Kaduna babies Kidnap: Àwọn agbébọn ṣèkọlù sí iléèwòsàn, wọ́n jí àwọn ọmọọwọ́ gbé

Kaduna kidnap

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn agbebọn ti ṣekọlu si ileewosan kan ni ilu Zaria ti wọn si ji awọn ọmọọwọ to wa nibẹ gbe lọ, to fi mọ awọn nọọsi ati awọn ẹṣọ alaabo.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Kaduna ni awọn agbebọn naa ṣekọlu si ọpọlọpọ agbegbe ti awọn eniyan n gbe ni ileewosan National Tuberculosis and Leprosy Hospital ati agọ ọlọpaa to sun mọ ibẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ojiji ni iṣẹlẹ naa waye, ti o si kọja afẹnusọ, ti eniyan meje sọ ẹmi wọn nu, ti wọn si ji awọn bii mẹwaa gbe lọ.

Àkọlé fídíò, 'Oko ni mo wà lọ́nà "Express" Ilesha tí àwọn agbébọn yìnbọn bá ẹnu mi tí mò fi dà báyìí'

Wọn ni nise ni awọn agbebọn ni abẹlẹ sina bolẹ ni agọ ọlọpaa ni Zaria.

''Lasiko ti iṣẹlẹ yii n waye lọwọ ni awọn agbebọn miran bẹrẹ si ni yin ibọn ni ileewosan National Tuberculosis and Leprosy centre.''

Kaduna kidnap

Oríṣun àwòrán, Getty Images

''Bi o tilẹ jẹpe awọn ọlọpaa bori awọn agbebọn to ṣekọlu si ago ọlọpaa naa, awọn agbebọn gbe awọn ọmọọwọ, awọn nọọsi to fi mọ awọn ẹṣọ alaabo ni ileewosan ọhun.''

''Awọn agbebọn naa si sa wọ inu igbo pẹlu awọn ti wọn jigbe naa''

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni ọpọ ilu kereje to wa nibẹ ni wọn ṣekọlu si, ti wọn si fi ibọn le awọn araalu kuro nibẹ.

Wọn fikun pe awọn mẹrin ni wọn pa loju ẹṣẹ ninu awọn ti wọn jigbe lasiko iṣẹlẹ naa.