atimu lọ.

"Ọdún mẹ́sàn-án sẹ́yìn ni ọkọ Oluwamayokun ti lọ sílùú òyinbo láti ṣiṣẹ́ ajé, tó sì ń fi owó ránṣẹ́ sí wọn"

Gẹgẹ bi ẹni to ba BBC News Yoruba sọrọ naa ṣe ṣalaye, o ni ọdun kẹsan-an ree ti ọkọ Oloogbe Oluwamayokun ti rin irinajo iṣẹ aje lọ si oke okun.

O ni aini amumọra lo jẹ ki oṣiṣẹ FRSC yii wa ọkunrin ti wọn yoo jọ maa ṣe wọle-wọde.

"Ki aṣiri ma ba a tu lo jẹ ko rin jinna lati wa ọrẹkunrin naa sipinlẹ Osun. Iyẹn nikan kọ, Victor ati oṣiṣẹ FRSC yii ko ṣẹṣẹ maa lọ sile adahunṣe ati babalawo," Ẹni naa lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.

Siwaju si i, o ni lọjọ ti Oluwamayokun ati ọmọ rẹ naa di awati, Victor lo waa gbe wọn ninu ile lọ sipinlẹ Osun, pẹlu erongba lati lọ sọdọ babalawo, lai mọ pe erongba ohun ti wọn fẹẹ lọ ṣe nibẹ yatọ.

"Nigba ti wọn de ipinlẹ Osun, ile babalawo naa ni Sewa wa fun bi ọjọ meji, ti Mayokun ati ale re si lọ gbadun ara wọn, ko to di pe wọn pada sile babalawo naa.

"Ko sẹni to mọ ibi ti Victor pada gbe Sewa lọ, nitori a gbọ pe Mayokun nikan lo pa, ti a si ri oku rẹ, ṣugbọn a ko ri oku ọmọ naa, bẹẹ ni a ko ri aaye rẹ."

Bakan naa lo sọ pe bo tilẹ jẹ pe ọwọ ti tẹ babalawo to lọwọ ninu iku oṣiṣẹ FRSC ọhun, sibẹ ko ti i sẹni to le sọ pato ibi ti Victor ati Sewa wọlẹ si.

O wa rọ awọn agbofinro lati tubọ ṣiṣẹ iwadii wọn daadaa, ki wọn si lo ẹrọ ibanisọrọ Victor lati fi tọpinpin ibi to ba wa, ki idajọ ododo le waye.

Àlàyé lórí bí afurasí ọ̀rẹ́kùnrin àti babaláwo ṣe gbìmọ̀ pọ̀ ṣekúpa òṣìṣẹ́ FRSC àti ọmọ rẹ fún ètùtù ọlà

Oluwamayokun Lasisi ninu aṣọ iṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo pẹlu ọmọbinrin rẹ Sewa

Oríṣun àwòrán, Other

O dabi ẹni pe aṣiri iku to pa oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ alaabo oju popo, FRSC, ẹka tipinlẹ Ogun, Arabinrin Lasisi Funmilayo Oluwamayokun ati ọmọ rẹ, Adesewa Lasisi, ti tu o lẹyin ti Babalawo tọwọ ọlọpaa tẹ jẹwọ pe Victor to jẹ ọrẹkunrin Sewa lo wa ba oun fun aajo owo.

Babalawo naa ṣalaye pe Victor lo du awọn mejeeji lọrun to si lọ sọ oku wọn seti odo, lẹyin to ti ge ori ati awọn ẹya ara wọn lọ.

Awọn ọlọpaa ni a gbọ pe wọn pada lọ gbe oku tọmọ-tiya naa lọ si ile igbokusi ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti ti ipinlẹ Osun fun ayẹwo lati mọ iru iku to pa wọn.

Victor ti na papa bora, titi di asiko ti a kọ iroyin yii ni awọn ọlọpaa si n ṣeleri wi pe ọwọ yoo tẹ Victor laipẹ bi iwadii ṣe n tẹsiwaju.

Ohun to ti ṣẹlẹ ṣaaju

Awuyewuye si n lọ lori iku oṣiṣẹ ẹṣọ aabo oju popo, ẹka tipinlẹ Ogun, Arabinrin Oluwamayokun ati ọmọ rẹ, Adesewa ti awọn amookunṣeka ṣekupa lairotẹlẹ nipinlẹ Osun.

Kayeefi si ni iṣẹlẹ naa si jẹ fun ọpọ eeyan titi di akoko yii, eyi lo jẹ kawọn eeyan maa pe fun idajọ ododo lori ọrọ naa.

Ọjọ Aiku, ọjọ keji, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 ti a wa yii ni a gbọ pe obinrin naa jade nile pẹlu ọmọ rẹ, to si jẹ pe lati igba naa ni ẹnikẹni ko ti gburo wọn.

