Sunday Igboho: Ìjà ní yóò gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ yíí tí ìjọba kò bá fí Sunday Igboho sílẹ̀

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Others

Agbẹnusọ fun ajijagbara Sunday Igboho, Olayomi Koiki ti rọ awọn ọmọ Yoruba lati dide dasi ọrọ Sunday Igboho ti awọn agbofinro DSS mu ni orilẹede Benin Republic.

Koiki lo sọ bẹẹ lasiko to n sọrọ lori ẹrọ ayelujara lori iroyin pe wọn ti fi Sunday Igboho si panpẹ ijọba.

Lasiko to n sọrọ naa ni kii ṣe tuntun mọ pe wọn ti mu Sunday Igboho amọ ọna abayọ si itusilẹ rẹ ni pe ki gbogbo awọn ọmọ Yoruba kaakiri agbaye fi ẹhọnu han paapaa ni awọn ileeṣẹ ijọba ilẹ okeere paapaa Germany ati Benin Republic.

''Ọna abayọ lo yẹ ki a ma a wa, ko yẹ ki a da ọrọ yii da Ọjọgbọn Banji Akintoye nikan, gbogbo wa ni ọrọ naa kan.''

''A gbọdọ sọ wi pe ko i tii tan, a ṣẹṣẹ bẹrẹ ni nitori ọpọlọpọ Sunday Igboho ni yoo dide pẹlu igbesẹ ti ijọba n gbe''

''Ọjọ Kini, Osu Keje ni ijọba Naijiria ti fẹ pa Sunday Igboho amọ ti ori ko o yọ, ti wọn si pa awọn eniyan ninu ile rẹ''

Agbẹnusọ Sunday Igboho naa kesi awọn eniyan paapaa awọn to wa ni oke okun lati tu yaya jade ki wọn fi ẹhọnu han tako bi ijọba ṣe fi panpẹ mu Sunday Igboho.

Bakan naa lo fikun pe awọn ti gba agbẹjọro to datọ lorilẹede Benin Republic ti yoo dena ijọba Naijiria to fẹ da Sunday Igboho pada wa si Naijiria lati wa koju ẹsun ti ijọba fi kan an.

Koiki ni Sunday Igboho sọ fun awọn alatilẹyin rẹ pe ki wọn ma ṣekọlu si awọn agbofinro titi ti wọn fi mu u.

Amọ Koiki ni ija ni yoo gbẹyin ọrọ yii bi ijọba ba fẹ bi wọn ba kọ, ti wọn ko ba fi Sunday Igboho silẹ ni ẹrọ ko ma a lọ ni alaafia nitori ko ṣe ijọba, awọn eniyan rẹ ti awọn Fulani darandaran n pa lo n ja fun.

Bakan naa lo fikun pe ki awọn ọmọ Yoruba to wa ni oke bi ti oun ma dakẹ lori ọrọ Sunday Igboho nitori kii ṣe ẹṣẹ si ijọba lati bere fun ominiran kuro lara orilẹede.