Kwara Brutal Flogging: Ilé àṣòfin kéde òfin tí yóò dènà ìfìyàjẹni lọ́nà àìtọ́

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Ile Igbimọ Aṣofin ni ipinlẹ Kwara ti rọ ijọba lati bẹrẹ igbesẹ lori ofin to de ifiyajẹni lọna aitọ nipinlẹ naa.
Eyi ko ṣẹyin iṣẹlẹ to waye ni ileẹkọ Madrasah Arabic School nibi ti adari ileẹkọ naa ti paṣẹ pe ki wọn na awọn akẹkọọ ni nitori wọn lọ si ile ijo lo ṣe ariya.
Fidio to ja ranyin lori ẹrọ ayelujara safihan bi awọn akẹkọọ ọkunrin marun un ṣe n na awọn akẹkọọ obinrin pẹlu aṣẹ adari ileẹkọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Odunlade, a fún ọ lọ́jọ́ méje, yọ sinimá tó ń fi ẹlẹ́hàá ṣe yẹ̀yẹ́ kúró lórí ayélujára - Ẹgbẹ́ THURIST
- Egúngún fi àdá gba ₦370,000, ọ̀rọ̀ di wàhálà l‘Ondo
- Kò sí iṣẹ́ fún òṣìṣẹ́ ọba tí kò bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára títí December 1 - Ìjọba àpapọ̀
- Ìgbésẹ̀ tà ń gbé rèé lórí ìlera Sunday Igboho àti ìtúsílẹ̀ rẹ̀ - Ilana Ọmọ Oodua
- Ẹ wo ọmọbabinrin ilẹ̀ Japan to sọ ipò iyebíye ti owó rẹ̀ tó $1.3m nù nítorí olólùfẹ́
- "Bí ń kò sún mọ́ Sunday Igboho, ogun abẹ́lé kò bá ti wáyé ní Nàíjíríà"
- Aṣòfin méjì wọ gàù lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ń lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ agbébọn
Ọmọ Ile Aṣofin ipinlẹ Kwara, Adetiba Olanrewaju (Oke- Ero) ni ihuwasi adari olukọ ileẹkọ naa ko ba ofin mu , to si bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa to waye ni agbegbe Ganmo, ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun, ni ipinlẹ naa.
Ile igbimọ aṣofin naa rọ ijọba lati kesi awọn ti ọrọ naa kan ki wọn fi ijiya to tọ jẹ ẹnikẹni tabi ileeṣẹ to ba n ṣe iru tabi hu iru iwa bẹẹ ni ipinlẹ Kwara.
Bakan naa ni wọn rọ ijọba lati bẹrẹ ilanilọyẹ nipa lilo ẹrọ ayeluyara ati awọn ọna ibanisọrọ miran lati fi to awọn araalu leti, ni gbogbo ede ti wọn gbọ, lori ofin to de iwa ipa ni ipinlẹ naa.
Ile Aṣofin naa gboriyin fun gomina Abdulrahman Abdulrazaq lori igbeṣẹ to gbe ni kiakia nipa iṣẹlẹ to waye ni ileẹkọ naa.
Gomina Abdulrazaq gbe igbimọ ẹlẹni-mẹwaa dide lati ṣewadii iṣẹlẹ naa ati ohun ti o ṣokunfa rẹ.
Nibayii, wọn ti ni ki adari ileẹkọ Madrasah Arabic School naa lọ rọkun ni ile fun igba diẹ titi iwadii yoo fi pari lori iṣẹlẹ naa.

Ileesẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadii ile Keu to lu akẹkọọ bii bara

