Princess Mako: Ẹ wo ọmọbabinrin ilẹ̀ Japan to sọ ipò iyebíye ti owó rẹ̀ tó $1.3m nù nítorí olólùfẹ́

Toko taya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

111Ọmọbabinrin ilẹ Japan, Mako ti ṣetan lati ṣe igbeyawo pẹlu ololufẹ rẹ to jẹ araalu ni Oṣu Kẹwaa, ọdun 2021.

Ọmọbabinrin Mako lo gbe igbesẹ yii lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti wa lori ọrọ naa laaarin ẹbi rẹ

Ki o to le fẹ araalu naa yoo fi ipo rẹ silẹ, ti igbeyawo yoo si waye ni Ọjọ Kẹrindinlọgbọn, Oṣu Kẹwaa yii.

Ọdun 2018 ni ọmọbabinrin Mako ati ololufẹ rẹ ti fẹ ṣe igbeyawo, amọ awọn ẹbi Arakunrin Komuro wa ninu gbese,ni wọn ko ṣe le ṣe igbeyawo naa ni ọdun meji sẹyin.

Awọn ololufẹ mejeeji ni yoo pada si orilẹede Amerika lati lo ma a gbe nibi ti ọkọ ti n ṣiṣẹ agbẹjọrọ.

Ọpọlọpọ iroyin nipa ọmọbabinrin naa ti baba rẹ jẹ ọba Fumihito ati ẹbi afẹsọna rẹ, Komulo fa aisan irẹwẹsi ọkan fun ọmọbabinrin naa.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho‘s Birthday: Àwọn olólùfẹ́ Igboho rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba Benin láti túu sílẹ̀,

Bakan naa ni auntie rẹ, Masako naa ni ipenija aisan irọnu ọkan lẹyin ti ọpọ eniyan fi oju si lara pe ki o bi arẹmọ ọkunrin.

Ọdun 2012 ni ọmọbabinrin ati ololufẹ rẹ pada lasiko ti wọn jẹ akẹkọọ ni ileẹkọ fasti imọ ẹsin Kristẹni ni Tokyo.

Awọn mejeeji ṣe mọmi n-mọ ọ ni ọdun 2017, ti wọn si fẹ ṣe igbeyawo ni ọdun 2018, ki iwadii to fihan pe iya Komuro jẹ ọkọ afẹsọna rẹ tẹlẹri ni gbese.

Àkọlé fídíò, Olota Of Ota: N kò fara mọ́ ìyapa Nàíjíríà, ìṣèjọba ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ọ̀nà àbáyọ

Leyin naa ni ile ọba fi iroyin lede pe awọn lo lọwọ si ifasẹyin igbeyawo wọn nitori wọn gbọdọ san gbese ti iya rẹ jẹ ki o to le fẹ ọmọ wọn.

Iroyin ni Ọmọbabinrin Mako yoo padanu iye owo to to 150 million yen ($1.3m; £0.97m) to yẹ ko gba to ba n fẹ ọkọ gẹgẹ bi idile ọba.

Bakan naa ni ko ni le e ṣe ayẹyẹ igbeyawo naa gẹgẹ bi ọmọọba laafin amọ bii ti awọn araalu.

Eyi jẹ ki ọmọbabinrin naa jẹ ẹni akọkọ ti yoo kuro ni idile ọba bẹẹ lai si ayẹyẹ igbeyawo to rọmọ

Labẹ ofin orilẹede Japan, ọmọbabinrin yoo sọ ipo rẹ nu to ba fẹ araalu ti ko wa lati idile ọba, amọ ofin yii ko de ọmọbakunrin ilẹ Japan rara.