Sunday Igboho: Yorùbá yóò gba òmìnira láìpẹ́, ó dá mi lójú

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1
Ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Sunday Igboho ti sọ pe o da oun loju pe ipe fun orilẹede Oduduwa, Yoruba Nation yoo wa si imuṣẹ laipẹ.
Sunday Igboho to sọrọ lati ẹwọn ni orilẹede Benin Republic ni agbẹnusọ rẹ, Olayomi Koiki, fi isẹ rẹ jẹ fawọn ololufẹ rẹ.
Ninu ọrọ rẹ, Koiki ni Sunday Igboho ni ki oun dupẹ fun awọn adari ni ilẹ Yoruba ati kaakiri orilẹede Naijiria to ṣe atilẹyin fun oun, paapaa ni asiko ti oun wa ni panpẹ ni orilẹede Benin Republic.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ̀yin olùwọ́de Yoruba Nation, Arewa ń fẹ́ kẹ jáwọ́ àmọ́... - Àgbàgbà Yoruba
- Sunday Igboho, Nnamdi Kanu tó ń dàámú wa ti kó sẹ́wọ̀n, Ọlọ́run wa kò sùn - Miyetti Allah
- Ajínigbé kọlu ìjọ David Oyedepo, wọ́n jí èèyàn mẹ́ta gbé lọ
- Àjàlú ńlá ń bọ̀ Buhari múra, màrìwò eégún lásán lo rí ní NDA - Fr Mbaka
- Sunday Igboho tún dá Malami mọ́lẹ̀ fún ìgbà kejì nílé ẹjọ́
- DSS tú mẹ́jọ sílẹ̀ nínú àwọn ọmọlẹyìn Igboho, mẹ́rin ṣì wà ní àhámọ́
- Alálẹ̀ ló fi èmi àti Sunday Igboho pamọ́ sí àhámọ́ kí ewu le ré wa kọjá - Oba Ogboni
Lara awọn ọba ti Igboho ni ki wọn dupẹ lọwọ rẹ ni Ooni of Ife, Oba Enitan Ogunwusi; Osile ti Oke Ona ilẹ Egba, Oba Adedapo Adewale Tejuoso; Olugbon of Orile Igbo, Oba Francis Alao.
Bakan naa ni Igboho ni ki wọn dupẹ lọwọ gbajugbaja ọjọgbọn ati onkọwe Wole Soyinka, Aarẹ orilẹede Benin Republic, Patrice Talon ati Minisita fun eto idajọ lorilẹede Benin Republic.
Sunday Igboho ni afojusun oun ni pe bi orilẹede Benin Republic ti oun ti wa ni atimọle ṣe n gbadun ina ọba loore-koore, naa ni ilẹ Yoruba yoo ma gbadun rẹ lẹyin ti ominira ba de.
''Baba wa fi ikini ranṣẹ si gbogbo ọmọ Yoruba kaakiri agbaye.
Bakan naa lo fi ikini ranṣẹ si Ooni ti Ile Ife, Adeyeye Ogunwusi, fun aduroti ati atilẹyin wọn fun oun, nitori iyawo oun jiṣẹ wọn fun oun ni gbogbo igba.
O ni ki n ki Ọba Olugbọn pẹlu Ọba Tejuosho naa to ti wa ni orilẹede Benin Republic lọwọ bayii, amọ ti awọn ko i tii ri ara wọn.
Sunday Igboho ni ki n dupẹ lọwọ Ọjọgbọn Agba ati Onkọwe Wole Soyinka, aarẹ ilẹ Benin Republic ati minisita fun eto idajọ fun bi wọn ṣe pese aabo to peye fun iyawo Sunday Igboho lai jẹ ki ibi kankan sun mọ iyawo naa.''
Bakan naa lo ni ki a wo bi Benin ṣe n jẹ igbadun ina ọba ni gbogbo igba eleyii to ṣọwọn ni Naijiria. Amọ Yoruba Nation yoo gbadun ina ọba bi eyi lẹyin ti wọn ba ṣe aṣẹyọri pẹlu gbigba eto wọn si ominira lọwọ ijọba Naijiria.''
Ikọ ọtẹlẹmuyẹ lorilẹede Naijiria lo fi panpẹ ọba mu Igboho ati iyawo rẹ ni Cotonou, Benin Republic ni ọjọ kọkandinlogun, Oṣu Keje, lẹyin to sakuro ni Naijiria lati bọ lọwọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n wa naa.
Ajọ DSS lo yabọ ile Igboho ni ilu Ibadan, ti ẹmi sọfo ti wọn si mu lara awọn alatilẹyin rẹ, amọ ti wọn ko ri Igboho mu ni ilẹ rẹ.
Lẹyin naa ni Agbẹnusọ Ajọ DSS fi atẹjade sita wi pe ijọba orilẹede Naijiria n wa Sunday Igboho ki o si jọwọ ara rẹ lai si rogbodiyan nitori ọwọ yoo tẹ bi o fẹ bi o kọ.
Laipẹ naa ni ọwọ tẹ Sunday Igboho ati iyawo rẹ ni orilẹede Benin Republic lasiko ti oun ati iyawo rẹ n gbiyanju lati salọ si orilẹede Germany.
Amọ, iyawo Igboho gba itusilẹ kuro ni panpẹ ọlọpaa nigba ti Igboho ṣi wa ni atimọle ni orilẹede Benin Republic.





















