Ibadan Gas tanker accident: Báyìí ni ọkọ tó kó afẹ́fẹ́ gáàsì ṣe ṣìnà lọ kọlu àwọn èèyàn n'Ibadan

Aworan lati ibi ijmaba ọkọ ni Bode, Ibadan

Oríṣun àwòrán, Instagram/@connectibadan

Eeyan merin otooto lo padanu emi won, ti awon mefa si fi ara pa lojo Aiku ninu ijamba ọkọ kan ni Ibadan.

Loja Bode to n be ni agbegbe Molete ilu Ibadan lo ti ṣẹlẹ lasiko ti oko ajagbe kan to gbe afefe gaasi padanu ijanu re.

Awon eeyan to wa nibi isele naa se alaye wi pe oko naa to morile ona Gate lati Idi Arere lo jawo inu oja ti o se kolu awon ontaja ati awon eeyan to n koja lọ lopopona.

Pupo ninu awon oja ti won to si ori igba lo pare sinu isele naa.

Adari eso aabo oju popo nipinle Oyo, Arabinrin Chukwurah Uche fi idi oro mule pe awon eeyan mewa lo fi ara gba nibi isele naa.

O ni ijanu oko to da ise sile lo sokunfa ijamba to mu emi eeyan merin lowo.

Omode kan to je okunrin, odo kan to je okunrin ati awon obinrin meji to je odo.

Uche fi kun oro re pe awon eeyan mefa mii fi ara pa ni orisirisi ona, botile je wi pe osojumikoro kan ti ko fe ki a da oruko oun so fun awon akoroyin pe oku eeyan marun un ni oun si to sun sile.Awon osise panapana ipinle Oyo naa yoju sibi isele naa lati dena ijamba ina. Bakan naa ni awon eso aabo fi ara han lati moju to eto aabo agbegbe naa ati lati se akoso lilobibo oko.

Awọn aworan lati ibi isele jamba ina
Àkọlé àwòrán, Awọn aworan lati ibi isele jamba ina

Ẹmí sùn n'Ibadan bí ọkọ tó kó afẹ́fẹ́ gáàsì ṣe ṣìnà lọ kọlu àwọn èèyàn

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ọkọ kan to kun fọfọ fun afẹfẹ gaasi ṣi ọna gba to si pa ọpọlọpọ eeyan to wa loju popo ni ọja Bode lagbegbe Molete n'Ibadan.

Gẹgẹ bi awọn to ṣoju wọn ṣe sọ ọ, ọkọ naa bẹrẹ si ni ṣina lati Idi Arere to si yi wọ inu ọja Bode.

"Ọkọ Tanka naa sare kọja awọn olutaja awọn kan lara wọn si ku loju ẹsẹ nigba ti ọpọlọpọ farapa".

Ẹni to wa nibi iṣlẹ yii ni oun gba awọn eeyan nimọran lati rin jina si ibi ti iṣẹlẹ yii ti waye tori ọkọ naa lee gbina bi awọn ileeṣẹ panapana ko ba ribi da ọgbọn ẹ.

Awọn oniroyin to wa nibẹ fabọ jẹni pe awọn oṣiṣẹ alaabo atawọn oṣiṣẹ panapana wa nibẹ lati mojuto eto naa.

Titi di akoko ti ako iroyin yii jọ, ko tii si ẹnikẹni to mọ iye eeyan to padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa òkú gbígbẹ́ tí wọ́n ṣì bá oyún nínú rẹ̀?