Baba Ijesha: Gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ẹsùn aṣemaṣe Baba Ijesha kó ni lọ láì jìyà

Princess ati Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Princess Comedian, Baba Ijesha

Ijba ipinlẹ Eko ti ni o ṣeeṣe ko ma jẹ Baba Ijesha nikan ni wọn yoo bi lẹjọ lori ẹsun igbiyanju ati fipa ba ọmde lopọ ti wọn fi kan an.

Eyi jẹ jade ninu atẹjade ti wọn fi sita to ṣalaye gbogbo ẹsun ti Baba Ijesha yoo kawọ pọnyin roj le lori ati ijiya wọn to ba jẹbi ọkankan ninu wọn.

Ẹsun marun to ba ofin mu ni gbajugbaja oṣere, Olanrewaju James ti ọpọ mọ si Baba Ijesha yoo fara gba niwaju ile ẹjọ latari ẹsun pe o fẹ fipa ba ọmọde lopọ.

O ṣeeṣe ki ijọba ipinlẹ Eko gbe Baba Ijesha lọ sile ẹjọ laipẹ lori ẹsun naa atawọn ẹsun miran to jọ mọ ibalopọ lọna aitọ.

Ijiya fun ẹsun ibalopọ lọna aitọ ni ipinlẹ Eko ni ẹwọn gbere.

Àkọlé fídíò, 'Ẹ kálọ sí ìlú mi'... Ètò ńlá tó bẹ̀ sílẹ̀ kìjà lórí BBC Yorùbá

Adajọ agba ipinlẹ ọhun, Moyosore Onigbanjo sọ ninu atẹjade kan pe ileeṣẹ ijọba Eko to n ṣegbẹjọ awọn araalu, DPP, ti daba pe ki wọn gbe afurasi naa lọ sile ẹjọ lori ẹsun marun.

Awọn ẹṣun ti wọn fi kan Baba Ijesha ati ijiya fun ọkọọkan ree:

  • Ẹsun kinni, biba ọmọde hu iwa to jọ mọ ibalopọ, eyii ti ijiya rẹ jẹ ẹwọn ọdun meje.
  • Ẹsun keji, biba ọmọde ni ibalopọ, eyii ti ijiya rẹ jẹ ẹwọn gbere.
  • Ẹsun kẹta, fifi ipa ni ibalopọ, ẹwọn gbere ni ijiya rẹ bakan naa.
  • Ẹsun kẹrin, igibiyanju lati fi ipa ni ibalopọ, eyii ti ijiya rẹ jẹ ẹwọn ọdun mẹrinla.
  • Ẹsun karun un, ibalopọ ti ko ti inu ẹnikeji wa, eyii ti ijiya rẹ jẹ ẹwọn ọdun mẹta.
Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha

Atẹjade naa tẹsiwaju pe bo tilẹ jẹ pe awọn ko ni fi iya jẹ afurasi naa lọna aitọ, ati pe awọn ko ni tẹ ẹtọ rẹ labẹ ofin loju, awọn yoo rii daju pe ẹnikẹni to ba ṣẹ si ofin ifipabanilopọ nipinlẹ Eko yoo foju wina ofin.

Ileeṣẹ naa ni awọn ni igbagbọ to dantọ ninu ẹka eto idajọ ipinlẹ ọhun lati rii daju pe "gbogbo awọn ti ọrọ naa kan ni yoo ri idajọ ododo gba".

Lẹyin naa ni adajọ agba ọhun sọ pe awọn yoo gbe ọrọ naa lọ ile ẹjọ laipẹ gẹgẹ bii imọran DPP.

Àkọlé fídíò, 'Iṣẹ wá burẹkẹ síi tórí Covid-19, owó ńlá ló wà nínú dídáná sun òkú, ìsìnkú Zoom, Live streaming'
Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha

Ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko sọ fun BBC ninu atẹjade kan pe, afurasi naa ti wa ni ahamọ.

Wọn fi baba Ijesha si atimọle lẹyin ti Damilola Adesanya, ti ọpọ mọ si Princess Comedian fi ẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa to wa ni Sabo nilu Eko.

Ọjọ diẹ si akoko naa ni oṣere tiata miran, Iyabo Ojo gbe fidio ibi ti wọn ni ọwọ ti tẹ Baba Ijesha jade loju opo Instagram rẹ, ti afurasi si n bẹbẹ pe ki wọn foriji oun nitori iṣẹ eṣu lo mu ki oun ṣe aṣemase ti wọn ka mọ oun lọwọ.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria ati awọn akẹgbẹ afurasi ọhun nidi iṣẹ tiata ni wọn ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori iṣẹlẹ naa.