Àjọ ICPC kéde àwọn nǹkan tí wọ́n kó nílé El-Rufai l'Abuja, ẹbi El-Rufai ké gbàjarè

Nasir El-Rufai wọ aṣọ buba alawọ eeru ati fila dudu

Oríṣun àwòrán, Kaduna State Governmnent

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ ICPC to n gbogun ti iwa ibajẹ ti ṣalaye awọn nnkan ti ajọ naa ko nile gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, Nasir El-Rufai, to wa niluu Abuja.

ICPC fidi ọrọ yii mulẹ ninu ẹjọ ti wọn pe tako El-Rufai to n beere fun biliọnu kan naira owo gba mabinu lori ẹsun pe ajó naa tẹ ẹtọ ọmọniyan oun mọle nile ẹjọ giga apapọ to wa niluu Abuja.

El-Rufai sọ pe bi ajọ ICPC ṣe mu oun ti wọn si ju oun si atimọle ati bi wọn ti lọ ko awọn nnkan ninu ile oun lodi sofin.

Amọ, ninu ẹjọ ti ICPC pe, ajọ naa kepe ile ẹjọ lati yi ẹjọ El-Rufai danu tori awọn oṣiṣẹ ajọ naa ko tapa sofin pẹlu gbogbo nnkan ti wọn ṣe fun Rufai.

ICPC ṣalaye pe awọn ọlọpaa tẹle awọn oṣiṣẹ ajọ naa lọ si ile El-Rufai, ati pe iyawo rẹ gan an, Hadiza El-Rufai, ati ọmọkunrin rẹ, Muhammed El-Rufai, wa nile nigba ti ajọ ICPC lọ sile rẹ.

Lara awọn nnkan ti ICPC ri nile El-Rufai ni oriṣiiriṣii iwe akaunti, fọọmu ti El-Rufai fi kede dukia rẹ, iwẹ ẹri iforukọ okowo silẹ atawọn iwe mii to ni ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu ADC.

Awọn nnkan mii ti wọn tun ri nile El-Rufai ni iwe akọsilẹ ti ijọba ipinlẹ Kaduna fi yawo lati ilẹ okeere eyi ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kaduna buwọlu lọdun 2015 si 2023.

Lara awọn nnkan mii ti wọn tun ri nile El-Rufai ni iwe ẹri idokowo pẹlu Ecobank Nigeria, iwe ilẹ, iwe owo fawọn akẹkọọ to fi mọ iwe ilukoro fun ọfiisi gomina.

Awọn nnkan mii ti ICPC tun ko nile El-Rufai ni ohun elo kọmputa ti oloyinbo n pe ni falsh drive mẹsan an, oriṣiiriṣii ẹrọ kọmputa MacBook, foonu Blackberry, Nokia N95, Toshiba, SamsungIDEOS, Google IDEOS atawọn nnkan mii.

ICPC ni gbogbo nnkan ti ajọ naa ko nile El-Rufai lo wa ni akọsilẹ tori awọn maa lo wọn fun iṣẹ iwadii.

Ẹwẹ, ẹbi El-Rufai ti fẹsun kan ICPC wi pe wọn fẹ fẹsun iwa ọdaran kan gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ tori o dakẹ lasiko ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo.

Ninu atẹjade kan ti Bello El-Rufai buwọlu, El-Rufai sọ pe ki ICPC gbe oun lọ sile ẹjọ ti wọn ba ri ẹsun kankan ka soun lẹsẹ.

Ẹbi El-Rufai ni didakẹ rẹ ko tumọ si pe o jẹbi awọn ẹsun ti ICPC fi kan an.

Ẹbi naa tun sọ pe awọn foonu ti ko dara mọ atawọn ohun elo kọmputa ti wọn n pe ni flash drive nikan ni ajọ ICPC ko nile El-Rufai.

Awọn ẹsu ti wọn fi kan El-Rufai

Ẹsun kinni ni pe El-Rufai gba ọna ti ko ba ofin mu lati ti ọwọ bọ foonu Nuhu Ribadu, eyii to lodi si abala 12(1) ofin Naijiria ni ti wọn ṣe atunṣe rẹ lọdun 2024.

Ẹsun keji ni pe El-Rufua sọ pe oun ṣiṣẹ pẹlu ẹnikan to tọwọ bọ foonu Nuhu Ribadu, eyii to lodi si abala 27(b) ti ofin ori ayelujara ti wọn ṣatunṣe rẹ lọdun 2024.

Ẹsun kẹta ni pe Mallam Nasir El Rufai lo imọ ẹrọ lati ṣakoba fun araalu ati abo orilẹede Naijiria nipa bo ṣe tọwọ bọ foonu Ribadu, eyii to sọ funra ninu ifọrọwerọ kan lori ẹrọ amohunmaworan Arise lọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2026.

Wayi o, ṣaaju ipẹjọ yii ni awọn ọtẹmuyẹ DSS ti kọkọ gbiyanju lati fi panpẹ ofin mu afurasi naa ni papakọ ofurufu amọ to kọ jalẹ lati jẹ ki wọn mu oun.

O sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC lẹyin igbiyannu naa pe niṣe ni ijọba Naijiria n dunkoko mọ oun, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ labẹ ijọba awarawa.