DSS Sunday Igboho: Ọ̀rọ̀ pọ nínú ìwé tí Igboho kọ sí ìjọba àpapọ̀, ká diẹ nípa rẹ̀ níbi

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/Instagram
Gbajugbaja ajafẹtọ awọn ọmọ Yoruba, Sunday Igboho ti kọ iwe si ijọba apapọ Naijiria pe ki wọn san owo gba ma binu lori awọn dukia rẹ ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ba jẹ.
Iwe yi ti agbẹnusọ rẹ Olayemi Koiki fi soju opo Facebook rẹ la ti rii ka pe o ni ẹẹdẹgbẹta miliọnu Naira ati iwe itọrọ aforiji ni oun fẹ gba.
Agbẹjọro Igboho, Chief Yomi Alliyu sọ bakan naa pe ọna aitọ ni awọn ọmọ ikọ DSS fi yabo ile Igboho leyi to tako ilana ofin Naijiria.
- Ẹ fi Sunday Ìgbòho sílẹ, ǹkan tí ìjọba Nàìjíríà bàjẹ́ ló ń gbìyànjú àti túnṣé; Ìjọba àpapọ̀ ní láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀ - Wole Soyinka
- Ẹmí sùn n'Ibadan bí ọkọ tó kó afẹ́fẹ́ gáàsì ṣe ṣìnà lọ kọlu àwọn èèyàn
- Àwọn ọmọ ìkókó níléèwòsàn kàgbákò agbébọn! Wọ́n jí wọn gbé pẹ̀lú nọ́ọ̀sì
- Ó tún ti ṣẹlẹ̀! Agbébọn tún jí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Baptist kan gbé
O ni labẹ ofin, o yẹ ki awọn agbofinro ṣafihan erongba wọn lati wọ ile afurasi. Bi wọn ko ba ri esi gba lọdọ ẹni naa, wọn wa le wọle gba ilẹkun ẹnu na tabi ibomiran ninu ile naa.
Yomi Alliyu ni iyalẹnu lo jẹ pe awọn DSS yi ko bikita ẹmi awọn to wa ninu ile naa to fi mọ Imaamu agbalagba kan to n ṣaaju irun Tahajjud fawọn ara inu ile naa.
''Obinrina kan lara awọn to wa si ile Igboho ninu awọn DSS, Niṣer lo n pariwo pe bi ẹ ba ti rii, ẹ yinbọn pa a ni''.

Gẹgẹ bi alaye ti agbẹjọro yi sọ, o ni ko si ẹni ti kọ mọ pe labẹ ofin, o gbọdọ kọkọ fi iwe aṣẹ han pe o fẹ tu ile afurasi eyi ti awọn DSS kọ lati ṣe.
Bẹẹ naa lo ṣalaye pe lati ita lawọn DSS ti da ibọn bole ti wọn si pa eeyan meje yatọ si eeyan meji ti wọn ni awọn pa ninu ikọlu pẹlu awọn ẹsọ Igboho.
''Ko dun mọ awọn DSS yi ninu bi wọn ko ṣe ri ibọn lọdọ awọn ọmọ iṣẹ Igboho. Ohun lo mu wọn gba ibọn meji ti wọn ba lọd awọn ẹṣọ to tẹle alejo to wa Igboho wa''.

Oríṣun àwòrán, Facebook/yomialliyu
Ninu alaye to ṣe bakan naa to fi ni awọn fẹ owo gba ma binu ati iwe itọrọ aforiji lọdọ ijọba, agbẹjọro Igboho ni owo, foonu ati nkan miran lawọn agbofinro gbe lọ.
''Ẹgbẹrun kan Euros, miliọnu meji Naira, ẹgba ọrun owo iyebiye, iwe irinaa, onde ,foonu iPhone12 meji ati foonu awọn eeyan mejila to wa ninu ile naa ni wọn gbe''.
Nigba to n bẹnu atẹ lu awọn DSS ọgbẹni Alliyu sọ pe awọn fẹ ki ijọba ni kiakia:
- paṣẹ iwadii lori DSS ati awọn agbofinro mii to ṣigun wa si ile Igboho
- fi iya jẹ awọn to ba ṣe aṣemaṣe nipa ikọlu si ile r yi
- tu awọn alaimọkan ti wọn wa ni ahamọ ijọba
- san owo gba ma binu fawọn mọlẹbi eeyan to padanu ẹmi wọn
- san owo gba ma binu ẹẹdgbẹta miliọnu Naira fun Igboho lori awọn ọkọ rẹ olowoiyebiye Mercedes Benz G-Class ati 2019 Lexus ti wọn bajẹ
- Ki wọn tọrọ aforijin leyi ti kii ṣe bonkẹlẹ lọwọ Igboho fun aṣiṣe yi
Lakotan o ni awọn fẹ ki ajọ DSS jawọ nibi ko maa ṣapejuwe alabara awọn tii ṣe Igboho gẹgẹ bi ọdaran nipa ṣiṣe afihan ibọn DSS ti wọn pe ni tiẹ.














