Father Mbaka: Àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá ló yẹ kí Buhari kọ́ dípò ríra ohun ìjà olóró

Fr Ejike Mbaka ati aa Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, State House Abuja

Gbajugbaja oniwaasu nni, Fada Ejike Mbaka tun ti fi ikilọ ranṣẹ si aarẹ Buhari lori awọn ohun elo ija to n kojọ.

Mbaka lasiko to n waasu ninu ijọ rẹ, Adoration Ministry ni ilu Enugu ni, o ṣe ni laanu pe ohun ija ti aarẹ Buhari n kojọ yii gan an ni yoo rẹyin orilẹede NaijIria.

Ohun to gba aarẹ Buhari ni iyanju lati ṣe ni ki o kọ awọn ileeṣẹ nla nla ti yoo pese iṣẹ fun awọn eniyan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Aarẹ Buhari ti o ko ba ṣọra, awọn ohun ija ọkọ baluu ofurufu to n ra wọnyii ni wọn yoo lo lati fi doju orilẹede Naijiria bolẹ.

''Ẹ jọwọ ẹni akọkọ to ba ri aarẹ Buhari lẹyin iwaasu yii ni ko jiṣẹ fun un lori ọna iparun to wa ninu kikọ awọn dukia ijagun pamọ.''

''Ọlọrun lo ni ki n sọ fun aarẹ Buhari bẹẹ ni asiko yii.''

Àkọlé fídíò, Olota Of Ota: N kò fara mọ́ ìyapa Nàíjíríà, ìṣèjọba ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ọ̀nà àbáyọ

''O to gẹ lori ọrọ rira ohun ija ijagun, kọ kọ kọ awọn ileeṣẹ nla nla.

Amọ ni ọsẹ to kọja lasiko ti aarẹ Buhari sọrọ lo ni pe awon ti n ko awon ohun ijagun tuntun miran wọ orilẹede Naijiria lati awọn orilẹede to fẹran wa.

Buhari ni awọn ohun ijagun naa ni wọn yoo fi koju eto aabo to dẹnukọlẹ kaakiri orilẹede Naijiria.

''Awọn ohun ija yii yoo ran wa lọwọ lati tete bori eto aabo to dẹnukọlẹ.''

Amin iyasọtọ kan

"Ó ṣeéṣe ká ta gáàsì 12.5kg ní ₦10,000 kó tó di December ọdún yìí"

Afẹfẹ Gaasi

Ẹgbẹ awọn alagbata gaasi idana ti n kọminu lori bi wọn ko ṣe ri ọja ta, eyii to mu ki gaasi ọhun ma fi ojojumọ gbowo lori ni Naijiria.

Akọwe agba ẹgbẹ naa, Bassey Essien sọ nibi ipade ita gbangba kan ti ẹgbẹ naa ṣe pe o ṣeeṣe ki iye owo ti awọn araalu n ra gaasi naa di ẹgbẹrun mẹwaa ko ti do oṣu kejila ọdun yii.

Iwọn gaasi 12.5kg ti awọn eeyan n ra ni ẹgbẹrun mẹrin ibẹrẹ yii ti di nnkan bii ẹgbẹrun meje si mẹjọ bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn alagbata gaasi naa ni pupọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n lo eedu ati ina igi nitori ọwọngogo gaasi.

Essien ni ijọba apapọ gbọdọ ṣe atunyẹwo awọn owo ori to n gba lori awọn ọja ti wọn n ko wọ Naijiria lati ilẹ okeere ati iye owo ori VAT.

Àkọlé fídíò, Adeyemi Olubunmi Crown: Láti ìgbà ti mo ti fún ọkọ mi ni ẹ̀bùn mọ́tò ni ìfẹ́ wa ti yàtọ̀

O ni bi bẹẹ kọ, o ṣeeṣe ki awọn maa ta iwọn gaasi 12.5kg ni ẹgbẹrun mẹwaa naira.

O ni "Lonii yii, iye owo gaasi ti di ₦7,500 si ₦8,000, ṣugbọn awọn n gbiyanju ki owo naa ma baa wọn ju bẹẹ lọ."

"Fun apẹrẹ, iye ti a n ra ogun tọọnu gaasi ko to miliọnu marun un naira lọdun to kọja, ṣugbọn bayii o ti le miliọnu mẹwaa naira."

"Niwọn igba ti a ko ba ri ọja ra, iye ti a n taa fun awọn araalu gbọdọ gbowo lori dandan ni."

Nigba to sọrọ lori bi awọn alagbata ko ṣe ta daadaa bii ti atẹyinwa, o ni pupọ ọmọ Naijiria lo ti pada si lilo epo kẹrosini, sawdust, igi idana ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ẹgbẹ naa ti n ba ijọba jiroro lori ọna abayọ si iṣoro ọwọngogo gaasi ọhun laarin awọn to n ko wọ Naijiria lati oke okun ati awọn alagbata.

Ẹgbẹ naa pari ọrọ wọn pe yatọ si gaasi, silinda ti wọn rọ gaasi naa si tun ti gbowo lori ju ti tẹlẹ lọ nitori oke okun ni wọn ti n ko awọn eroja ti wọn fi n ṣe silinda ọhun wọ Naijria.

Àkọlé fídíò, Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb