Sunday Igboho: Páropáro ní iléẹjọ́ dá, tí wọn sì fi àgádágodo ti ẹnu ọ̀nà

Ile ẹjọ giga ijọba apapọ ni Abuja

Yatọ si ikede to waye lọjọ Aje pe igbẹjọ awọn eeyan ti DSS ko nile Sunday Igboho yoo waye lọjọ Isẹgun, tii se ọjọ ọdun Ileya, amọ ọrọ ko ri bẹẹ mọ.

Nigba ti BBC Yoruba kan sile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa nilu Abuja, lati mọ boya lootọ nile ẹjọ naa yoo joko lati gbọ ẹjọ naa, a ri pe paro paro ni ibẹ da.

Koda, a ko ri awọn agbẹjọro, ọlọpaa tabi awọn eeyan kankan to yọju sile ẹjọ naa lati wa mọ ohun ti yoo sẹlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda, agadagodo ni wọn fi ti ẹnu ọna abawọle ile ẹjọ naa, ti gbogbo ọọfisi to wa nibẹ si wa ni titipa.

Bẹẹ ba gbagbe, Adajọ Yomi Aliyu ti kede saaju fun BBC Yoruba pe oun yoo yọju sile ẹjọ naa lonii, boya adajọ joko lati gbọ ẹjọ naa abi bẹkọ.

Amin iyasọtọ kan

Adajọ fi igbẹjọ awọn afurasi ti DSS ko nile Sunday Igboho si ọjọ ọdun Ileya

Awọn eeyan ti DSS ko nile Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, DSS

Agbẹjọro fun awọn eeyan mejila ti DSS ko nile Sunday Igboho Yomi Aliyu, ti ni igbẹjọ yoo bẹrẹ lori ẹjọ ti wọn pe tako ajọ DSS nile ẹjọ ni ọjọ Isẹgun ọla.

Bẹẹ ba gbegbe, ọla ọjọ Isẹgun ni ọjọ ọdun Ileya, ti ijọba si ti kede pe isinmi ọlọjọ fun awọn ọmọ Naijiria lati gbadun ọdun naa.

Ireti si wa pe awọn osisẹ ile ẹjọ, awọn agbẹjọro atawọn adajọ gan yoo wa lẹnu isinmi fun ọdun Ileya naa.

Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba, Agbẹjọro Aliyu ni lootọ ni ijọba fi ọjọ igbẹjọ si ọjọ ọdun ileya.

"Iru rẹ ko sẹlẹ ri, a ko wa mọ ohun to le mu ki adajọ ni oun fẹ gbọ ẹjọ naa lọjọ ọdun, to si mọ pe isinmi wa, gbogbo awọn afurasi yii si ni wọn fẹ ko lọ sile ẹjọ.

Awọn eroja ti DSS ko nile Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, DSS

Amọ ibeere ni pe awọn wo gan lo fẹ ko awọn afurasi yii de ile ẹjọ.? Awọn ọlọpaa ti yoo ko wọn lọ gan yoo se ọdun nile.

Amọ, a ko tii mọ iru ara ti wọn fẹ da, awa yoo de ile ẹjọ lọla, bi adajọ joko, bi ko joko, awa yoo wa nibẹ.

Awa la pe ijọba apapọ lẹjọ lati tako bi wọn se ti awọn eeyan naa mọle lọna ti ko ba ofin mu, ti wọn ko si jẹ ki awa agbẹjọro wọn ri wọn."

Aliyu ni ohun to tiẹ wa n kọ awọn lominu ni ọrọ obinrin kan soso to wa laarin wọn, o ni wọn ko gba laaye lati paarọ asọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Ilorin Cripple Couple: Ọṣẹ ìfabọ́ ni tọkọ-taya tó ní ìpèníjà ẹsẹ̀ ń tà láti bọ́ ọmọ mẹ́ta

"Pata kan soso to wọ si idi ni ọjọ ti wọn mu, naa lo si wa ni idi rẹ, wọn ko jẹ ko paarọ pata tabi asọ."

Aliyu wa fikun pe ohun ti awọn n beere nile ẹjọ ni pe ki adajọ pasẹ pe ki awọn DSS fi oju awọn eeyan mejeejila naa han sita fun wa.

A fẹ fi oju wa ri wọn lati mọ boya awọn mejeejila si wa laye tabi wọn ti ku, a fẹ mọ."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: