Sunday Igboho Aides: Olajengbesi àti Ilana Omo Oodua sọ ìdí tí DSS ṣe wowọ́ mọ́ èèyàn mẹ́rin

Awọn eeyan to gba idande

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore Facebook

Ni ọjọ Aje ni okiki kan pe mẹjọ ninu awọn eeyan mejila tawọn oṣiṣẹ agbofinro DSS mu ni ile Sunday Igboho ni ọjọ kini oṣu keje ọdun 2021, ti gba idande.

Amọ ọpọ ibeere lo jade lori idi ti awọn DSS ko fi tu awọn mẹrin yoku silẹ lẹyin ti ile ẹjọ ti paṣẹ pe ki wọn gba oniduro wọn.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, agbẹjọro fun awọn mejila naa, Amofin Pẹlumi Ọlajẹmgbesi ṣalaye pe idi ti awọn mẹrin yoku naa fi wa ni ahamọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn o ni iṣẹ nlọ lati tu awọn mẹrinla yoku silẹ.

O fikun pe ohun ti ileeṣẹ DSS ko fẹ ko jade sita faraye gbọ, ti wọn fi n wonkoko mọ awọn eeyan naa ni ohun to pe ni iwa ibajẹ ati titẹ oju ofin mọlẹ ti wọn hu nile Sunday Igboho loru ọjọ ti wọn kọlu u.

Awọn eeyan to gba idande

O ni awọn fẹ kọkọ gba awọn mẹrin to ku naa silẹ na, ki awọn to yanju awọn ariwisi ti DSS n gbe sike lori awọn oniduro wọn.

DSS ko fẹ ki asiri iwa ibi to hu nile Sunday Igboho tu lo se wowọ mọ awọn mẹrin naa - Olajengbesi

O ni gbogbo ọgbọn ti awọn DSS n da ni pe " wọn ko fẹ ki awọn to wa lahamọ jade, ki wọn ma baa le sọ nnkan ti oju wọn ri ni ọjọ ti DSS wa si ile Oloye Sunday Igboho.

Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ ti a si gbagbọ, wọn ni awọn DSS atawọn ṣọja to wa, wọ gbogbo awọn yara, gbogbo gbọngan ati gbogbo ibi ti wọn ba wọ ni wọn kan n yinbọn si."

O ni wọn ko tilẹ fẹ mọ boya eeyan wa nibẹ tabi ko si nibẹ ti wọn sa n ṣina ibọn bolẹ.

Ọkan ninu awọn ẹsọ Igboho ti DSS pa ko riran:

"Oloogbe adogan (ọkan lara awọn meji ti wọn pa nile Sunday Igboho) ibi to sa pamọ si ninu ile iwẹ ni ibọn ti ba. Ẹni keji to jẹ alfaa tori pe ko riran daadaa, ni ko mọ ibi ti yoo gba, ibi ti o ti n kaakiri ni ibọn ti baa"

O ni lara awọn mejila naa, eyi ti awọn oṣiṣẹ DSS fi ọmọ odo lu ninu wọn wa, ti Eleduwa kan da ẹmi wọn si.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Lori ọrọ ti DSS sọ pe lori awọn ohun ti wọn ba ni ile oloye Sunday Igboho loru ọjọ naa, Amofin Ọlajemgbesi ṣalaye pe ileeṣẹ agbofinro DSS nikan lo mọ ibi ti wọn ti ri ibọn.

Bakan naa lo kede ẹru DSS ni ibọn ti wọn n sọ pe awọn ri nile Igboho ati pe, awọn gan lo mọ ibi ti wọn ti ri wọn.

O fi kun un pe, bi wọn ba ni awọn ri oogun ati iwe irinna soke okun, ẹtọ oloye Sunday Adeyẹmọ ni lati ni awọn nnkan bayii.

O salaye pe niwọn igba ti wọn ko lee mu pasitọ nitori Bibeli, ti wọn ko si lee mu alfa nitori pe wọn ba Kurani ninu ile rẹ, gẹgẹ bi ọmọ Yoruba atata Sunday Igboho mu awọn nnkan iṣọra ati iṣẹṣe lọkunkundun.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Ki ni ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua naa sọ?

Ninu ọrọ tiwọn, ẹgbẹ agbarijọpọ awọn to n ja fun idasilẹ orilẹede Yoruba, ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua ṣalaye pe awọn mọ pe awọn alagbara kan lo n mu ki awọn oṣiṣẹ DSS maa hu iwa itapa-sofin bo ṣe wu wọn.

Alagba Akinọla, to jẹ akọwe agba ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua ni lẹyin ti ile ẹjọ ti sọ pe ki wọn gba oniduro awọn eeyan mejila naa, sọ fun BBC News Yoruba pe ohun ti iwa DSS n tọka si ni pe, wọn ko bọwọ fun ofin Naijiria, bẹẹ si ni ko si ẹni kan tabi ileeṣẹ kan to ga ju ofin lọ.

O ni DSS gbọdọ jẹjọ fun awọn eeyan meji ti wọn pa nile Sunday Igboho nigba ti wọn foru boju kọlu ile eekan to n ja fun idasilẹ orilẹede Yoruba.