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ni ìpínlẹ̀ Kwara ni ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nílé Kewu kan tí bẹ̀rẹ̀ ni pẹrẹwu bí àwọn se ń fi ọ̀rọ̀ wá adarí ilé Kewu Misbaudeen Al Islamiy lẹ́nu wò fún bí ó ṣe pa á láṣẹ kí wọ́n lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún pé wọ́n lọ ilé ijó.
Ajayi Okasanmi tó jẹ́ agbẹnuso ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara lo fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ lọ́jọ́ Ajé.
"Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́lọ́wó yìí, wọn ń ṣe Ìfọ̀rọ̀wanilenuwo fún adarí ilé Kewu náà, bákan náà ni ìwádìí ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà.
- "Ará Cotonou, Sunday Igboho kò gbọdọ̀ kú sọ́dọ̀ wa o, ó ti wà nílé ìwòsàn báyìí"
- Ẹ dẹ́kun fífún ọkùnrin tí kò bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ní ìbálòpọ̀
- Akúṣẹ́ apẹja bọ́ sínú agbami ọrọ̀ lẹ́yìn tó rí èébì ẹja Wéèlì létíkun
- Ààrẹ Buhari sàlàyé ọdún tí wọn yóò parí òpópónà Eko si Ibadan
- Ìdí rèé tí ń kò fi máa lo bàálù àdáni - Oluwo
- Seyi Makinde pe olóyè PDP lẹ́jọ̀ fún ìbanilórúkọ jẹ́ lórí Facebook
- Buhari, ohun ìjà tó ń kójọ ni wọn yóò lò láti rẹ́yìn Nàíjíríà - Fr Mbaka
- "Èmi ni mo sọ fáwọn ọ̀gá ilé Keu pé kí wọ́n lu ọmọ mi bí ẹran"
- Ọlọ́run nìkan ló ni ẹ̀mí mi, ara mi ti le koko - Bola Tinubu
Ó Kún pé adarí ilé Kewu náà tí gba ìwé gbélé ẹ títí òpin ìwádìí ọlọ́pàá. Ẹ̀wẹ̀, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ni àwọn kò fi adarí ilé ẹ̀kọ́ náà sí àtìmọ́lé.
Làsìkò tó ń fèsì lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Kọmísọ́nà ètò ẹ̀kọ́ ni ìpínlẹ̀ Kwara Sa'adatu Modibbo Kawu sọ pé ilé iṣẹ́ òun ti ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ tí yóò ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
Kawu sọ pé olórí ilé Kewu náà tó sọ pé òun ló pa á láṣẹ pé dá sẹ̀ríà fún àwọn ọmọ náà tí wà nílé náà títí gbogbo ìwádìí yóò fi parí.
"Ìjọba ti ko àwọn ọmọ náà lọ sí ilé ìwòsàn bákan náà fún àyẹ̀wò àti ìtọ́jú tó péye. Èyí ni láti rí i dájú pé kò sí ẹni tí o farapa tàbí tí ọ̀rọ̀ náà yóò máa dàmú ọpọlọ rẹ" gẹ́gẹ́ bí Kawu ṣe sọ
Ki ni àwọn onímọ̀ Islamu mìíràn sọ?
Àwọn onímọ̀ Islamu mìíràn tó bá BBC sọ̀rọ̀ ti fi èrò kan náà hàn ní orí ọ̀rọ̀ náà
Sheik Sayyid Musa Aloba láti ìlú Ilorin nípìnlẹ̀ Kwara ṣàlàyé pé kò bá ojú mú kí olùkọ́ tàbí ẹnikẹni lu akẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀
Gbajúgbajà ónímọ̀ fi kún pé "gbogbo ilé ẹ̀kọ́ yala tí ẹṣin tàbí tí ìgbàlódé náà ni máa ń bá ọmọ wí tí wọ́n bá ṣẹ̀
Ṣùgbọ́n kìí ṣe bí ti kí gbogbo ènìyàn pé lè enikan lórí kí wọn wá máa lù ú
Ṣùgbọ́n tí ẹ̀sẹ̀ tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe bá pọ̀jù ó yẹ kí wọn fi tó àwọn aláṣẹ tó bá yẹ létí kí wọ́n sì tọ ọna tó yẹ.
Dókítà Jabir Sani Maihula is tó jẹ́ olórí ẹ̀ka ẹ̀kọ́ èdè Arabu àti ẹ̀sìn Islamu ni Fáṣítì ìpínlẹ̀ Sokoto ṣàlàyé pé ẹ̀sẹ̀ tó níṣe pẹ̀lú ọtí mímú kii se fún àwọn tó kii se alaṣẹ láti dá.
Ó ní èyí ni ìlànà tó yẹ kí wọ́n gbé gbà adájọ́ kóòtù Sẹ̀ríà nìkan sì ló lè da
Onímọ̀ yìí fi kún pé bótilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ibi tó wà nínú kurani pé iye ẹgba báyìí lọ tó sì ẹni náà.
Àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó kù náà ni Nàìjíríà máa ń bá ọmọ tó bá ṣẹ̀ wí nípa lílo ẹgba sugbọn ń iwọntún-wọnsì ni, kò gbọdọ̀ kọjá àfaradà
Àwọn onímò méjèèjì fẹnu kò pé àṣà àwọn ilé ẹ̀kọ́ ni Nàìjíríà ni lati na a ọmọ tó bá ṣe, ṣùgbọ́n kò sí ilé ẹ̀kọ́ tàbí òbí tó ní eto láti lu ọmọ ni ìlùkulù
Nínú fọ́nrán kan tí ó lu orí ayélujára pa lópin ọ̀sẹ̀ ni a ti rí àwọn gende mẹ́rin tí wọ́n de fìlà funfun tí wọ́n sì wọ aṣọ aró, ọmọbìnrin kan kúnlẹ̀ sí àárín wọn tí wọ́n sì ń lù ú lẹ́gbẹ̀ nípa titẹ̀lé àṣẹ adarí ilé Kewu náà.
Àwọn aláṣẹ ilé Kewu náà ni lílu àwọn ọmọ náà ni làti yí ayé wọn padà, ó ní àwọn rí àwọn ọmọ náà nínú fọ́nrán tí wọn ń mu ọtí ni ilé ijó àwọn òbí wọn náà ló sì mú ẹjọ́ wá sí ilé Kewu.
Fọ́nrán míì náà tún jẹyọ tí akekoo kan kúnlẹ̀ tí àwọn tó kù sì ń da ọtí lè lórí
"Wọn tún ń di mọ ọmọbìnrin kan lára wọn. Ìdí tí a fi lu wọn nìyẹn nítorí abẹ́ àkóso wa ní wọ́n wà," èyí ni nǹkan tí àwọn aláṣẹ ilé Kewu náà sọ.




















