El Mencho: Olórí agbóògùn olóró tí wọ́n fi pósí wúrà sin òkú rẹ̀ ní Mexico

Aworan Posi El Menchiọ

Oríṣun àwòrán, Reuters

    • Author, Vanessa Buschschlüter
    • Role, Latin America digital editor
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Olori agboogun oloro ni Mexico, Nemesio Oseguera Cervantes, tí ọpọ mọ si El Mencho, ni ẹbi rẹ ti sin pẹlu posi oni wura ni ọjọ Aje.

El Mencho ni o padanu ẹmi rẹ lẹyin to farapa lasiko ti ija bẹ silẹ laarín awọn oluṣọ rẹ ati awọn ikọ ologun Mexico ti wọn ran wa lati mu un ni iparí Oṣu Keji.

Ẹni ọdun mọkandinlọgọta naa to jẹ oludasilẹ ẹgbẹ ajẹṣepọ Jalisco New Generation Cartel (CJNG) jẹ eeyan ti ilu naa n wa, ti orilẹede Amẹrika si gbe ẹbun owo toto $15m (₤11.2m) kalẹ fun ẹni to ba ni ọna bi wọn ṣe le mu un.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Francisco Guasco/EPA/Shutterstock

Iku rẹ fa ọpọ rogbodiyan ti awọn ẹgbẹ rẹ si dana sun ọpọ, gbe igi dena opopona kaakiri ogun ipinlẹ lorilẹede Mexico.

Awọn ọmọ ẹgbẹ ti Ẹṣọ ti Orilẹ-ede naa jade sita lati ṣe idiwọ iwa-ipa tuntun lati dide lasiko isinku to waye ni tosi Guadalajara ni ipinlẹ Jalisco, odi agbara fun ọmọ ẹgbẹ cartel naa.

Ọpọ ododo nla ni a rii ti wọn gbe wọle sinu ile isinku ṣaaju ayẹyẹ naa, pẹlu ọkan ti o ni apẹrẹ bi akukọ ni itọkasi ifẹ rẹ si akukọ.

Gẹgẹ bii ile-iṣẹ iroyin AFP sẹ sọ, awọn ọkọ ajagbe marun un ni wọn nilo lati gbe gbogbo awọn ododo lọ si isinku naa.

Ilana isinku naa wa pẹlu ẹgbẹ kan to n kọ orin ranchero ati narcocorridos - awọn orin yii wa lati ma kan saara si oloogbe naa.

Lẹyin wakati kan, awọn oludarọ - ọpọlọpọ ninu wọn ti fi idanimọ wọn pamọ nipa lilo iboju - tẹle apoti naa bi wọn ṣe n gbe lọ si iboji.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aworan Posi oni goolu

Oríṣun àwòrán, Ulises Ruiz/AFP via Getty Image

Àkọlé àwòrán, The drug lord was buried in Jalisco state late on Monday