Tinubu, Dapo Abiodun ń ṣèdáró Segun Awolowo, ọmọ-ọmọ Baba Awolowo tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 62

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/Facebook
Aarẹ Bola Tinubu n ṣedaro Segun Awolowo, ọmọ-ọmọ Baba Obafemi Awolowo to jade laye lẹni ọdun mejilelọgọta.
Ninu atẹjade kan ti oludamọran aarẹ lori ọrọ iroyin, Bayo Onanuga, fi sita ni Aarẹ Tinubu ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi Awolowo.
Tinubu ṣapujuwe iku Segun gẹgẹ bii nnkan to bani lọkan jẹ, aarẹ ni gbogbo orilẹede Naijiria lo n kẹdun oloogbe, kii ṣe ẹbi Awolowo nikan.
Aarẹ ni Segun huwa bi Ọmọluabi ati gẹgẹ bii ẹni to jade lati inu ẹbi baba Awolowo.
''Gbogbo ọna ni Segun fi jọ Baba Awolowo, o jọ baba ninu iṣesi ati ninu ihuwasi rẹ.
Segun jẹ agbẹjọro gẹgẹ bii baba-baba rẹ, o si duro fun idajọ ododo ati otitọ.
Lanaa Ọjọbọ ni ẹbi Baba Awolowo kede iku Segun ninu atẹjade kan ti ẹbi naa fi sita.
''Pẹlu ọgbẹ ọkan ni a fi kede iku ọkọ, baba, ati baba-baba wa – Olusegun Awolowo.
Segun jẹ ọkọ, baba ati baba-baba to ṣe e mu yangan, o jẹ ẹni to ni ifẹ, ti o si ko ẹbi mọra,
O jẹ olufọkansin si orilẹede Naijiria, gbogbo ipa ati agbara rẹ ni o fi sin Naijiria nigba aye rẹ.
Ọrẹ gidi ni Segun, o si tun jẹ ojiṣẹ Ọlọrun ati ẹni to nifẹẹ ọmọniyan.
Iku rẹ bawa lọkan jẹ, amọ, a dupẹ fun igbesi aye to dara ti o gbe ati ifẹ to fi han si gbogbo wa.
A gbadura wi pe ki Eledua tẹ ẹ si afẹfẹ rere.
Gomina Dapo Abiodun ipinlẹ Ogun ṣedaro Segun Awolowo
Gomina Dapo Abiodun ipinlẹ Ogun naa n ṣedaro Segun Awolowo to di oloogbe.
Gomina Abiodun ni ibanujẹ ni iku Segun jẹ, o ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bi ẹni to ni igboya ti o si fi gbogbo agbara rẹ sin orilẹede Naijiria.
Abiodun sọ loju opo X rẹ pe pẹlu ibanujẹ ọkan loun fi gba iroyin iku Segun.
''Iyalẹnu ni iku Segun Awolowo jẹ fun wa, adanu nla ni iku Segun jẹ.
Segun jẹ ọlọpọlọ pipe eeyan ati ẹni ti ko ni aapọn rara.
A o ni gbagbe awọn ẹkọ ti a ti ri kọ lara Segun nigba aye rẹ,'' Gomina Abiodun lo sọ bẹẹ.
Lọdun 2021 ni wọn dibo yan Segun Awolowo gẹgẹ bii aarẹ ajọ NTPO to n ri si okowo ninu ajọ ECOWAS, ipo yii naa lo si wa titi to fi jade laye.















