Mbaka missing: Father Ejike Mbaka ti ṣí aṣọ lójú àwọn tó sọ ọ́ dàwátì

Oríṣun àwòrán, other
Gbajumọ oluṣọaguntan ijọ aguda nipinlẹ Enugu, Ẹniọwọ Ejike Mbaka ti ọpọ mọ si Fada Mbaka ti ṣalaye awọn to wa nidi bo ṣe di awati fun ọjọ meji.
Nigba to n ba awọn olujọsin ijọ rẹ sọrọ nileejọsin Adoration ministries ni Umuchigbo Nike nilu Enugu, Fada Mbaka ṣalaye pe awọn alaṣẹ daosisi ijọ Aguda nilu Enugu lo wa nidi bi oun ṣe dawati.
O ni Bisọbu agba ijọ aguda nibẹ lo pe oun sibi ipade kan, ibẹ si ni wọn ti fi oun si abẹ ahamọ.
O ni ara ẹsun ti wọn ka si oun lẹsẹ̀ ni pe oun gbadura fun Nnamdi Kanu, aṣiwaju ẹgbẹ agbesunmọmi IPOB.
- Ní Yàjóyàjó: Pasítọ̀ Dare, ọmọ́ Pásítọ̀ Adeboye ti dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 42
- Ṣé o mọ àwọn òrìṣà ìṣẹ̀mbáyé méje tó di ilẹ̀ gbogbo àgbáyé mú?
- Ọwọ́ NDLEA tẹ ìyá ẹni ọdún 80 pẹ̀lú oògùn olóró bíi kokeni, heroin, colorado àti skuchies
- Ẹ̀sùn gbígbìyànjú láti wọ́lé sí ojú ara ọmọdé pẹ̀lú ìpá àtàwọn ẹ̀sùn mìí tí Baba Ijesha yóò jẹ́ rèé
Gẹgẹ bi o ṣe sọ fawọn ọmọ ijọ rẹ, ọgbọn ọjọ ni wọn gbero lati fi fi oun si ahamọ ki o to di pe awọn ọmọ ijọ rẹ pariwo sita ti wọn fi tu oun silẹ.
Fada Mbaka ṣalaye pe oun ti wọn sọ fun oun ni pe oun yoo wa lahamọ fun oṣu kan fun oun lati gbadura ki oun si ṣe aṣaro lori iṣe oun.
O ni oun rọ wọn lati fun oun laaye lati ba awọn eeyan ijọ oun sọrọ ki oun si ti ilẹkun ileejọsin naa "ṣugbọn wọn ni rara, ẹ gbami laaye lati ṣe isin oni fun awọn olujọsin ijọ mi, mi o tilẹ ni sọ fun wọn pe mo wa labẹ ibawi, wọn ni rara. Maa kan sọ fawọn ọmọ ijọ mi ni pe mo n lọ fun adura ọlọgbọn ọjọ, a o pada wa gbogbo wa yoo si bọwọ fun gbogbo nnkan ti wọn ba sọ, wọn ni rara"
O ni oun tilẹ bẹ wọn pe ki wọn gbe iranṣẹ Ọlọrun miran lọ si ijọ naa, sibẹ wọn kọ ni.
Ni Ọjọru ni okiki kan nigba tawọn ọmọ ijọ Adoration ministries ti Fada Mbaka n ṣe oluṣọaguntan fun wọde nilu Enugu ti wọn si n pariwo pe ki wọn ba awọn wa Fada Mbaka ti wọn ji gbe.
Ninu ọrọ rẹ, Fada Mbaka ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ agbofinro DSS kọ lo gbe oun gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe ro.
Wo bí Rev'd Father Ejike Mbaka ṣe padà sílé lẹ́yìn tó 'di àwátì' fún ọjọ́ méjì
Wọn ti ri ojiṣẹ Ọlọrun, Fr Ejike Mbaka.
Ṣaaju ni iroyin jade pe alufaa naa to ni ijọ Adoration Ministry nilu Enugu ti di awati fun bi ọjọ meji.
Iṣẹlẹ yii n waye lẹyin ọjọ diẹ ti Mbaka pe ki Aarẹ Muhammadu Buhari fi ipo silẹ nitori bi eto aabo ṣe ri ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Adoration ministry enugu
Bi iroyin ṣe jade pe wọn ko ri Mbaka, ni awọn alatilẹyin rẹ ti tu jade fun iwọde lọ si ile Olori alufaa ijọ Aguda nilu Enugu.
Botilẹ jẹ pe a ko ti i le sọ nkankan nipa bi alufaa naa ṣe pada si ilu tabi ibi to ti n bọ, tilu-tifọn, tijo tayọ ni awọn eeyan fi pade rẹ.
Awọn to wa ni ayika alufaa naa sọ pe o ti le ni ọjọ meji ti awọn ti ri Mbaka gbẹyin.
A gbọ pe o dagbere fun to sunmọ pe pun n lọ si ile Alufaa Agba ijọ Katoliliiki ni ẹkun Enugu, ṣugbọn wọn ko ri i lati igba naa.
Lasiko ti BBC ṣe abẹwo si inu ọgba ijọ rẹ, Adoration Ministry, niṣe ni eero pe jọ sibẹ, ti wọn si n beere pe nibo ni Father Mbaka wa.
Ṣugbọn, BBC ko ti i le sọ ni pato boya wọn ji alufaa naa gbe lọ ni, boya o farapamọ ni tabi wa ni ọdọ awọn agbofinro.
Bakan naa ni awọn alaṣẹ ijọ Aguda nilu Enugu sọ pe awọn ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa.
Alufaa kan to sunmọ Mbaka naa sọ pe oun ko gbọ nipa didi awati rẹ, ṣugbọn ko gbe ipe oun si ori ẹrọ ibanisọrọ rẹ.
Iṣẹlẹ yii si ti mu ki awọn ọmọ ijọ rẹ bẹrẹ iwọde.













