Masquerade Robbers: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí egúngún méjì tó fi àdá gba owó

Ọwọ ijọba ipinlẹ Ondo ti tẹ egungun mejilori ẹsun pe wọn ji owo to to ẹgbẹrun lọna ọtalelọọdunrun naira o le mẹwa (₦370,000).
Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan awọn egungun naa pe wọn fi ada da ọgbẹ si ara ẹni to ni owo naa, Adinoyi Muhammed.
Orukọ awọn ara ọrun naa ni Sheriff Ojo ati Muhammad Lukman, ti awọn mejeeji si ti n naju lagọ ọlọpaa bayii, ti wọn yoo si tun fi oju ba ile ẹjọ laipẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Odunlade, a fún ọ lọ́jọ́ méje, yọ sinimá tó ń fi ẹlẹ́hàá ṣe yẹ̀yẹ́ kúró lórí ayélujára - Ẹgbẹ́ THURIST
- Kò sí iṣẹ́ fún òṣìṣẹ́ ọba tí kò bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára títí December 1 - Ìjọba àpapọ̀
- Ìgbésẹ̀ tà ń gbé rèé lórí ìlera Sunday Igboho àti ìtúsílẹ̀ rẹ̀ - Ilana Ọmọ Oodua
- Ẹ wo ọmọbabinrin ilẹ̀ Japan to sọ ipò iyebíye ti owó rẹ̀ tó $1.3m nù nítorí olólùfẹ́
- "Bí ń kò sún mọ́ Sunday Igboho, ogun abẹ́lé kò bá ti wáyé ní Nàíjíríà"
- Aṣòfin méjì wọ gàù lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ń lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ agbébọn
Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmi Odunlami ti salaye ninu atẹjade kan to fisita, agbegbe Melenge nilu Ipele nipinlẹ Ondo ni awọn egungun mejeeji yii ti sisẹ ibi naa.
Odunlami ni "Awọn afurasi ole yii ni wọn n dibọn bii egungun, wọn fi ada sa Adinoyi Muhammed lati gba owo lọwọ rẹ.
Bakan naa ni wọn tun gba ẹrọ foonu rẹ ti owo rẹ to ẹgbẹrun mejilelọgbọn naira ati asọ kan towo rẹ to ẹgbẹrun meji ati aabọ naira.
Wọn tun da ọgbẹ si ara baba ọmọkunrin ti wọn ja lole naa, Saliu Ajayi lara, tawọn ọlọpaa si ti gba ada meji, oogun abẹnu gọngọ ati ẹku eegun lọwọ wọn."
Ileesẹ ọlọpaa ti wa n leri leka pe laipẹ ni awọn afurasi mejeeji naa yoo fi oju ba ile ẹjọ.

Òbí kan kó jàńdùkú lọ ká olùkọ́ tó na ọ̀mọ̀ rẹ̀ mọ́ iléẹ̀kọ́

Oríṣun àwòrán, Ogun State Police
Ọwọ ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti tẹ ọkunrin kan, Abidemi Oluwaseun, ẹni ọdun marundinlogoji, lori ẹsun pe o kọlu ile ẹkọ kan.
Lasiko ikọlu naa, wọn fi ẹsun kan Abidemi pe o ko awọn afurasi janduku lọ ba olukọ kan nibẹ, ẹni to fẹsun kan pe o lu ọmọ oun obinrin, ọmọ ọdun mẹẹdogun.
Atẹjade kan ti osisẹ alarina fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi fisita lo sisọ loju ọrọ yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Igboho ń jà fún ìran rẹ̀ ni, kìí ṣe apànìyàn, ìjọba Benin, ẹ bá wa tú u sílẹ̀
- Kíndìnrín àti ẹ̀dọ̀fóró Sunday Igboho ni àìsàn ń ṣe - Yomi Aliyu
- "Ará Cotonou, Sunday Igboho kò gbọdọ̀ kú sọ́dọ̀ wa o, ó ti wà nílé ìwòsàn báyìí"
- Àṣìṣe márùn ún tí àwọn lọ́kọláyà ńṣe nípa owó
- Buhari kíyèsára, gbèsè Naijiria pọ̀ ju owó tó ń pa wọlé lọ - AfDB
- "Buhari, oúnjẹ ní ko wá síkùn aráàlú ná, má fi N13.3bn gbé ọlọ́pàá agbègbè kalẹ̀"
Bakan naa ni atẹjade ọhun fikun pe ọwọ tẹ awọn eeyan meji mii, Fayesele Olabanji, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn ati Alebiosu Quawiyu, ẹni ọdun mẹrinlelogun, lori isẹlẹ yii.
Ọga ile ẹkọ naa, Baptist Girls College to wa ladugbo Idi Aba nilu Abeokuta, lo pe awọn ọlọpaa nipe pajawiri pe awọn ọkunrin mẹta ti kọlu ile ẹkọ naa pẹlu ọkọ kan ti ko ni nọmba.
Awọn ọkunrin naa lo ni wọn ko ada tuntun lọwọ, ti wọn si n dunkoko pe awọn yoo sa olukọ kan ni ada nile iwe naa.
Ni kete ti ipe pajawiri naa de, ni ọga ọlọpaa to wa ni agọ ọlọpaa Kemta, Opebiyi Sunday, lewaju awọn osisẹ rẹ lati ko awọn eeyan naa ninu ọgba ile ẹkọ ọhun.
Asiko yii si ni wọn gba ada ati ọkọ ti wọn gbe wa se ikọlu naa.
Ki lo sẹlẹ ti obi fi yọ ada lọ ba olukọ:
Nigba ti wọn n fi ọrọ wa Abidemi lẹnu wo lori ohun to ri lọbẹ, to fi wa iru sọwọ, o salaye pe ọmọ oun atawọn akẹẹgbẹ rẹ ni wọn n fi olukọ wọn se yẹyẹ ni kilaasi lasiko to n kọ wọn lẹkọọ lọwọ.
Idi ree ti olukọ naa fi sa awọn to lewaju iwa aidaa, to si fi ẹgba na wọn gẹgẹ bii ijiya ẹsẹ wọn, amọ se ni ọmọbinrin naa lọ rojọ fun baba rẹ nile pe olukọ na oun.
Eyi si lo mu ki baba naa, Abidemi ko awọn afurasi janduku meji lọwọ lati kọlu ile ẹkọ naa pẹlu ada lọwọ lati gbẹsan lara olukọ to lu akẹkọọ naa.
Wayi o, Kọmisọna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti pasẹ pe ki wọn se iwadii isẹlẹ naa, ki wọn si ko awọn afurasi naa sile ẹjọ laipẹ.
Bakan naa lo sekilọ pe ileesẹ ọlọpaa ko ni fara mọ iru iwa ọdaluru bayii lawọn ile ẹkọ ijọba tabi ti aladani nitori iwa sise idajọ lọwọ ara ẹni lo jẹ.




















