Àlàyé lórí ọjọ́, pápá ìṣiré àti àkókò tí àṣekágbá ife ẹ̀yẹ UEFA Champions League tí Arsenal fẹ́ gbá yóò wáyé?

Aworan ife ẹyẹ UEFA Champions League.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti pegede lati kopa ninu ipele aṣekagba ife ẹyẹ UEFA Champions League saa yii to jẹ ti ọdun 2025/26.

Arsenal nlọ si ipele aṣekagba lẹyin ti wọn bori Athletico Madrid pẹlu ami ayo kan ṣoṣo si odo ni papa iṣire Emirates lọjọ Iṣẹgun. Eyi lo sọ apapọ goolu wọn di meji si ẹyọ kan lẹyin ti wọn ta ọmi onigoolu kọọkan pẹlu Athletico Madrid ni orilẹede Spain lọsẹ to kọja.

Ta ni Arsenal yoo pade ni ipele aṣekagba?

Aworan Awọn agbabọọlu Arsenal pẹlu Akọnimọọgba wọn, Mikel Arteta nibi ti wọn ti n dunnu lẹyin ti wọn bori Athletico Madrid lati tẹ siwaju si ipele aṣekagba UEFA Champons league

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọkan ninu Bayern Munich tabi Paris Saint Germain ni Arsenal yoo pade ni ipele aṣekagba. Bayern ati PSG yoo waa ko ni ifẹsẹwọnsẹ keji ninu ipele to kangun si aṣekagba lalẹ oni lati mọ ẹni ti yoo koju Arsenal.

Nigba wo ni ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba naa yoo waye ati wi pe nibo ni yoo ti waye?

Aworan papa iṣire Puskas ni ilu Budapest.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba ife ẹyẹ UEFA Champions League ọdun yii yoo waye ni ọjọ Abamẹta, ọgbọ̀n ọ̀jọ̀ oṣu karun un ọdun 2026.

Papa iṣire Puskas Arena ni ilu Budapest lorilẹede Hungary ni yoo si ti waye.

Eeyan to din diẹ lẹgbẹrun lọna aadọrin ni papa iṣire naa le gba to ba kun fọfọ.

Ni oṣu kọkanla ọdun 2019 ni wọn ṣi papa iṣire naa eyi ti wọn fi sọ orukọ Ferenc Puskás, eekan agbabọọlu ẹgbẹ agbabọ̀ọ̀lu Real Madrid to jẹ ilumọọka ọmọ Hungary to wa lara ikọ agbabọọ̀lu Hungary to milẹ titi lọdun 1950.