Ninu atẹjade ti Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi sita lọjọ Karun-un, oṣu Kọkanla, ọdun 2025, ni o ti jẹ ko di mimọ pe awọn n wa obinrin naa ati ọmọ rẹ.

Odutọla lo jẹ ko di mimọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ FRSC pẹlu awọn mọlẹbi Oluwamayokun ni wọn wa fi to ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni agbegbe Kemta Idi-Aba leti wi pe wọn ko gburo awọn mejeeji mọ lati ọjọ Kẹji, oṣu yii.

''Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun nilo iranlọwọ araalu lati ṣawari SRC Lasisi Funmilayo Oluwamayokun, ẹni ọdun mejidinlogoji to jẹ oṣiṣẹ Federal Road Safety Corps, ẹkun Abẹokuta, ati ọmọ rẹ, Sewa Lasisi, tawọn ẹbi wọn n wa,'' agbẹnusọ ọlọpaa lo sọ bẹẹ ninu atẹjade to fi sita.

Atẹjade ọhun sọ siwaju sii pe SRC Lasisi ati ọmọ rẹ kuro nile ti wọn n gbe ni lagbegbe Obasanjo Hilltop Estate, Oke-Mosan, Abeokuta, laarọ ọjọ Aiku, ọjọ keji, oṣu Kọkanla, ọdun 2025, wọn ko si tii pada sile latigba naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni gbogbo akitiyan lati ba wọn sọrọ lori foonu lo ja si pabo, nitori ti ẹrọ ibanisọrọ naa ko lọ

Lẹyin naa ni Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Ogunlowo, paṣẹ pe ki iṣẹ iwadii bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lati le mọ ibi ti obinrin naa ati ọmọ rẹ wọlẹ si, ki wọn si rii daju pe wọn pada sile layọ ati alaafia lai farapa.''

Wọn ṣawari oku Oluwamayokun ati ọmọ rẹ nile babalawo l'Osun

Iyalẹnu nla lo jẹ nigba ti awọn kan bẹrẹ sii gbe iroyin kan kaakiri pe wọn ti ṣawari oku Oluwamayokun ati ọmọ rẹ, Sewa nile babalawo kan nipinlẹ Osun.

Ọkunrin oniroyin kan nipinlẹ Ogun, Solanke Ayomideji Taiwo lo gbe iroyin naa sita l'Ọjọru ọsẹ yii wi pe wọn ti ṣawari oku oṣiṣẹ FRSC ati ọmọ rẹ ninu ile babalawo naa.

Solanke sọ pe ipakupa ni awọn amookuṣeka pa iyale ile naa ati ọmọ rẹ danu, koda to ni o ṣee ṣe ko jẹ pe niṣe ni wọn fi wọn ṣẹṣo ọla.

Iroyin to tẹ BBC Yoruba lọwọ jẹ ko di mimọ pe kete ti ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Bankole ti gbọ, lo ti kan si ọga ọlọpaa ipinlẹ Osun lati rii daju pe ọwọ tẹ afurasi babalawo naa, lati le jẹ ki iwadii ijinlẹ waye, ki okodoro si foju han.

"Iku oṣiṣẹ FRSC naa ati ọmọ rẹ jẹ eyi to ba ni lọkan jẹ pupọ, ti a ko le gba laaye. A maa rii daju pe a ṣiṣẹ iwadii ijinlẹ lati rii pe ọwọ tẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu iku naa, ki idajọ ododo le waye," ọga ọlọpaa sọ bẹẹ.

Ọwọ tẹ afurasi babalawo

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun jẹ ko di mimọ pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi babalawo to lọwọ ninu iku Oluwamayokun, oṣiṣẹ FRSC ati ọmọ rẹ, Sewa.

Ohun ti a gbọ ni pe alakoso agba fun ileeṣẹ FRSC, ẹkun TS11.1 nipinlẹ Osun, Leye Adegboyega ati alakoso oluwadii ni wọn ṣabẹwo si ọga ọlọpaa ipinlẹ Osun, Ibrahim Gotan.

Nibi ipade naa ni ọga ọlọpaa ti ṣalaye wi pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi babalawo naa, to si lawọn ti n fi ọrọ wa lẹnu wo.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ jẹ ko di mimọ pe babalawo naa ti n ṣe iranlọwọ fun ọlọpaa.

Gẹgẹ bi Gotan ṣe ṣalaye, o ni ọga agba lẹka ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ ijinigbe ti sọ pe bi Oluwamayokun ati ọmọ rẹ ṣe poora niluu Abẹokuta, ko ṣẹyin ọrẹkunrin rẹ ti orukọ rẹ n jẹ Victor.

O ni ẹrọ ibanisọrọ Ọgbẹni Victor naa fidi rẹ mulẹ pe oun pẹlu babalawo naa jọ n duna dura niluu Iwoye Ijesa, ipinlẹ Osun, ko to di pe tọmọ-t'iya naa dawati.

A rii gbọ pe ilu Iloko Ijesa lọwọ ti tẹ Babalawo naa.